A A A A A

God: [Blessing]


Luku 6:38
Ẹ fifún ni, a ó sì fifún yín; òṣùnwọ̀n dáradára, àkìmọ́lẹ̀, àti àmìpọ̀, àkúnwọ́sílẹ̀, ni a ó wọ̀n fún àyà yín: nítorí òṣùnwọ̀n náà tí ẹ̀yin fi wọ̀n, òun ni a ó padà fi wọ̀n fún yín.”

Matiu 5:4
Alábùkún-fún ni àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, nítorí a ó tù wọ́n nínú.

Filipi 4:19
Ṣùgbọ́n Ọlọ́run mi yóò pèsè ní kíkún fún gbogbo àìní yín, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú ògo nínú Kírísítì Jésù.

Saamu 67:7
Ọlọ́run yóò bùkún fún wa, àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò sì máa bẹ̀rù Rẹ̀.

Numeri 6:24-25
[24] “ ‘ “Kí OLÚWA bùkún un yín Kí ó sì pa yín mọ́.[25] Kí OLÚWA kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín.

Filipi 4:6-7
[6] Ẹ má ṣe ṣe àníyàn ohunkóhun; ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo, nípa àdúrà àti ẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́, ẹ máa fi ìbéèrè yín hàn fún Ọlọ́run.[7] Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín máa nínú Kírísítì Jésù.

Jakọbu 1:17
Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ẹ̀bùn pípé láti òkè ni ó ti wá, ó sì sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ baba ìmọ́lẹ̀ wá, lọ́dọ̀ ẹni tí kò lè yípadà gẹ́gẹ́ bí òjìji àyídà.

Jeremiah 17:7-8
[7] “Ṣùgbọ́n ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLÚWA, tí ó sì fi OLÚWA ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.[8] Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún-un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjáyà fún-un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”

Isaiah 41:10
Nítorí náà má bẹ̀rù, nítorí èmi wà pẹ̀lúù rẹ; má ṣe jẹ́ kí àyà kí ó fò ọ́, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Èmi yóò fún ọ lókun èmi ó sì ràn ọ́ lọ́wọ́. Èmi ó gbé ọ ró pẹ̀lú ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi.

Johanu 1:16
Nítorí láti inú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀ ni gbogbo wa sì ti gba ìbùkún kún ìbùkún.

Gẹnẹsisi 22:16-17
[16] Ó sì wí pé, OLÚWA wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dùn mí,[17] dájúdájú, Èmi yóò bùkún ọ, Èmi yóò sì mú kí ìran rẹ yìí kí ó pọ̀ bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí i yanrìn etí òkun. Irú ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀ta wọn,

Gẹnẹsisi 27:28-29
[28] Kí OLÚWA kí ó fún ọ ní ìrì ọ̀run àti nínú ọ̀rá ilẹ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti wáìnì túntún.[29] Kí àwọn orílẹ̀-èdè kí ó máa sìn ọ́, kí àwọn ènìyàn sì máa tẹríba fún ọ, máa ṣe olórí àwọn arákùnrin rẹ, kí àwọn ìyekan rẹ sì máa wólẹ̀ fún ọ Ègún ni fún gbogbo ẹni tí ń fi ọ́ ré, Ìbùkún ni fún gbogbo ẹni tí ó súre fún ọ.”

Saamu 1:1-3
[1] Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà, tí kò rìn ní pa ìmọ̀ràn àwọn ènìyàn búburú tàbí ti kò ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn pọ̀, tàbí ti kò si bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.[2] Ṣùgbọ́n ayọ̀ inú Rẹ̀ wà nínú òfin OLÚWA àti nínú òfin Rẹ̀ ni ó ń ṣe àṣàrò ní ọ̀sán àti òru.[3] Ó dàbí igi tí a gbìn sí eti odò tí ń ṣàn, tí ń so èso Rẹ̀ jáde ní àkókò Rẹ̀ tí ewé Rẹ̀ kì yóò Rẹ̀. Ohunkóhun tí ó dáwọ́lé, ni yóò máa yọrí sí rere.

Saamu 23:1-4
[1] OLÚWA ni Olùsọ́ àgùntàn mi, èmi kì yóò ṣe aláìní.[2] Ó mú mi dùbúlẹ̀ síbi pápá oko tútù Ó mú mi lọ síbi omí dídákẹ́ rọ́rọ́;[3] Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò Ó mú mi lọ sí ọ̀nà ododo nítorí orúkọ Rẹ̀.[4] Bí mo tílẹ̀ ń rìn Láàrin àfonífojì òjiji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan; nítorí ìwọ wà pẹ̀lú ù mi; ọ̀gọ Rẹ àti ọ̀pá à Rẹ wọ́n ń tù mi nínú.

2 Samuẹli 22:3-4
[3] Ọlọ́run mi, àpáta mi, nínú ẹni tí èmi ní ààbò, àti ìwọ ìgbàlà mi, ibi ìsádi gíga mi, àti ibi ìlùmọ̀ mi, Olùgbàlà mi; ìwọ ni ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìwà ipá.[4] Èmi képe OLÚWA, tí ó yẹ láti máa yìn, ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

1 Johanu 5:18
Àwá mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pá ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ kàn án.

Saamu 138:7
Bí èmi tilẹ̀ ń rìn nínú ìpọ́njú ìwọ ni yóò sọ mi di àyè; ìwọ ó nà ọwọ́ Rẹ̀ si àwọn ọ̀tá mi, ọwọ́ ọ̀tún Rẹ yóò sì gbà mí.

2 Kọrinti 9:8
Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo.

Filipi ౪:౭
Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín máa nínú Kírísítì Jésù.

Yoruba Bible (BMY) 2014
Biblica Yoruba Bible