A A A A A


Search

Matiu 10:13
Bí ilé náa bá sì yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó bà sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà yín kí ó padà sọ́dọ̀ yín.


Matiu 10:34
“Ẹ má ṣe rò pé mo mú àlàáfíà wá sí ayé, Èmi kò mú àlàáfíà wá bí kò ṣe idà.


Matiu 26:49
Nísinsìn yìí, Júdásì wá tààrà sọ́dọ̀ Jésù, ó wí pé, “Àlàáfíà, Ráábì” ó fi ẹnu kò ó ní ẹnu.


Matiu 28:9
Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jésù pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹṣẹ̀ mú. Wọ́n sì forí balẹ̀ fún un.


Marku 5:34
Jésù sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ lára dá: Má a lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú àrùn rẹ.”


Marku 9:50
“Iyọ̀ dára, ṣùgbọ́n tí ó bá sọ agbára adùn rẹ̀ nù, báwo ni ẹ ṣè lè padà mu un dùn? Ẹ ni iyọ̀ nínú ara yín, ki ẹ sì máa gbé ni àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.”


Luku 10:6
Bí ọmọ àlààáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e: ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò tún padà sọ́dọ̀ yín.


Luku 11:21
“Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà.


Johanu 14:27
Àlàáfíà ni mo fi sílẹ̀ fún yín pé, Èmi ń lọ, èmi fi fún yín. Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú, ẹ má sì jẹ́ kí ó wárìrì.


Johanu 16:33
“Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín tẹ́lẹ̀, kí ẹ̀yin kí ó lè ní àlàáfíà nínú mi. Nínú ayé, ẹ̀yin ó ní ìpọ́njú; ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”


Johanu 20:19
Lọ́jọ́ kan náà, lọ́jọ́ kínní ọ̀ṣẹ̀ nígbà tí alẹ́ lẹ́, tí a sì ti ìlẹ̀kùn ibi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn gbé péjọ, nítorí ìbẹ̀rù àwọn Júù, bẹ́ẹ̀ ni Jésù dé, ó dúró láàárin, ó sì wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín.”


Johanu 20:21
Nítorí náà, Jésù sì tún wí fún wọn pé, “Àlàáfíà fún yín: gẹ́gẹ́ bí Baba ti rán mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì rán yín.”


Johanu 20:26
Lẹ́yìn ijọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tọ́másì pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlèkùn, Jésù dé, ó sì dúró láàrin, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.”


Ìṣe àwọn Aposteli 9:31
Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Jùdíà àti ni Gálílì àti ni Samaríà, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i


Ìṣe àwọn Aposteli 10:36
Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Isírẹ́lì, nígbà tí a wàásù àlàáfíà nípa Jésù Kírísítì (Òun ni Olúwa ohun gbogbo)


Ìṣe àwọn Aposteli 12:20
Héródù sí ń bínú gidigidi sí àwọn ará Tírè àti Sídónì; ṣùgbọ́n wọ́n fi ìmọ̀sọ̀kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nígbà tí wọn sì ti tu Bílásítù ìwẹ̀fà ọba lójú, wọn ń bẹ̀ẹ̀ fún àlàáfíà, nítorí pé ìlú ọba náà ni ìlú tiwọn ti ń gba oúnjẹ.


Ìṣe àwọn Aposteli 15:29
Kí ẹ̀yin fà sẹ̀yìn kúrò nínú ẹran àpabọ òrìṣà, àti nínú ẹ̀jẹ̀ àti nínú ohun ìlọ́lọ́rùn-pa, àti nínú àgbérè: nínú ohun tí, bí ẹ̀yin bá pa ara yín mọ́ kúrò, ẹ̀yin ó ṣe rere. Àlàáfíà.


Ìṣe àwọn Aposteli 15:33
Nígbà tí wọn sì pẹ́, díẹ̀, àwọn arákùnrin rán wọn padà lọ ni àlàáfíà sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ó rán wọn wá.


Ìṣe àwọn Aposteli 16:36
Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Pọ́ọ̀lù, wí pé, “Àwọn onídájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da yín ṣílẹ̀: ǹjẹ́ nisinsìnyìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”


Ìṣe àwọn Aposteli 23:24
Ó sì wí pé, kí wọn pèṣè ẹranko, kí wọ́n gbé Pọ́ọ̀lù gùn ún; kí wọ́n sì lè mú un dé ọ̀dọ̀ Fẹ́líkísì baálẹ̀ ní àlàáfíà.”


Ìṣe àwọn Aposteli 23:26
Kíláúdíù Lísíà, Sí Fẹ́líkísì baálẹ̀ ọlọ́lá jùlọ: Àlàáfíà.


Ìṣe àwọn Aposteli 24:2
Nígbà tí a sí tí pè Pọ́ọ̀lù jáde, Tátúlù gbé ẹjọ́ rẹ̀ kalẹ̀ níwájú Fẹ́líkísì ó wí pé: “Àwa ti wà ní àlàáfíà ní abẹ́ ìjọba rẹ lá ìgbà pípẹ́ wá, àti pé ìfojúsù rẹ ti mú àyípadà rere bá orílẹ̀-èdè yìí.


Ìṣe àwọn Aposteli 27:44
Àti àwọn ìyókú, òmìíràn lórí pátakó, àti omíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ́.


Romu 1:7
Sí gbogbo àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run tí ó wà ní Róòmù tí a ti pè láti jẹ́ ènìyàn mímọ́: Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti láti ọ̀dọ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì.


Romu 2:10
ṣùgbọ́n ògo, àti ọlá, àti àlàáfíà, fún olúkúlùkù ẹni tí ń hùwà rere, fún Júù, ṣáájú àti fún àwọn aláìkọlà pẹ̀lú:


Romu 3:17
Ọ̀nà àlàáfíà ni wọn kò sì mọ̀:”


Romu 5:1
Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nípa ìgbàgbọ́, àwa ní àlàáfíà lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípaṣẹ̀ Olúwa wa Jésù Kírísítì.


Romu 8:6
Ṣíṣe ìgbọ́ran sí ẹ̀mí Mímọ́ ń yọrí sí ìyè àti àlàáfíà. Ṣùgbọ́n títẹ̀lé ara ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ náà ń yọrí sí ikú.


Romu 10:10
Nítorí pé, nípa ìgbàgbọ́ nínú ọkàn ni ènìyàn le gbà ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ ni ẹnu ni a sì fi ń sọ fún àwọn ẹlòmíràn ní ti ìgbàgbọ́ wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a sì sọ ìgbàlà wa di ohun tí ó dájú.


Romu 10:15
Wọ́n ó ha sì ti ṣe wàásù, bí kò ṣe pé a rán wọn? Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Ẹsẹ̀ àwọn tí ń wàásù ìyìn rere àlàáfíà ti dára tó, àwọn tí ń wàásù ìhìn ìyìn àyọ̀ ohun rere!”


Romu 12:18
Bí ó le ṣe, bí ó ti wà ní ipa ti yín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.


Romu 14:17
Nítorí ìjọba ọ̀run kì í se jíjẹ àti mímu, bí kò se nípa ti òdodo, àlàáfíà àti ayọ̀ nínú Èmí Mímọ́,


Romu 14:19
Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a sa gbogbo ipá wa láti máa lépa àlàáfíà, àti ohun tí àwa yóò fi gbé ara wa ró.


Romu 15:13
Njẹ́ kí Ọlọ́run ìrètí kí ó fi gbogbo ayọ̀ òun àlàáfíà kún yín bí ẹ̀yín ti gbà á gbọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè pọ̀ ní ìrétí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.


Romu 15:33
Kí Ọlọ́run àlàáfíà wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.


Romu 16:20
Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì tẹ Sátanì mọ́lẹ̀ ní àtẹ́lẹsẹ̀ yín ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa kí ó wà pẹ̀lú yín.


1 Kọrinti 1:3
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Olúwa wa tí í ṣe Jésù Kírísítì.


1 Kọrinti 14:33
Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run ohun rúdurùdu, ṣùgbọ́n ti àlàáfíà. Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ nínú gbogbo ijọ ènìyàn mímọ́


1 Kọrinti 16:11
Nítorí náà kí ẹnikẹ́ni má ṣe kẹ́gàn rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ sín ín jáde lọ́nà àjò ni àlàáfíà, kí òun lè tọ̀ mí wá; nítorí tí èmí ń fi ojú sí ọ̀nà fún wíwá rẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin.


2 Kọrinti 1:2
Oore-ọ̀fẹ́ si yín àti àlàáfíà làti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Jésù Kírísítì Olúwa.


2 Kọrinti 2:13
Síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kan mi, nítorí tí èmi kò rí Títù arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedóníà,


2 Kọrinti 13:11
Ní àkótan, ará ó dì gbòóṣe, ẹ ṣe àtúnse ọ̀nà yín, ẹ tújúká, ẹ jẹ́ onínúkan, ẹ máa wà ní àlàáfíà, Ọlọ́run ìfẹ́ àti ti àlàáfíà yóò wà pẹ̀lú yín.


Galatia 1:3
Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa,


Galatia 5:22
Ṣùgbọ́n èèso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,


Galatia 6:16
Kí àlàáfíà àti àánú wà lórí gbogbo àwọn tí ń rìn ní ìlànà yìí, àti lórí Ísírẹ́lì Ọlọ́run.


Efesu 1:2
Oore ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jésù Kírísítì Olúwa.


Efesu 2:14
Nítorí oun ni àlàáfíà wa, ẹni tí o ti ṣe méjèèjì ni ọ̀kan, tí ó sì ti wó ògiri ìkélé ti ìkórira èyí tí ń bẹ láàrin yín.


Efesu 2:17
Ó sì ti wá ó sì ti wàásù àlàáfíà fún ẹ̀yin tí o jìnnà réré, àti àlááfíà fún àwọn tí o súnmọ́ tòòsí.


Efesu 4:3
Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà.


Efesu 6:15
Tí ẹ sì ti fí ìmúrà ìyìn rere àlàáfíà wọ ẹṣẹ̀ yín ní bàtà.


Efesu 6:23
Àlàáfíà fún àwọn ará, àti ìfẹ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, làti ọdọ Ọlọ́run Baba wà, àti Olúwa wà Jésù Kírísítì.


Filipi 1:2
Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jésù Kírísítì.


Filipi 4:7
Àti àlàáfíà Ọlọ́run, tí ó ju ìmòye gbogbo lọ, yóò pa ọkàn àti èrò yín máa nínú Kírísítì Jésù.


Filipi 4:9
Àwọn nǹkan tí ẹ̀yin ti kọ́, tí ẹ̀yin sì ti gbà, tí ẹ̀yin sì ti gbọ́, tí ẹ̀yin sì ti rí lọ́wọ́ mi, ẹ máa ṣe wọ́n: Ọlọ́run àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.


Kolose 1:2
Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin nínú Kírísítì tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kólósè. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún-un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.


Kolose 1:20
Àti nípaṣẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ lọ́rùn, nípa mímú àlàáfíà wá nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélèbùú.


Kolose 3:15
Ẹ sì jẹ́ kí àlàáfíà Ọlọ́run kí ó máa ṣe àkóso ọkàn yín, sínú èyí tí a pè yín pẹ̀lú nínú ara kan; kí ẹ sì máa dúpẹ́.


1 Tẹsalonika 1:1
Pọ́ọ̀lù, Sílásì àti Tímótíù. A kọ ọ́ sí ìjọ tí ó wà ní ìlú Tẹsalóníkà, àwọn ẹni tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run Baba àti ti Olúwa Jésù Kírísítì. Kí ìbùkún àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba àti Jésù Kírísítì kí ó jẹ́ tiyín.


1 Tẹsalonika 5:13
Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ni àlàáfíà láàrin ara yín.


1 Tẹsalonika 5:23
Kí Ọlọ́run àlàáfíà pàápàá wẹ̀ yín mọ́, kí ó sì yà yín sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́, títí di ìgbà wíwá Jésù Kírísítì Olúwa wa.


2 Tẹsalonika 1:2
Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jésù Kírísítì Olúwa.


2 Tẹsalonika 3:16
Ǹjẹ́ kí Olúwa àlàáfíà, fúnrarẹ̀ máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo. Kí Olúwa kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín.


1 Timotiu 1:2
Sí Tímótíù ọmọ mi nínú ìgbàgbọ́: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Jésù Kírísítì Olúwa wa.


2 Timotiu 1:2
Sí Tímótíù, Ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n: Oore-ọ̀fẹ́, àánú àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Kírísítì Jésù Olúwa wa,


2 Timotiu 2:22
Máa sá fún ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ èwe: sì máa lépa òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tí ń ké pe Olúwa láti inú ọkàn funfun wá.


Titu 1:4
Sí Títù, ọmọ mi tòótọ́ nínú ìgbàgbọ́ wa kan náà. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run baba àti Kírísítì Jésù Olùgbàlà wa.


Filemoni 1:3
Oore-Ọ̀fẹ́ fún un yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa àti Jésù Kírísítì.


Heberu 7:2
Ẹni tí Ábúráhámù sì pin ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún; lọ́nà èkíniní nínú ìtumọ̀ rẹ̀, “Ọba òdodo,” àti lẹ̀yìn náà pẹ̀lú, “ọba Sálẹ́mù,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.”


Heberu 11:31
Nípa ìgbàgbọ́ ni Ráhábù panṣágà kò ṣègbé pẹ̀lú àwọn tí kò gbọ́ràn nígbà tí o tẹ́wọ́gba àwọn àmì ní àlàáfíà.


Heberu 12:11
Gbogbo ìbáwí kò dábì ohun ayọ̀ nísinsìn yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹ́yìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.


Heberu 12:14
Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa:


Heberu 13:20
Ǹjẹ́ Ọlọ́run àlàáfíà, ẹni tí o tún mu olùsọ́-àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn, ti inú òkú wá, nípa ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mu ayérayé, àní Olúwa wa Jésù.


Jakọbu 1:1
Jákọ́bù, ìránṣẹ́ Ọlọ́run àti ti Jésù Kírísítì Olúwa, Sí àwọn ẹ̀yà méjìlá tí ó fọ́n káà kiri, orílẹ̀-èdè. Àlàáfíà.


Jakọbu 2:16
Tí ẹni kan nínú yín sì wí fún pé, “máa lọ ní àlàáfíà, kí ara rẹ kí ó má ṣe tutù, kí ó sì yó,” ṣùgbọ́n ẹ kò fi nǹkan wọ̀n-ọn-nì ti ara ń fẹ́ fún wọn; èrè kí ni ó jẹ́?


Jakọbu 3:17
Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsáájú, a sì máa sọ òtítọ́.


Jakọbu 3:18
Àwọn tí ó ń ṣíṣẹ́ àlàáfíà a sì máa gbin èso àlàáfíà ní àlàáfíà.


1 Peteru 1:2
àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kírísítì: Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.


1 Peteru 3:11
Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere; kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.


1 Peteru 3:14
Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, àlàáfíà ni: ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú;


2 Peteru 1:2
Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jésù Olúwa wá.


2 Peteru 3:14
Nítorí náà, olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti ń retí irú nǹkan wọ̀nyí, ẹ múra gírí, kí a lè bá yín ní àlàáfíà ní àìlábàwọ́n, àti ní àìlábùkù lójú rẹ̀.


3 Johanu 1:14
Mo ni ìrètí láti rí ọ láìpẹ́, tí àwa yóò sì sọ̀rọ̀ lójúkojú. Àlàáfíà fún ọ. Àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà níbí kí ọ. Kí àwọn ọ̀rẹ́ wa tó wà níbẹ̀ yẹn ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.


Juda 1:2
Kí àánú, àlàáfíà àti ìfẹ́ kí ó máa jẹ́ tiyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.


Ìfihàn 1:4
Jòhánù, Sí àwọn ìjọ méje tí ń bẹ ní Éṣíà: Ore-ọ̀fẹ́ fún yín, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ń bẹ, tí ó sì ti wà, tí ó sì ń bọ̀ wá; àti láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí méje tí ń bẹ níwájú ìtẹ́ rẹ̀;


Ìfihàn 6:4
Ẹṣin mìíràn tí ó pupa sì jáde: a sì fi agbára fún ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀, láti gba àlàáfíà kúrò lórí ilẹ̀ ayé, àti pé kí wọn kí ó máa pa ara wọn: A sì fi idà ńlá kan lé e lọ́wọ́.


Yoruba Bible (BMY) 2014
Biblica Yoruba Bible