Instagram
English
A A A A A


Search

Матфей 5:45
Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo.


Johanu 7:18
Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ń wá ògo ti ara rẹ̀. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń wá ògo ẹni tí ó rán an níṣẹ́ jẹ́ olóòótọ́, kò sí aiṣododo ninu rẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 8:23
Nítorí mo wòye pé ẹ̀tanú ti gbà ọ́ lọ́kàn, àtipé aiṣododo ti dè ọ́ lẹ́wọ̀n.”


Romu 3:5
Bí aiṣododo wa bá mú kí òdodo Ọlọrun fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ni kí á wá wí? Ṣé Ọlọrun kò ṣe ẹ̀tọ́ láti bínú sí wa ni? (Mò ń sọ̀rọ̀ bí ẹni pé eniyan ni Ọlọrun.)


1 Kọrinti 6:9
Àbí ẹ kò mọ̀ pé kò sí alaiṣododo kan tí yóo jogún ìjọba Ọlọrun? Ẹ má tan ara yín jẹ, kò sí àwọn oníṣekúṣe, tabi àwọn abọ̀rìṣà, àwọn àgbèrè tabi àwọn oníbàjẹ́, tabi àwọn tí ó ń bá ọkunrin lòpọ̀ bí obinrin;


2 Kọrinti 6:14
Ẹ má ṣe da ara yín pọ̀ mọ́ àwọn alaigbagbọ. Nítorí ìrẹ́pọ̀ wo ni ó wà láàrin ìwà òdodo ati aiṣododo? Tabi, kí ni ó pa ìmọ́lẹ̀ ati òkùnkùn pọ̀?


1 Peteru 3:18
Nítorí Kristi kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo fún ẹ̀ṣẹ̀ wa; olódodo ni, ó kú fún alaiṣododo, kí ó lè mú wa wá sọ́dọ̀ Ọlọrun. A pa á ní ti ara, ṣugbọn ó wà láàyè ní ti ẹ̀mí.


2 Peteru 2:9
Oluwa mọ ọ̀nà láti yọ àwọn olùfọkànsìn kúrò ninu ìdánwò, ṣugbọn ó pa àwọn alaiṣododo mọ́ de ìyà Ọjọ́ Ìdájọ́.


2 Peteru 2:15
Wọ́n fi ọ̀nà títọ́ sílẹ̀, wọ́n ń ṣe ránun-rànun kiri. Wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, tí ó fẹ́ràn èrè aiṣododo.


1 Johanu 5:17
Gbogbo aiṣododo ni ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀ṣẹ̀ mìíràn wà tí kò jẹ mọ́ ti ikú.


Yoruba Bible (BM) 2010
Bible Society of Nigeria © 1900/2010