A A A A A


Search

Matiu 1:1
Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu.


Matiu 1:16
Jakọbu bí Josẹfu ọkọ Maria, ẹni tí ó bí Jesu tí à ń pè ní Kristi.


Matiu 1:17
Nítorí náà, gbogbo ìran Jesu láti ìgbà Abrahamu títí di ti Dafidi jẹ́ mẹrinla; láti ìgbà Dafidi títí di ìgbà tí wọn kó àwọn ọmọ Israẹli lẹ́rú lọ sí Babiloni jẹ́ ìran mẹrinla; láti ìgbà tí wọn kó wọn lẹ́rú lọ sí Babiloni títí di àkókò Kristi jẹ́ ìran mẹrinla.


Matiu 1:18
Bí ìtàn ìbí Jesu Kristi ti rí nìyí. Nígbà tí Maria ìyá rẹ̀ wà ní iyawo àfẹ́sọ́nà Josẹfu, kí wọn tó ṣe igbeyawo, a rí i pé Maria ti lóyún láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.


Matiu 1:21
Yóo bí ọmọkunrin kan, o óo sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu nítorí òun ni yóo gba àwọn eniyan rẹ̀ là kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”


Matiu 1:25
Kò sì bá a lòpọ̀ rárá títí ó fi bímọ. Ó sì pe orúkọ ọmọ náà ní Jesu.


Matiu 2:1
Nígbà tí wọ́n bí Jesu ní Bẹtilẹhẹmu ní ilẹ̀ Judia, ní ayé Hẹrọdu ọba, àwọn amòye kan wá sí Jerusalẹmu láti ìhà ìlà oòrùn.


Matiu 3:13
Nígbà náà ni Jesu lọ láti ilẹ̀ Galili, sọ́dọ̀ Johanu ní odò Jọdani, kí Johanu lè ṣe ìrìbọmi fún un.


Matiu 3:15
Jesu dá a lóhùn pé, “Jẹ́ kí á ṣe é bẹ́ẹ̀ ná, nítorí báyìí ni ó yẹ fún wa bí a bá fẹ́ ṣe ẹ̀tọ́ láṣepé.” Nígbà náà ni Johanu gbà fún un.


Matiu 3:16
Bí Jesu ti ṣe ìrìbọmi tán, tí ó gòkè jáde kúrò ninu omi, ọ̀run pínyà lẹsẹkẹsẹ. Jesu wá rí Ẹ̀mí Ọlọrun tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, tí ó ń bà lé e.


Matiu 4:1
Lẹ́yìn náà, Ẹ̀mí gbé Jesu lọ sí aṣálẹ̀ kí Èṣù lè dán an wò.


Matiu 4:4
Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè, bíkòṣe nípa gbogbo ọ̀rọ̀ tí Ọlọrun bá sọ.’ ”


Matiu 4:7
Jesu sọ fún un pé, “Ó tún wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”


Matiu 4:10
Jesu bá dá a lóhùn, ó ní, “Pada kúrò lẹ́yìn mi, Satani. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o máa sìn.’ ”


Matiu 4:12
Nígbà tí Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ju Johanu sẹ́wọ̀n, ó yẹra lọ sí Galili.


Matiu 4:17
Láti àkókò yìí ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí waasu pé, “Ẹ ronupiwada, nítorí ìjọba ọ̀run súnmọ́ ìtòsí.”


Matiu 4:18
Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meji kan, Simoni tí ó tún ń jẹ́ Peteru ati Anderu arakunrin rẹ̀. Wọ́n ń da àwọ̀n sí inú òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.


Matiu 4:19
Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, kì í ṣe ẹja ni ẹ óo máa pamọ́, eniyan ni ẹ óo máa fà wá.”


Matiu 4:23
Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan.


Matiu 5:1
Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan, ó gun orí òkè lọ. Ó jókòó; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.


Matiu 7:28
Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ẹnu ya àwọn eniyan sí ẹ̀kọ́ rẹ̀;


Matiu 8:1
Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn eniyan ń tẹ̀lé e.


Matiu 8:3
Jesu bá na ọwọ́ rẹ̀, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́, kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ ni àrùn ẹ̀tẹ̀ náà bá kúrò lára rẹ̀.


Matiu 8:4
Jesu wá sọ fún un pé, “Má sọ fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn, lọ, fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ gẹ́gẹ́ bí Mose ti pa á láṣẹ, bí ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.”


Matiu 8:5
Nígbà tí Jesu wọ ìlú Kapanaumu, ọ̀gágun kan tí ó ní ọgọrun-un ọmọ-ogun lábẹ́ rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, ó ń bẹ̀ ẹ́; ó ní,


Matiu 8:7
Jesu bá sọ fún un pé, “N óo wá, n óo sì wò ó sàn.”


Matiu 8:10
Nígbà tí Jesu gbọ́, ẹnu yà á, ó sọ fún àwọn tí ó ń tẹ̀lé e pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!


Matiu 8:13
Jesu bá sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Máa lọ, gẹ́gẹ́ bí o ti gbàgbọ́, bẹ́ẹ̀ ni kí ó rí fún ọ.” Ara ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì dá ní àkókò náà gan-an.


Matiu 8:14
Nígbà tí Jesu wọ inú ilé Peteru, ó rí ìyá iyawo Peteru tí ibà dá dùbúlẹ̀.


Matiu 8:15
Jesu bá fi ọwọ́ kàn án lọ́wọ́, ibà náà sì fi í sílẹ̀. Ó bá dìde, ó bá tọ́jú oúnjẹ fún un.


Matiu 8:18
Nígbà tí Jesu rí ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n yí i ká, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn kọjá sí òdìkejì òkun.


Matiu 8:20
Jesu wí fún un pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́; ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”


Matiu 8:22
Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ tẹ̀lé mi, jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn.”


Matiu 8:23
Jesu wọ ọkọ̀ ojú omi kan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e.


Matiu 8:24
Ìgbì líle kan sì dé lójú omi òkun; ó pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó jẹ́ pé omi fẹ́rẹ̀ bo ọkọ̀; ṣugbọn Jesu sùnlọ.


Matiu 8:31
Àwọn ẹ̀mí èṣù náà bá bẹ Jesu pé, “Bí o óo bá lé wa jáde, lé wa lọ sinu agbo ẹlẹ́dẹ̀ ọ̀hún nnì.”


Matiu 8:32
Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ lọ!” Wọ́n bá jáde lọ sí inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀. Gbogbo agbo ẹlẹ́dẹ̀ bá dorí kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà, wọ́n sáré lọ, wọ́n sì rì sómi.


Matiu 8:34
Gbogbo ìlú bá jáde lọ pàdé Jesu. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó kúrò ní agbègbè wọn.


Matiu 9:1
Jesu wọ inú ọkọ̀, ó rékọjá sí òdìkejì òkun, ó bá dé ìlú ara rẹ̀.


Matiu 9:2
Àwọn kan bá gbé arọ kan wá, ó dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ṣe ara gírí, ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”


Matiu 9:4
Ṣugbọn Jesu mọ èrò inú wọn; ó bá bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro èrò burúkú ninu ọkàn yín?


Matiu 9:9
Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó rí ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Matiu tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.” Kíá, ó bá dìde, ó ń tẹ̀lé e.


Matiu 9:10
Matiu se àsè ní ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wọ́n wá, tí wọn ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun.


Matiu 9:12
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá.


Matiu 9:15
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa ṣọ̀fọ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà lọ́dọ̀ wọn. Àkókò ń bọ̀ nígbà tí a óo gba ọkọ iyawo lọ́wọ́ wọn; wọn yóo máa gbààwẹ̀ nígbà náà.


Matiu 9:18
Bí Jesu tí ń sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, ìjòyè kan wá, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Ọmọdebinrin mi ṣẹ̀ṣẹ̀ kú nisinsinyii ni, ṣugbọn wá gbé ọwọ́ rẹ lé e, yóo sì yè.”


Matiu 9:19
Jesu bá dìde. Ó ń tẹ̀lé e lọ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.


Matiu 9:20
Obinrin kan wà, tí nǹkan oṣù rẹ̀ kò tètè dá rí fún ọdún mejila, ó gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ Jesu;


Matiu 9:22
Jesu bá yipada, ó rí obinrin náà, ó ní, “Ṣe ara gírí, ọmọbinrin. Igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Ara obinrin náà bá dá láti àkókò náà lọ.


Matiu 9:23
Nígbà tí Jesu dé ilé ìjòyè náà, ó rí àwọn tí wọn ń fun fèrè ati ọ̀pọ̀ eniyan tí wọn ń ké.


Matiu 9:27
Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, àwọn afọ́jú meji kan tẹ̀lé e, wọ́n ń kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”


Matiu 9:28
Nígbà tí ó wọ inú ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ lọ. Jesu bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gbàgbọ́ pé mo lè wò yín sàn?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa.”


Matiu 9:30
Ojú wọn bá là. Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gidigidi, ó ní “Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀.”


Matiu 9:32
Bí àwọn afọ́jú náà ti jáde, bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan mú ọkunrin kan, tí ẹ̀mí èṣù mú kí ó yadi, wá sọ́dọ̀ Jesu.


Matiu 9:35
Jesu ń rìn kiri ní gbogbo àwọn ìlú ati àwọn ìletò, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu àwọn ilé ìpàdé, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó sì ń wo oríṣìíríṣìí àrùn ati àìlera sàn.


Matiu 10:1
Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila sọ́dọ̀, ó fún wọn ní àṣẹ láti máa lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ati láti máa ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àrùn ati àìsàn.


Matiu 10:4
Simoni ará Kenaani ati Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.


Matiu 10:5
Àwọn mejila yìí ni Jesu rán níṣẹ́, ó pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má gba ọ̀nà ìlú àwọn tí kì í ṣe Juu lọ; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má wọ ìlú àwọn ará Samaria.


Matiu 11:1
Lẹ́yìn tí Jesu ti fi gbogbo ìlànà wọnyi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mejila tán, ó kúrò níbẹ̀ lọ sí àwọn ìlú wọn, ó ń kọ àwọn eniyan ó sì ń waasu.


Matiu 11:2
Johanu gbọ́ ninu ẹ̀wọ̀n nípa iṣẹ́ tí Jesu ń ṣe. Ó bá rán àwọn kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọ́n lọ bi í pé,


Matiu 11:4
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ lọ ròyìn ohun tí ẹ ti gbọ́ ati ohun tí ẹ ti rí fún Johanu. Ẹ sọ fún un pé,


Matiu 11:7
Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Johanu pada lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún àwọn eniyan nípa Johanu pé, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Ṣé koríko tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín, sọ́hùn-ún? Rárá o!


Matiu 11:20
Nígbà náà ni Jesu bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn ìlú wọ̀n-ọn-nì wí níbi tí ó ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu pupọ jùlọ, nítorí wọn kò ronupiwada.


Matiu 11:25
Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè.


Matiu 12:1
Ní àkókò náà Jesu ń la oko ọkà kan kọjá ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu. Ebi ń pa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń jẹ ẹ́.


Matiu 12:3
Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò kà nípa ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?


Matiu 12:9
Lẹ́yìn èyí, Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí inú ilé ìpàdé wọn.


Matiu 12:15
Nígbà tí Jesu mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó bá kúrò níbẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan sì tẹ̀lé e, ó sì wo gbogbo wọn sàn.


Matiu 12:22
Nígbà náà wọ́n mú ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu tí ó ní ẹ̀mí èṣù; ẹ̀mí èṣù yìí ti fọ́ ọ lójú, ó sì mú kí ó yadi. Jesu bá wò ó sàn; ọkunrin náà bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì ríran.


Matiu 12:25
Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń rò. Ó bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo ìlúkílùú tabi ilékílé tí àwọn eniyan ibẹ̀ bá ń bá ara wọn jà yóo tú.


Matiu 12:39
Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìran burúkú ati ìran oníbọkúbọ ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fi fún un àfi àmì Jona wolii.


Matiu 12:46
Bí Jesu ti ń bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀ ni ìyá rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀ bá dé, wọ́n dúró lóde, wọ́n fẹ́ bá a sọ̀rọ̀. [


Matiu 12:48
Jesu dá a lóhùn pé, “Ta ni ìyá mi? Àwọn ta sì ni arakunrin mi?”


Matiu 13:1
Ní ọjọ́ kan náà, Jesu jáde kúrò nílé, ó lọ jókòó létí òkun.


Matiu 13:34
Jesu sọ gbogbo nǹkan wọnyi fún àwọn eniyan ní òwe. Kò sọ ohunkohun fún wọn láì lo òwe;


Matiu 13:36
Nígbà tí Jesu kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan, ó lọ sinu ilé. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sọ pé, “Ṣe àlàyé òwe èpò inú oko fún wa.”


Matiu 13:51
Jesu bi wọ́n pé, “Ṣé gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ye yín?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni.”


Matiu 13:53
Lẹ́yìn tí Jesu ti parí gbogbo àwọn òwe wọnyi, ó kúrò níbẹ̀.


Matiu 13:57
Wọ́n sì kọ̀ ọ́. Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì àfi ní ìlú baba rẹ̀ ati ní ilé rẹ̀.”


Matiu 14:1
Ní àkókò náà, Hẹrọdu ọba gbúròó Jesu.


Matiu 14:12
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu bá wá, wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ, wọ́n sin ín; wọ́n sì lọ ròyìn fún Jesu.


Matiu 14:13
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wọ ọkọ̀ ojú omi kúrò níbẹ̀ lọ sí ibìkan tí eniyan kò sí, kí ó lè dá wà. Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, wọ́n gba ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ láti ìlú wọn, wọ́n tẹ̀lé e.


Matiu 14:16
Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Kò yẹ kí wọ́n lọ; ẹ fún wọn ní oúnjẹ jẹ.”


Matiu 14:25
Nígbà tí ó di nǹkan bí agogo mẹta òru, Jesu ń bọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó ń rìn lójú omi òkun.


Matiu 14:27
Lẹsẹkẹsẹ Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣe ara gírí. Èmi ni. Ẹ má bẹ̀rù!”


Matiu 14:29
Jesu bá sọ fún un pé, “Máa bọ̀!” Ni Peteru bá sọ̀kalẹ̀ ninu ọkọ̀, ó rìn lójú omi lọ sọ́dọ̀ Jesu.


Matiu 14:31
Lẹsẹkẹsẹ Jesu bá fà á lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ìwọ onigbagbọ kékeré yìí! Kí ni ó mú ọ ṣe iyè meji?”


Matiu 15:1
Nígbà náà ni àwọn Farisi ati àwọn amòfin wá sọ́dọ̀ Jesu láti Jerusalẹmu, wọ́n bi í pé,


Matiu 15:3
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀yin náà ṣe ń fi àṣà ìbílẹ̀ yín rú òfin Ọlọrun?


Matiu 15:13
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Gbogbo igi tí Baba mi tí ń bẹ lọ́run kò bá gbìn ni a óo hú dànù.


Matiu 15:16
Jesu dá a lóhùn pé, “Kò ì tíì yé ẹ̀yin náà títí di ìwòyí?


Matiu 15:21
Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Tire ati Sidoni.


Matiu 15:23
Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá wá sọ fún un pé, “Lé obinrin yìí lọ, nítorí ó ń pariwo tẹ̀lé wa lẹ́yìn.”


Matiu 15:24
Jesu bá dáhùn pé, “Kìkì àwọn aguntan tí ó sọnù, àní ìdílé Israẹli nìkan ni a rán mi sí.”


Matiu 15:26
Ṣugbọn Jesu dá a lóhùn pé, “Kò dára láti sọ oúnjẹ ọmọ eniyan sóde sí àwọn ajá!”


Matiu 15:28
Nígbà náà ni Jesu sọ fún un pé, “Obinrin yìí! Igbagbọ rẹ tóbi gidi. Kí ó rí fún ọ bí o ti fẹ́.” Ara ọdọmọbinrin rẹ̀ bá dá láti àkókò náà.


Matiu 15:29
Nígbà tí Jesu kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ẹ̀bá òkun Galili; ó gun orí òkè lọ, ó bá jókòó níbẹ̀.


Matiu 15:32
Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ́dọ̀ ó ní, “Àánú àwọn eniyan wọnyi ń ṣe mí, nítorí ó di ọjọ́ mẹta tí wọ́n ti wà lọ́dọ̀ mi; wọn kò ní oúnjẹ mọ́. N kò fẹ́ tú wọn ká pẹlu ebi ninu, kí òòyì má baà gbé wọn lọ́nà.”


Matiu 15:34
Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n ní, “Meje, ati ẹja kéékèèké díẹ̀.”


Matiu 15:35
Jesu pàṣẹ kí àwọn eniyan jókòó nílẹ̀.


Matiu 15:39
Lẹ́yìn tí Jesu ti tú àwọn eniyan ká, ó wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó bá lọ sí agbègbè Magadani.


Matiu 16:1
Àwọn Farisi ati àwọn Sadusi wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n ń dán an wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run han àwọn.


Matiu 16:6
Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gáfárà fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati àwọn Sadusi.”


Matiu 16:8
Ṣugbọn Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń sọ láàrin ara yín nípa oúnjẹ tí ẹ kò ní, ẹ̀yin onigbagbọ kékeré?


Matiu 16:13
Nígbà tí Jesu dé agbègbè ìlú Kesaria ti Filipi, ó bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé Ọmọ-Eniyan jẹ́?”


Matiu 16:17
Jesu sọ fún un pé, “O káre, Simoni, ọmọ Jona, nítorí kì í ṣe eniyan ni ó fi èyí hàn ọ́ bíkòṣe Baba mi tí ń bẹ lọ́run.


Matiu 16:20
Nígbà náà ni Jesu wá pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Mesaya.


Matiu 16:21
Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí máa fihan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé dandan ni kí òun lọ sí Jerusalẹmu, kí òun jìyà pupọ lọ́wọ́ àwọn àgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin; ati pé kí wọ́n pa òun, ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí òun dìde.


Matiu 16:23
Ṣugbọn Jesu yipada, ó sọ fún Peteru pé, “Kó ara rẹ̀ kúrò níwájú mi, Satani. Ohun ìkọsẹ̀ ni o jẹ́ fún mi, nítorí o kò ro nǹkan ti Ọlọrun, ti eniyan ni ò ń rò.”


Matiu 16:24
Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, ó níláti sẹ́ ara rẹ̀, kí ó gbé agbelebu rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.


Matiu 17:1
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu arakunrin Jakọbu, wọ́n lọ sí orí òkè gíga kan; àwọn nìkan wà níbẹ̀.


Matiu 17:2
Jesu bá para dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ wá ń tàn bí oòrùn. Aṣọ rẹ̀ mọ́ gbòò bí ọjọ́.


Matiu 17:3
Wọ́n wá rí Mose ati Elija tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀.


Matiu 17:4
Peteru bá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, kì bá dára kí á máa gbé ìhín. Bí o bá fẹ́, èmi yóo pa àgọ́ mẹta síhìn-ín, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.”


Matiu 17:7
Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó fọwọ́ kàn wọ́n, ó ní, “Ẹ dìde. Ẹ má bẹ̀rù.”


Matiu 17:8
Nígbà tí wọ́n gbé ojú wọn sókè, wọn kò rí ẹnikẹ́ni mọ́, àfi Jesu nìkan.


Matiu 17:9
Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má sọ ohun tí ẹ rí fún ẹnikẹ́ni títí a óo fi jí Ọmọ-Eniyan dìde kúrò ninu òkú.”


Matiu 17:14
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan, ọkunrin kan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀.


Matiu 17:17
Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ ati ìran tí ó bàjẹ́ yìí, ìgbà wo ni n óo wà lọ́dọ̀ yín dà? Ìgbà wo ni n óo sì fara dà á fun yín dà? Ẹ mú ọmọ náà wá síhìn-ín.”


Matiu 17:18
Jesu bá pàṣẹ fún ẹ̀mí èṣù náà kí ó jáde kúrò ninu rẹ̀, ara ọmọ náà sì dá láti ìgbà náà.


Matiu 17:19
Nígbà tí ó yá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu níkọ̀kọ̀, wọn bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?”


Matiu 17:22
Nígbà tí wọ́n péjọ ní Galili Jesu sọ fún wọn pé, “A óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn eniyan lọ́wọ́,


Matiu 17:25
Ó ní, “Kí ló dé? A máa san án.” Nígbà tí ó dé ilé, Jesu ló ṣáájú rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó ní, “Kí ni o rò, Simoni? Lọ́wọ́ àwọn ta ni àwọn ọba ayé ti ń gba owó-orí tabi owó-odè? Lọ́wọ́ àwọn ọmọ onílẹ̀ ni tabi lọ́wọ́ àlejò?”


Matiu 17:26
Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àlejò ni.” Jesu wá sọ fún un pé, “Èyí ni pé kò kan àwọn ọmọ onílẹ̀.


Matiu 18:1
Ní àkókò náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Ta ní ṣe pataki jùlọ ní ìjọba ọ̀run?”


Matiu 18:2
Jesu bá pe ọmọde kan, ó mú un dúró láàrin wọn,


Matiu 18:21
Nígbà náà ni Peteru wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Oluwa, ìgbà mélòó ni arakunrin mi óo ṣẹ̀ mí tí n óo dáríjì í? Ṣé kí ó tó ìgbà meje?”


Matiu 18:22
Jesu dá a lóhùn pé, “N kò sọ fún ọ pé ìgbà meje; ṣugbọn kí ó tó ìgbà meje lọ́nà aadọrin!


Matiu 19:1
Nígbà tí Jesu parí àwọn ọ̀rọ̀ wọnyi, ó kúrò ní Galili, ó dé ìgbèríko Judia ní òdìkejì odò Jọdani.


Matiu 19:8
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Nítorí líle ọkàn yín ni Mose fi gbà fun yín láti kọ aya yín sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.


Matiu 19:13
Ní àkókò yìí ni wọ́n gbé àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ Jesu, kí ó lè gbé ọwọ́ lé wọn, kí ó sì súre fún wọn. Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá àwọn tí wọn gbé wọn wá wí.


Matiu 19:14
Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi; ẹ má dí wọn lọ́nà, nítorí ti irú wọn ni ìjọba ọ̀run.”


Matiu 19:16
Nígbà kan, ẹnìkan wá sọ́dọ̀ Jesu, ó bi í pé, “Olùkọ́ni, nǹkan rere wo ni kí n ṣe kí n lè ní ìyè ainipẹkun?”


Matiu 19:17
Jesu sọ fún un pé, “Nítorí kí ni o ṣe ń bi mí nípa ohun rere? Ẹni rere kanṣoṣo ni ó wà. Bí o bá fẹ́ wọ inú ìyè, pa àwọn òfin mọ́.”


Matiu 19:18
Ó bi Jesu pé, “Òfin bí irú èwo?” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa eniyan. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe àgbèrè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè. Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké.


Matiu 19:20
Ọdọmọkunrin náà sọ fún Jesu pé, “Gbogbo òfin wọnyi ni mo ti pamọ́. Kí ni ó tún kù kí n ṣe?”


Matiu 19:21
Jesu sọ fún un pé, “Bí o bá fẹ́ ṣe àṣepé, lọ ta dúkìá rẹ, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka; o óo sì ní ìṣúra ní ọ̀run. Lẹ́yìn náà, máa tẹ̀lé mi.”


Matiu 19:23
Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé yóo ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba ọ̀run.


Matiu 19:26
Jesu wò wọ́n lójú, ó sọ fún wọn pé, “Èyí kò ṣeéṣe fún eniyan; ṣugbọn ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún Ọlọrun.”


Matiu 19:28
Jesu sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, nígbà tí ó bá di àkókò àtúndá ayé, tí Ọmọ-Eniyan bá jókòó lórí ìtẹ́ ìgúnwà rẹ̀, ẹ̀yin náà tí ẹ tẹ̀lé mi yóo jókòó lórí ìtẹ́ mejila, ẹ óo máa ṣe ìdájọ́ lórí ẹ̀yà Israẹli mejila.


Matiu 20:17
Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ní ọ̀nà, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, níkọ̀kọ̀, ó sọ fún wọn pé,


Matiu 20:20
Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede wá sọ́dọ̀ Jesu pẹlu àwọn ọmọ rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó ń bèèrè nǹkankan lọ́dọ̀ rẹ̀.


Matiu 20:21
Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́?” Ó ní, “Gbà pé kí àwọn ọmọ mi mejeeji yìí jókòó pẹlu rẹ ní ìjọba rẹ, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún ekeji ní ọwọ́ òsì.”


Matiu 20:22
Jesu dáhùn pé, “Ẹ kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lè mu ún.”


Matiu 20:25
Ṣugbọn Jesu pè wọ́n sọ́dọ̀, ó ní, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá láàrin wọn a sì máa lo agbára lórí wọn.


Matiu 20:29
Bí Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, ọ̀pọ̀ eniyan tẹ̀lé e.


Matiu 20:30
Àwọn afọ́jú meji kan jókòó lẹ́bàá ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n kígbe pé, “Ọmọ Dafidi, ṣàánú wa.”


Matiu 20:32
Jesu bá dúró, ó pè wọ́n, ó ní, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”


Matiu 20:34
Àánú wọn ṣe Jesu, ó bá fi ọwọ́ kàn wọ́n lójú. Wọ́n ríran lẹsẹkẹsẹ, wọ́n bá ń tẹ̀lé e.


Matiu 21:1
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Jerusalẹmu, tí wọ́n dé Bẹtifage ní Òkè Olifi, Jesu rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji lọ ṣiwaju.


Matiu 21:6
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà lọ, wọ́n ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn.


Matiu 21:7
Wọ́n fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ati ọmọ rẹ̀ wá, wọ́n tẹ́ aṣọ lé wọn lórí, Jesu bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn.


Matiu 21:10
Nígbà tí Jesu wọ Jerusalẹmu, gbogbo ìlú mì tìtì. Àwọn ará ìlú ń bèèrè pé, “Ta nìyí?”


Matiu 21:11
Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.”


Matiu 21:12
Jesu bá wọ inú Tẹmpili lọ, ó lé gbogbo àwọn tí wọn ń tà, tí wọn ń rà kúrò níbẹ̀. Ó ti tabili àwọn tí wọn ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó ṣubú. Ó da ìsọ̀ àwọn tí wọn ń ta ẹyẹlé rú.


Matiu 21:15
Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin rí àwọn ohun ìyanu tí Jesu ṣe, tí wọ́n tún gbọ́ bí àwọn ọmọde ti ń kígbe ninu Tẹmpili pé, “Hosana fún Ọmọ Dafidi,” inú wọn ru.


Matiu 21:16
Wọ́n sọ fún un pé, “O kò gbọ́ ohun tí àwọn wọnyi ń wí ni?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo gbọ́. Ẹ kò tíì kà á pé, ‘Lẹ́nu àwọn ọmọ-ọwọ́ ati àwọn ọmọ-ọmú ni ìwọ ti gba ìyìn pípé?’ ”


Matiu 21:21
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ bá ní igbagbọ, láì ṣiyèméjì, ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí nìkan kọ́ ni ẹ óo ṣe, ṣugbọn bí ẹ bá sọ fún òkè yìí pé, ‘Dìde, kí o lọ rì sinu òkun,’ bẹ́ẹ̀ ni yóo rí.


Matiu 21:23
Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?”


Matiu 21:24
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi náà yóo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan. Tí ẹ bá dá mi lóhùn, èmi náà yóo wá sọ irú agbára tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi.


Matiu 21:27
Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fun yín.”


Matiu 21:31
Ninu àwọn mejeeji, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?” Wọ́n ní, “Ekinni ni.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó yóo ṣáájú yín wọ ìjọba Ọlọrun.


Matiu 21:33
Jesu ní, “Ẹ tún gbọ́ òwe mìíràn. Baba kan wà tí ó gbin èso àjàrà sí oko rẹ̀. Ó ṣe ọgbà yí i ká; ó wa ilẹ̀ ìfúntí sibẹ; ó kọ́ ilé-ìṣọ́ sí i; ó bá fi í lé àwọn alágbàro lọ́wọ́, ó lọ sí ìdálẹ̀.


Matiu 21:42
Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ kò ì tíì kà ninu Ìwé Mímọ́ pé, ‘Òkúta tí àwọn tí ń mọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki ní igun ilé. Iṣẹ́ Oluwa ni èyí, ìyanu ni ó jẹ́ lójú wa.’


Matiu 22:1
Jesu tún fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀. Ó ní,


Matiu 22:15
Àwọn Farisi bá lọ forí-korí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ Jesu lẹ́nu.


Matiu 22:18
Ṣugbọn Jesu mọ èrò ibi tí ó wà lọ́kàn wọn. Ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí ẹ̀yin alárèékérekè yìí?


Matiu 22:29
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.


Matiu 22:37
Jesu dá a lóhùn pé, “ ‘Fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ pẹlu gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo ẹ̀mí rẹ, ati ní gbogbo èrò rẹ.’


Matiu 22:41
Nígbà tí àwọn Farisi péjọ pọ̀, Jesu bi wọ́n pé,


Matiu 23:1
Jesu bá sọ fún àwọn eniyan ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,


Matiu 24:1
Jesu jáde kúrò ninu Tẹmpili. Bí ó ti ń lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá, wọ́n pe akiyesi rẹ̀ sí bí a ti ṣe kọ́ ilé náà.


Matiu 24:3
Nígbà tí Jesu jókòó lórí Òkè Olifi, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n bi í pé, “Sọ fún wa, nígbà wo ni gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀, kí sì ni àmì àkókò wíwá rẹ ati ti òpin ayé?”


Matiu 24:4
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má baà tàn yín jẹ.


Matiu 26:1
Nígbà tí Jesu parí gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,


Matiu 26:4
Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á.


Matiu 26:6
Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, ninu ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí,


Matiu 26:7
obinrin kan wọlé tọ̀ ọ́ wá tí ó ní ìgò òróró iyebíye olóòórùn dídùn, ni ó bá bẹ̀rẹ̀ sí tú u sí orí Jesu níbi tí ó ti ń jẹun.


Matiu 26:8
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu rí i, inú bí wọn. Wọ́n ní, “Kí ni ìdí irú òfò báyìí?


Matiu 26:10
Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, nítorí náà, ó wí fún wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń da obinrin yìí láàmú sí? Nítorí iṣẹ́ rere ni ó ṣe sí mi lára.


Matiu 26:15
Ó bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ óo fún mi bí mo bá fi Jesu le yín lọ́wọ́?” Wọ́n bá ka ọgbọ̀n owó fadaka fún un.


Matiu 26:17
Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?”


Matiu 26:19
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà ṣe bí Jesu ti pàṣẹ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.


Matiu 26:25
Nígbà náà ni Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, bi í pé, “Àbí èmi ni, Olùkọ́ni?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”


Matiu 26:26
Nígbà tí wọn ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó bá fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀; ó ní, “Ẹ gbà, ẹ jẹ ẹ́, èyí ni ara mi.”


Matiu 26:31
Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’


Matiu 26:34
Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé ní alẹ́ yìí, kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”


Matiu 26:36
Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ Gẹtisemani. Ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ẹ jókòó níhìn-ín, èmi ń lọ gbadura lọ́hùn-ún nì.”


Matiu 26:47
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni Judasi, ọ̀kan ninu àwọn mejila yọ, pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú.


Matiu 26:49
Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ Jesu, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o, Olùkọ́ni.” Ni ó bá da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.


Matiu 26:50
Jesu sọ fún un pé, “Ọ̀rẹ́ kí ló dé o?” Nígbà náà ni àwọn eniyan wá, wọ́n ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un.


Matiu 26:51
Ọ̀kan ninu àwọn tí ó wà pẹlu Jesu bá na ọwọ́, ó fa idà yọ, ó sì fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa kan, ó gé e létí.


Matiu 26:52
Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Ti idà rẹ bọ inú akọ rẹ̀ pada, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá ń fa idà yọ, idà ni a óo fi pa wọ́n.


Matiu 26:55
Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!


Matiu 26:57
Àwọn tí wọ́n mú Jesu fà á lọ sọ́dọ̀ Kayafa Olórí Alufaa, níbi tí àwọn amòfin ati àwọn àgbà ti pé jọ sí.


Matiu 26:58
Peteru ń tẹ̀lé Jesu, ó ń bọ̀ lẹ́yìn patapata, títí ó fi dé àgbàlá Olórí Alufaa. Ó wọlé, ó jókòó pẹlu àwọn ẹ̀ṣọ́ láti rí ibi tí gbogbo rẹ̀ yóo yọrí sí.


Matiu 26:59
Àwọn olórí alufaa ati gbogbo ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí èké tí ó lè kóbá Jesu kí wọn baà lè pa á.


Matiu 26:63
Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.”


Matiu 26:64
Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnu ara rẹ ni o fi sọ ọ́; ṣugbọn mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé láti ìsinsìnyìí lọ, ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.”


Matiu 26:69
Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.”


Matiu 26:71
Bí ó ti ń lọ sí ẹnu ọ̀nà, iranṣẹbinrin mìíràn tún rí i, ó bá sọ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”


Matiu 26:75
Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ, pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.” Ó bá bọ́ sóde, ó sọkún gidigidi.


Matiu 27:1
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú jọ forí-korí nípa ọ̀ràn Jesu, kí wọ́n lè pa á.


Matiu 27:3
Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rí i pé a dá Jesu lẹ́bi, ó ronupiwada. Ó bá lọ dá ọgbọ̀n owó fadaka pada fún àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà.


Matiu 27:11
Jesu bá dúró siwaju gomina. Gomina bi í pé, “Ìwọ ni ọba àwọn Juu bí?” Jesu ní, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”


Matiu 27:14
Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn gbolohun kan ṣoṣo, tí ó fi jẹ́ pé ẹnu ya gomina pupọ.


Matiu 27:16
Ní àkókó náà, ẹlẹ́wọ̀n olókìkí kan wà tí ó ń jẹ́ Jesu Baraba.


Matiu 27:17
Nígbà tí àwọn Juu pésẹ̀, Pilatu bi wọ́n pé, “Ta ni kí n dá sílẹ̀ fun yín, Jesu Baraba ni tabi Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?”


Matiu 27:20
Àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ti rọ àwọn eniyan láti bèèrè fún Baraba, kí wọ́n pa Jesu.


Matiu 27:22
Pilatu wá bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe sí Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?” Gbogbo wọn dáhùn pé, “Kàn án mọ́ agbelebu.”


Matiu 27:26
Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí ó ti pàṣẹ pé kí wọ́n na Jesu ní pàṣán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti kàn mọ̀ agbelebu.


Matiu 27:27
Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí.


Matiu 27:32
Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu.


Matiu 27:37
Wọ́n fi àkọlé kan kọ́ sí òkè orí rẹ̀, wọ́n kọ ẹ̀sùn tí a fi kàn án sibẹ pé, “Eléyìí ni Jesu ọba àwọn Juu.”


Matiu 27:46
Nígbà tí ó tó nǹkan bí agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe ní ohùn rara pé, “Eli, Eli, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi! Ọlọrun mi! Kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”


Matiu 27:50
Jesu bá tún kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀, ó bá dákẹ́.


Matiu 27:53
Wọ́n jáde kúrò ninu ibojì lẹ́yìn tí Jesu ti jí dìde, wọ́n wọ Jerusalẹmu lọ, ọpọlọpọ eniyan ni ó rí wọn.


Matiu 27:54
Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”


Matiu 27:55
Ọ̀pọ̀ àwọn obinrin wà níbẹ̀ tí wọ́n dúró ní òkèèrè réré, tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ni wọ́n tí ń tẹ̀lé Jesu láti Galili, tí wọn ń ṣe iranṣẹ fún un.


Matiu 27:57
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan, ará Arimatia tí ó ń jẹ́ Josẹfu wá. Òun náà jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.


Matiu 27:58
Ó tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu. Pilatu bá pàṣẹ pé kí wọ́n fún un.


Matiu 28:1
Nígbà tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, Maria Magidaleni ati Maria keji wá wo ibojì Jesu.


Matiu 28:5
Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá.


Matiu 28:9
Lójijì Jesu pàdé wọn, ó kí wọn, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o!” Wọ́n bá dì mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n júbà rẹ̀.


Matiu 28:10
Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arakunrin mi pé kí wọ́n lọ sí Galili; níbẹ̀ ni wọn yóo ti rí mi.”


Matiu 28:16
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla lọ sí Galili, sí orí òkè tí Jesu ti sọ fún wọn.


Matiu 28:18
Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé.


Marku 1:1
Bí ìyìn rere Jesu Kristi Ọmọ Ọlọrun ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí:


Marku 1:9
Ní ọjọ́ kan, Jesu wá láti Nasarẹti ìlú kan ní Galili, Johanu bá ṣe ìrìbọmi fún un ninu odò Jọdani.


Marku 1:10
Bí Jesu ti ń jáde kúrò ninu omi, lẹ́sẹ̀ kan náà ó rí Ẹ̀mí Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí àdàbà tí ó bà lé e.


Marku 1:12
Lẹ́yìn èyí, Ẹ̀mí Ọlọrun gbé Jesu lọ sinu aṣálẹ̀.


Marku 1:14
Lẹ́yìn ìgbà tí wọn ju Johanu sinu ẹ̀wọ̀n, Jesu wá sí Galili, ó ń waasu ìyìn rere tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá.


Marku 1:16
Bí Jesu ti ń rìn lọ lẹ́bàá òkun Galili, ó rí Simoni ati Anderu arakunrin rẹ̀ tí wọn ń da àwọ̀n sinu òkun, nítorí apẹja ni wọ́n.


Marku 1:17
Jesu bá wí fún wọn pé, “Ẹ wá máa tẹ̀lé mi, èmi yóo sọ yín di ẹni tí ó ń fa eniyan bí a ti ń dẹ ẹja ninu omi.”


Marku 1:20
Bí Jesu ti rí wọn, ó pè wọ́n. Wọ́n bá fi Sebede baba wọn sílẹ̀ ninu ọkọ̀ pẹlu àwọn alágbàṣe, wọ́n ń tẹ̀lé e.


Marku 1:21
Wọ́n lọ sí Kapanaumu. Ní Ọjọ́ Ìsinmi àwọn Juu, Jesu lọ sí ilé ìpàdé, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan.


Marku 1:24
“Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o dé láti pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ Ọlọrun ni ọ́.”


Marku 1:25
Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí.”


Marku 1:28
Òkìkí Jesu wá kan ká gbogbo ìgbèríko Galili.


Marku 1:29
Bí wọ́n ti jáde kúrò ninu ilé ìpàdé, Jesu pẹlu Jakọbu ati Johanu lọ sí ilé Simoni ati Anderu.


Marku 1:30
Ìyá iyawo Simoni wà ní ìdùbúlẹ̀ àìsàn ibà. Lẹsẹkẹsẹ wọ́n sọ fún Jesu nípa rẹ̀.


Marku 1:35
Ní òwúrọ̀ kutukutu kí ilẹ̀ tó mọ́, Jesu dìde, ó jáde kúrò ní ilé, ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú láti gbadura níbi tí kò sí ẹnìkankan.


Marku 1:41
Àánú ṣe Jesu ó bá na ọwọ́ ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́. Di mímọ́.”


Marku 1:43
Jesu fi ohùn líle kìlọ̀ fún un, lẹsẹkẹsẹ ó bá ní kí ó máa lọ.


Marku 1:45
Ṣugbọn ọkunrin náà jáde lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ fún ọpọlọpọ eniyan, ó ń rán ọ̀rọ̀ náà mọ́ ẹnu, tóbẹ́ẹ̀ tí Jesu kò fi lè wọ inú ìlú ní gbangba mọ́, ṣugbọn ó lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí eniyan. Sibẹ àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ibi gbogbo.


Marku 2:1
Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, Jesu tún lọ sí Kapanaumu, àwọn eniyan gbọ́ pé ó wà ninu ilé kan.


Marku 2:4
Nígbà tí wọn kò lè gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n dá òrùlé lu ní ọ̀kánkán ibi tí Jesu wà. Nígbà tí wọ́n ti dá a lu tán, wọ́n sọ ọkunrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ibùsùn rẹ̀.


Marku 2:5
Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó wí fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”


Marku 2:8
Ṣugbọn Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé wọ́n ń ro èrò báyìí ninu ọkàn wọn. Ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń kùn sinu?


Marku 2:13
Jesu tún jáde lọ sí ẹ̀bá òkun, gbogbo àwọn eniyan ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá ń kọ́ wọn.


Marku 2:15
Bí Jesu ti jókòó ní ilé Lefi, ọpọlọpọ àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ń bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jẹun, nítorí wọ́n pọ̀ tí wọn ń tẹ̀lé e.


Marku 2:17
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá: èmi kò wá láti pe àwọn olódodo bíkòṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.”


Marku 2:18
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn Farisi ń gbààwẹ̀ ní àkókò kan. Àwọn kan wá, wọ́n ń bi Jesu pé, “Kí ló dé tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn Farisi a máa gbààwẹ̀ ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tìrẹ kì í gbààwẹ̀?”


Marku 2:19
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ nígbà tí ọkọ iyawo wà lọ́dọ̀ wọn, níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn, wọ́n kò lè máa gbààwẹ̀.


Marku 2:23
Ní àkókò kan ní Ọjọ́ Ìsinmi, bí Jesu ti ń la ààrin oko ọkà kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà jẹ bí wọn tí ń lọ lọ́nà.


Marku 2:25
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe, nígbà tí kò ní oúnjẹ, tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?


Marku 3:1
Jesu tún wọ inú ilé ìpàdé lọ. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ rẹ̀ kan rọ.


Marku 3:4
Jesu bá bi wọ́n léèrè pé, “Èwo ni ó dára: láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ni tabi láti ṣe ìbàjẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là ni tabi láti pa ẹ̀mí run?” Ṣugbọn wọn kò fọhùn.


Marku 3:5
Jesu wò yíká pẹlu ibinu, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí pé ọkàn wọn le. Ó wá wí fún ọkunrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ.” Ó bá nà án. Ọwọ́ rẹ̀ sì bọ́ sípò.


Marku 3:7
Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra lọ sí ẹ̀bá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan sì ń tẹ̀lé e. Wọ́n wá láti Galili ati Judia ati Jerusalẹmu;


Marku 3:19
ati Judasi Iskariotu ẹni tí ó fi Jesu fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.


Marku 3:20
Lẹ́yìn náà, Jesu wọ inú ilé lọ, àwọn eniyan tún pé jọ tóbẹ́ẹ̀ tí òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò fi lè jẹun.


Marku 3:23
Jesu wá pè wọ́n sọ́dọ̀, ó fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Báwo ni Satani ti ṣe lè lé Satani jáde?


Marku 3:30
(Jesu sọ èyí nítorí wọ́n ń wí pé ó ní ẹ̀mí Èṣù.)


Marku 4:1
Jesu tún bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn eniyan lẹ́bàá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi níláti bọ́ sin ọkọ̀ ojú omi kan, ó bá jókòó níbẹ̀ lójú omi. Gbogbo àwọn eniyan wà ní èbúté, wọ́n jókòó lórí iyanrìn.


Marku 4:9
Lẹ́yìn náà Jesu ní, “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́!”


Marku 4:21
Jesu bi wọ́n pé, “Eniyan a máa gbé fìtílà wọlé kí ó fi igbá bò ó, tabi kí ó gbé e sí abẹ́ ibùsùn? Mo ṣebí lórí ọ̀pá fìtílà ni à ń gbé e kà.


Marku 4:33
Pẹlu ọpọlọpọ irú òwe bẹ́ẹ̀ ni Jesu fi ń sọ̀rọ̀ ìyìn rere fún wọn, gẹ́gẹ́ bí òye wọn ti mọ láti lè gbọ́.


Marku 4:35
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ sí èbúté ní òdìkejì òkun.”


Marku 4:38
Jesu wà ní ẹ̀yìn ọkọ̀, ó fi ìrọ̀rí kan rọrí, ó bá sùn lọ. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ jí i, wọ́n ní, “Olùkọ́ni, o kò tilẹ̀ bìkítà bí a bá ṣègbé sinu omi!”


Marku 5:1
Jesu lọ sí òdìkejì òkun ní ilẹ̀ àwọn ará Geraseni.


Marku 5:6
Ṣugbọn nígbà tí ó rí Jesu lókèèrè, ó sáré, ó dọ̀bálẹ̀ níwájú rẹ̀.


Marku 5:7
Ó ké rara pé, “Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ọmọ Ọlọrun tí ó lógo jùlọ? Mo fi Ọlọrun bẹ̀ ọ́, má ṣe dá mi lóró.”


Marku 5:8
(Nítorí Jesu tí ń sọ pé kí ẹ̀mí èṣù náà jáde kúrò ninu ọkunrin náà.)


Marku 5:9
Jesu wá bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje ni mò ń jẹ́, nítorí a kò níye.”


Marku 5:10
Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu títí pé kí ó má ṣe lé wọn jáde kúrò ní agbègbè ibẹ̀.


Marku 5:15
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin náà tí ó ti jẹ́ wèrè rí, tí ó ti ní ẹgbaagbeje ẹ̀mí èṣù, ó jókòó, ó wọ aṣọ, iyè rẹ̀ sì ti bọ̀ sípò. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí ó rí i.


Marku 5:17
Àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ Jesu pé kí ó kúrò ní agbègbè wọn.


Marku 5:19
Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó sọ fún un pé, “Lọ sí ilé rẹ, sọ́dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sọ ohun tí Oluwa ti ṣe fún ọ ati bí ó ti ṣàánú rẹ.”


Marku 5:20
Ọkunrin náà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un ní agbègbè Ìlú Mẹ́wàá, ẹnu sì ya gbogbo eniyan tí ó gbọ́.


Marku 5:21
Nígbà tí Jesu tún rékọjá lọ sí òdìkejì òkun, ọpọlọpọ eniyan wọ́ jọ pọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀ lẹ́bàá òkun.


Marku 5:22
Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Jairu, aṣaaju kan ni ní ilé ìpàdé ibẹ̀. Nígbà tí ó rí Jesu, ó dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀,


Marku 5:24
Jesu bá bá a lọ. Bí ó ti ń lọ, ọpọlọpọ eniyan ń tẹ̀lé e, wọ́n ń fún un lọ́tùn-ún lósì.


Marku 5:27
Nígbà tí obinrin náà gbọ́ nípa Jesu, ó gba ààrin àwọn eniyan dé ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀,


Marku 5:30
Lójú kan náà Jesu mọ̀ ninu ara rẹ̀ pé agbára ìwòsàn jáde lára òun. Ó bá yipada sí àwọn eniyan, ó bèèrè pé, “Ta ni fọwọ́ kàn mí láṣọ?”


Marku 5:32
Ṣugbọn Jesu ń wò yíká láti rí ẹni tí ó fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀.


Marku 5:33
Obinrin náà mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun, ó bá yọ jáde. Ẹ̀rù bà á, ó ń gbọ̀n, ó bá wá kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó sọ gbogbo òtítọ́ ọ̀rọ̀ náà fún un.


Marku 5:34
Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní alaafia, o kò ní gbúròó àìsàn náà mọ́.”


Marku 5:35
Kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, ni àwọn kan bá dé láti ilé olórí ilé ìpàdé tí Jesu ń bá lọ sílé, wọ́n ní, “Ọmọdebinrin rẹ ti kú, kí ni o tún ń yọ olùkọ́ni lẹ́nu sí?”


Marku 5:36
Ṣugbọn Jesu kò pé òun gbọ́ ohun tí wọn ń sọ, ó wí fún ọkunrin náà pé, “Má bẹ̀rù, ṣá ti gbàgbọ́.”


Marku 5:38
Nígbà tí wọ́n dé ilé olórí ilé ìpàdé náà, Jesu rí bí gbogbo ilé ti dàrú, tí ẹkún ati ariwo ń sọ gèè.


Marku 5:43
Jesu wá kìlọ̀ fún wọn gan-an pé kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀. Ó ní kí wọn wá oúnjẹ fún ọmọde náà kí ó jẹ.


Marku 6:1
Jesu jáde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bá a lọ.


Marku 6:4
Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Kò sí wolii tí kò níyì, àfi ní ìlú ara rẹ̀, ati láàrin àwọn ará rẹ̀, ati ninu ẹbí rẹ̀.”


Marku 6:6
Ẹnu yà á nítorí aigbagbọ wọn. Jesu ń káàkiri gbogbo àwọn abúlé tí ó wà yíká, ó ń kọ́ àwọn eniyan.


Marku 6:14
Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.”


Marku 6:30
Àwọn aposteli Jesu pé jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo nǹkan tí wọ́n ti ṣe ati bí wọ́n ti kọ́ àwọn eniyan.


Marku 6:34
Nígbà tí Jesu jáde ninu ọkọ̀ ó rí ọpọlọpọ eniyan, àánú ṣe é nítorí wọ́n dàbí aguntan tí kò ní olùṣọ́. Ó bá bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ọpọlọpọ nǹkan.


Marku 6:37
Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní ohun tí wọn óo jẹ.” Wọ́n ní, “Ṣé kí á wá lọ ra oúnjẹ igba owó fadaka ni, kí a lè fún wọn jẹ!”


Marku 6:41
Jesu bá mú burẹdi marun-un ati ẹja meji náà, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó dúpẹ́. Ó bá bu burẹdi náà, ó fi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kí wọn pín in fún àwọn eniyan. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó pín ẹja meji náà fún gbogbo wọn.


Marku 6:48
Ó rí i pé pẹlu ipá ni wọ́n fi ń wa ọkọ̀, nítorí afẹ́fẹ́ ṣọwọ́ òdì sí wọn. Ó tó bí agogo mẹta òru kí Jesu tó máa lọ sọ́dọ̀ wọn. Ó ń rìn lórí omi, ó fẹ́ kọjá lára wọn.


Marku 6:55
Wọ́n bá ń súré láti gbogbo àdúgbò ibẹ̀, wọ́n ń gbé àwọn aláìsàn wọn lórí ibùsùn wá sí ibikíbi tí wọn bá gbọ́ pé Jesu wà.


Marku 7:1
Àwọn Farisi ati àwọn amòfin kan tí wọ́n wá láti Jerusalẹmu péjọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.


Marku 7:6
Jesu wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni Aisaya sọ ní àtijọ́ nípa ẹ̀yin àgàbàgebè, tí ó sì kọ ọ́ báyìí pé, ‘Ọlọrun wí pé: Ẹnu ni àwọn eniyan wọnyi fi ń yẹ́ mi sí, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi,


Marku 7:9
Jesu tún wí fún wọn pé, “Òtítọ́ ni pé ẹ pa àṣẹ Ọlọrun tì, kí ẹ lè mú àṣẹ ìbílẹ̀ yín ṣẹ.


Marku 7:24
Láti ibẹ̀ Jesu gbéra, ó lọ sí agbègbè ìlú Tire, ó sì wọ̀ sí ilé kan. Kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀, ṣugbọn kò lè fi ara pamọ́.


Marku 7:27
Jesu wí fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ rí oúnjẹ jẹ yó ná, nítorí kò dára kí á mú oúnjẹ ọmọ kí á sọ ọ́ fún ajá.”


Marku 7:29
Jesu dá a lóhùn pé, “Nítorí gbolohun rẹ yìí, máa lọ sí ilé rẹ, ẹ̀mí èṣù náà ti jáde kúrò ninu ọmọ rẹ.”


Marku 7:36
Jesu kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má wí fún ẹnikẹ́ni. Ṣugbọn bí ó ti ń kìlọ̀ fún wọn tó, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ròyìn rẹ̀ tó.


Marku 8:1
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí ọpọlọpọ eniyan tún wà lọ́dọ̀ Jesu, tí wọn kò rí nǹkan jẹ, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó wí fún wọn pé,


Marku 8:5
Jesu bi wọ́n pé, “Burẹdi mélòó ni ẹ ní?” Wọ́n ní, “Meje.”


Marku 8:8
Àwọn eniyan jẹ, wọ́n yó. Wọ́n bá kó ẹ̀rúnrún àjẹkù jọ, ó kún apẹ̀rẹ̀ ńlá meje. Àwọn eniyan tí wọn jẹun tó bí ẹgbaaji (4,000). Lẹ́yìn náà Jesu ní kí wọn túká.


Marku 8:14
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu gbàgbé láti mú burẹdi lọ́wọ́ àfi ọ̀kan ṣoṣo tí wọn ní ninu ọkọ̀ ojú omi.


Marku 8:15
Jesu bá kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi ati ìwúkàrà Hẹrọdu.”


Marku 8:17
Nígbà tí Jesu mọ ohun tí wọn ń sọ, ó bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàrin ara yín pé nítorí ẹ kò ní burẹdi lọ́wọ́ ni? Ẹ kò ì tíì mọ̀ sibẹ, tabi òye kò ì tíì ye yín? Àṣé ọkàn yín le tóbẹ́ẹ̀?


Marku 8:25
Lẹ́yìn náà Jesu tún fi ọwọ́ kàn án lójú. Ọkunrin náà tẹjú mọ́ àwọn nǹkan tí ó wà ní àyíká rẹ̀, ojú rẹ̀ sì bọ̀ sípò, ó wá rí gbogbo nǹkan kedere, títí kan ohun tí ó jìnnà.


Marku 8:26
Jesu wí fún un pé, kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀, kí ó má ṣe wọ inú abúlé lọ.


Marku 8:27
Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí àwọn abúlé tí ó wà lẹ́bàá ìlú Kesaria ti Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ ní ọ̀nà, ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan ń pè mí?”


Marku 8:33
Ṣugbọn Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó bá Peteru wí. Ó ní, “Kó ara rẹ kúrò níwájú mi, ìwọ Satani. Ìwọ kò kó ohun ti Ọlọrun lékàn àfi ti ayé.”


Marku 9:2
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹfa, Jesu mú Peteru ati Jakọbu ati Johanu lọ sí orí òkè gíga kan, àwọn mẹta yìí nìkan ni ó mú lọ. Ìrísí rẹ̀ bá yipada lójú wọn.


Marku 9:4
Wọ́n rí Elija pẹlu Mose tí wọn ń bá Jesu sọ̀rọ̀.


Marku 9:5
Peteru wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, ó dára tí a wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pàgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose ati ọ̀kan fún Elija.”


Marku 9:8
Lójijì, bí wọ́n ti wò yíká, wọn kò rí ẹnìkankan lọ́dọ̀ wọn mọ́, àfi Jesu nìkan.


Marku 9:9
Bí wọ́n ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà, Jesu pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ ròyìn ohun tí wọ́n ti rí fún ẹnikẹ́ni títí òun, Ọmọ-Eniyan, yóo fi jí dìde kúrò ninu òkú.


Marku 9:14
Nígbà tí Jesu dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó rí ọpọlọpọ eniyan pẹlu àwọn amòfin, wọ́n ti ń bá ara wọn jiyàn.


Marku 9:19
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ìran alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó? N óo ti fara dà á fun yín pẹ́ tó? Ẹ mú ọmọ náà wá.”


Marku 9:20
Wọ́n bá mú un lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ẹ̀mí burúkú yìí rí Jesu, ó mú kí gìrì ki ọmọ náà ní akọ, ó gbé e ṣánlẹ̀, ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí yí nílẹ̀, ó ń yọ ìfòòfó lẹ́nu.


Marku 9:21
Jesu wá bi baba ọmọ náà pé, “Ó ti tó ìgbà wo tí irú èyí ti ń ṣe é?” Baba rẹ̀ dáhùn pé, “Láti kékeré ni.”


Marku 9:23
Jesu wí fún un pé, “Ọ̀ràn bí èmi bá lè ṣe é kọ́ yìí, ohun gbogbo ni ó ṣeéṣe fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́.”


Marku 9:25
Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ìjọ eniyan ń sáré bọ̀, ó bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó ní, “Ìwọ ẹ̀mí tí o jẹ́ kí ọmọ yìí ya odi, tí o sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò ninu rẹ̀, kí o má tún wọ inú rẹ̀ mọ́.”


Marku 9:27
Ṣugbọn Jesu fà á lọ́wọ́, ó gbé e dìde, ọmọ náà bá nàró.


Marku 9:28
Nígbà tí Jesu wọ inú ilé, tí ó ku òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n ń bi í pé, “Kí ló dé tí àwa kò fi lè lé ẹ̀mí náà jáde?”


Marku 9:30
Láti ibẹ̀ wọ́n jáde lọ, wọ́n ń la Galili kọjá. Jesu kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ̀,


Marku 9:39
Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Ẹ má ṣe dá a lẹ́kun, nítorí kò sí ẹni tí yóo fi orúkọ mi ṣe iṣẹ́ ìyanu tí yóo yára sọ ọ̀rọ̀ ibi nípa mi.


Marku 10:1
Nígbà tí Jesu dìde kúrò níbẹ̀, ó lọ sí agbègbè Judia, ó rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani. Ọpọlọpọ àwọn eniyan tún lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó tún ń kọ́ wọn.


Marku 10:5
Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Nítorí oríkunkun yín ni Mose fi kọ òfin yìí.


Marku 10:14
Nígbà tí Jesu rí i inú bí i: ó wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí ti irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.


Marku 10:16
Nígbà náà ni Jesu gbé àwọn ọmọde náà lọ́wọ́, ó gbé ọwọ́ lé wọn, ó sì súre fún wọn.


Marku 10:17
Nígbà tí Jesu jáde, bí ó ti ń lọ lọ́nà, ọkunrin kan sáré tọ̀ ọ́ lọ, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bi í pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”


Marku 10:18
Ṣugbọn Jesu wí fún un pé, “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan, àfi Ọlọrun nìkan.


Marku 10:21
Jesu wá tẹjú mọ́ ọn, ó fi tìfẹ́tìfẹ́ wò ó, ó wí fún un pé, “Nǹkankan ló kù kí o ṣe: lọ ta ohun gbogbo tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn aláìní, o óo wá ní ọrọ̀ ní ọ̀run; lẹ́yìn náà wá, kí o máa tẹ̀lé mi.”


Marku 10:23
Jesu bá wo ọ̀tún, ó wo òsì, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Yóo ṣòro pupọ fún àwọn ọlọ́rọ̀ láti wọ ìjọba Ọlọrun!”


Marku 10:24
Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nítorí gbolohun yìí. Ṣugbọn Jesu tún wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọde, yóo ṣòro pupọ láti wọ ìjọba Ọlọrun!


Marku 10:27
Jesu tẹjú mọ́ wọn, ó wí pé, “Kò ṣeéṣe fún eniyan, ṣugbọn ti Ọlọrun kò rí bẹ́ẹ̀, nítorí pé, kò sí ohun tí Ọlọrun kò lè ṣe.”


Marku 10:29
Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kò sí ẹnìkan tí ó fi ilé tabi arakunrin tabi arabinrin, tabi ìyá, tabi baba, tabi ọmọ, tabi ilẹ̀, sílẹ̀ nítorí mi ati nítorí ìyìn rere,


Marku 10:32
Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, tí wọn ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, Jesu ṣáájú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀lé e. Ẹnu ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ẹ̀rù sì ba àwọn eniyan tí wọ́n tẹ̀lé e. Ó bá tún pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila sí apá kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun fún wọn.


Marku 10:36
Jesu bi wọ́n pé, “Kí ni ẹ fẹ́ kí n ṣe fun yín?”


Marku 10:38
Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀ ń bèèrè. Ṣé ẹ lè mu ninu ife ìrora tí èmi yóo mu, tabi kí ojú yín rí irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí?”


Marku 10:39
Wọ́n wí fún un pé, “Àwa lè ṣe é.” Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ninu irú ife ìrora tí n óo mu ẹ̀yin náà yóo mu, irú ìṣòro tí ojú mi yóo rí, tiyín náà yóo sì rí i.


Marku 10:42
Ni Jesu bá pè wọ́n, ó wí fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ pé àwọn aláṣẹ láàrin àwọn alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn, àwọn eniyan ńláńlá ninu wọn a sì máa lo agbára lórí wọn,


Marku 10:46
Wọn dé Jẹriko. Bí Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ogunlọ́gọ̀ eniyan ti ń jáde kúrò ní Jẹriko, Batimiu afọ́jú, ọmọ Timiu, jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, ó ń ṣagbe.


Marku 10:47
Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ará Nasarẹti ni ó dé, ó bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé, “Jesu! Ọmọ Dafidi! Ṣàánú mi!”


Marku 10:49
Jesu bá dúró, ó ní, “Ẹ pè é wá.” Wọ́n wá wí fún afọ́jú náà pé, “Ṣe ara gírí, dìde, ó ń pè ọ́.”


Marku 10:50
Bẹ́ẹ̀ ni ọkunrin náà bọ́ aṣọ rẹ̀ sọ sí apá kan, ó fò sókè, ó bá lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu.


Marku 10:51
Jesu bi í pé, “Kí ni o fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Afọ́jú náà dáhùn pé, “Olùkọ́ni, mo fẹ́ tún ríran ni.”


Marku 10:52
Jesu bá wí fún un pé, “Máa lọ, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá.” Lójú kan náà, afọ́jú náà bá ríran, ó bá ń bá Jesu lọ ní ọ̀nà.


Marku 11:6
Wọ́n bá dá wọn lóhùn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti wí fún wọn. Àwọn eniyan náà sì yọ̀ǹda fún wọn.


Marku 11:7
Wọ́n bá fa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà wá sí ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí orí rẹ̀, Jesu bá gùn un.


Marku 11:14
Jesu wí fún igi náà pé, “Kí ẹnikẹ́ni má rí èso jẹ lórí rẹ mọ́ lae!” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbọ́.


Marku 11:15
Nígbà tí wọ́n dé Jerusalẹmu, Jesu wọ àgbàlá Tẹmpili lọ, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí wọn ń tà ati àwọn tí wọn ń rà jáde. Ó ti tabili àwọn onípàṣípààrọ̀ owó ṣubú, ó da ìsọ̀ àwọn tí ń ta ẹyẹlé rú.


Marku 11:19
Nígbà tí ọjọ́ rọ̀ Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde kúrò ní ìlú.


Marku 11:21
Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ àná. Ó wí fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, wo igi ọ̀pọ̀tọ́ tí o fi gégùn-ún, ó ti gbẹ!”


Marku 11:22
Jesu dáhùn, ó wí fún wọn pé, “Ẹ ní igbagbọ ninu Ọlọrun;


Marku 11:27
Wọ́n tún wá sí Jerusalẹmu. Bí Jesu ti ń rìn kiri ninu Tẹmpili, àwọn olórí alufaa, ati àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.


Marku 11:29
Jesu dá wọn lóhùn, ó ní, “N óo bi yín léèrè ọ̀rọ̀ kan, ẹ dá mi lóhùn, èmi náà óo wá sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi.


Marku 11:33
Wọ́n bá dá Jesu lóhùn pé, “Àwa kò mọ̀.” Nígbà náà ni Jesu sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi fun yín.”


Marku 12:1
Jesu bẹ̀rẹ̀ sí fi òwe bá wọn sọ̀rọ̀ pé, “Ọkunrin kan gbin àjàrà sinu oko kan, ó sì ṣe ọgbà yí i ká. Ó wa ihò ìfúntí sí ibẹ̀, ó kọ́ ilé-ìṣọ́, ó gba àwọn alágbàro tí yóo máa mú ninu èso àjàrà fi ṣe owó ọ̀yà wọn. Lẹ́yìn náà ó lọ sí ìdálẹ̀.


Marku 12:15
Ṣugbọn Jesu mọ àgàbàgebè wọn, ó wí fún wọn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń dẹ mí? Ẹ mú owó fadaka kan wá fún mi kí n rí i.”


Marku 12:17
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi nǹkan tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari, ohun tí ó bá sì jẹ́ ti Ọlọrun, ẹ fi fún Ọlọrun.” Ẹnu yà wọ́n pupọ sí ìdáhùn rẹ̀.


Marku 12:24
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ti ṣìnà patapata! Àṣé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ tabi agbára Ọlọrun?


Marku 12:28
Amòfin kan lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó gbọ́ bí wọn tí ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó wòye pé Jesu dá wọn lóhùn dáradára. Ó bá bèèrè pé, “Èwo ni ó ṣe pataki jùlọ ninu gbogbo òfin?”


Marku 12:29
Jesu dáhùn pé, “Èyí tí ó ṣe pataki jùlọ nìyí, ‘Gbọ́, Israẹli, Oluwa Ọlọrun wa nìkan ni Oluwa.


Marku 12:34
Nígbà náà ni Jesu ṣe akiyesi pé ó fi òye sọ̀rọ̀, ó wí fún un pé, “Ìwọ kò jìnnà sí ìjọba Ọlọrun.” Kò sì sí ẹnìkan tí ó ní ìgboyà láti tún bi í ní ìbéèrè kankan mọ́.


Marku 12:35
Bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili, ó bèèrè pé, “Báwo ni àwọn amòfin ṣe wí pé ọmọ Dafidi ni Kristi?


Marku 12:38
Jesu ń sọ ninu ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fún àwọn amòfin tí wọ́n fẹ́ràn ati máa wọ agbádá ńlá káàkiri òde, kí eniyan máa kí wọn ní ọjà, ati láti gba ìjókòó pataki ní ilé ìpàdé.


Marku 12:41
Bí Jesu ti jókòó lọ́kàn-ánkán àpótí owó, ó ń wò bí ọpọlọpọ eniyan ti ń dá owó sinu àpótí. Ọpọlọpọ àwọn ọlọ́rọ̀ ń dá owó pupọ sinu àpótí owó.


Marku 12:43
Jesu wá tọ́ka sí èyí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní, “Mo ń wí fun yín gbangba pé opó talaka yìí dá owó ju gbogbo àwọn tí ó dá owó sinu àpótí lọ.


Marku 13:2
Jesu wí fún un pé, “O rí ilé yìí bí ó ti tóbi tó? Kò ní sí òkúta kan lórí ekeji níhìn-ín tí a kò ní wó lulẹ̀.”


Marku 13:3
Nígbà tí Jesu jókòó ní orí Òkè Olifi, tí ó dojú kọ Tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu ati Anderu bi í níkọ̀kọ̀ pé,


Marku 13:5
Ni Jesu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ ṣọ́ra, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tàn yín jẹ.


Marku 14:1
Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ati ti Àìwúkàrà ku ọ̀tunla, àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà tí wọn yóo fi rí Jesu mú, kí wọ́n pa á.


Marku 14:3
Nígbà tí Jesu wà ní Bẹtani, bí ó ti jókòó tí ó fẹ́ máa jẹun ní ilé Simoni tí ó dẹ́tẹ̀ nígbà kan rí, obinrin kan wọlé wá tí ó mú ìgò ojúlówó òróró ìpara olóòórùn dídùn kan tí ó ní iye lórí lọ́wọ́. Ó fọ́ ìgò náà, ó bá tú òróró inú rẹ̀ sí Jesu lórí.


Marku 14:6
Ṣugbọn Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ fi í sílẹ̀, kí ni ẹ̀ ń yọ ọ́ lẹ́nu sí? Ohun rere ni ó ṣe sí mi.


Marku 14:10
Judasi Iskariotu, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila, bá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa, ó lọ fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.


Marku 14:11
Nígbà tí wọ́n gbọ́ ohun tí ó bá wá, inú wọn dùn, wọ́n bá ṣe ìlérí láti fún un ní owó. Judasi wá ń wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́.


Marku 14:12
Ní ọjọ́ kinni Àjọ̀dún Àìwúkàrà, ní ọjọ́ tí wọn máa ń pa aguntan láti ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu bi í pé, “Níbo ni o fẹ́ kí á tọ́jú fún ọ láti jẹ àsè Ìrékọjá?”


Marku 14:16
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ, wọ́n wọ inú ìlú, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn; wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.


Marku 14:17
Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Jesu wá sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila.


Marku 14:18
Bí wọ́n ti jókòó tí wọn ń jẹun, Jesu ní, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín tí ń bá mi jẹun nisinsinyii ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”


Marku 14:22
Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu mú burẹdi, ó gbadura sí i, ó bù ú, ó fún wọn. Ó ní, “Ẹ gbà, èyí ni ara mi.”


Marku 14:27
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, àwọn aguntan yóo bá fọ́nká,’


Marku 14:30
Jesu wí fún un pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ní alẹ́ yìí kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ náà yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta.”


Marku 14:43
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila dé, pẹlu àwọn eniyan tí ó mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ati àwọn àgbà.


Marku 14:45
Lẹsẹkẹsẹ bí ó ti dé, Judasi lọ sí ọ̀dọ̀ Jesu, ó kí i, ó ní, “Olùkọ́ni!” Ó sì da ẹnu dé e ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.


Marku 14:46
Àwọn tí ó bá a wá bá ṣùrù mọ́ Jesu, wọ́n mú un.


Marku 14:48
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ẹ mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́ láti wá mú mi bí ẹni pé ẹ̀ ń bọ̀ wá mú ọlọ́ṣà?


Marku 14:53
Wọ́n mú Jesu lọ sí ọ̀dọ̀ Olórí Alufaa, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ati àwọn amòfin wá péjọ sibẹ.


Marku 14:55
Àwọn olórí alufaa ati gbogbo Ìgbìmọ̀ ń wá ẹ̀rí tí ó lòdì sí Jesu, kí wọ́n baà lè pa á, ṣugbọn wọn kò rí.


Marku 14:60
Nígbà náà ni Olórí Alufaa dìde láàrin wọn, ó bi Jesu pé, “Ìwọ kò fèsì rárá?”


Marku 14:62
Jesu dáhùn pé, “Èmi ni. Ẹ óo rí Ọmọ-Eniyan tí ó jókòó lórí ìtẹ́ pẹlu agbára Ọlọrun, tí ìkùukùu yóo sì máa gbé e bọ̀ wá.”


Marku 14:67
Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”


Marku 14:72
Lẹsẹkẹsẹ, àkùkọ kọ ní ẹẹkeji. Peteru wá ranti ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ ní ẹẹmeji, ìwọ yóo sẹ́ mi ní ẹẹmẹta!” Orí Peteru wú, ó bá bú sẹ́kún.


Marku 15:1
Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́.


Marku 15:2
Pilatu bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ sọ ọ́.”


Marku 15:5
Ṣugbọn Jesu kò tún dá a lóhùn rárá mọ́, èyí mú kí ẹnu ya Pilatu.


Marku 15:10
Nítorí ó mọ̀ pé àwọn olórí alufaa ń jowú Jesu, wọ́n sì ń ṣe kèéta rẹ̀, ni wọ́n ṣe fà á wá siwaju òun.


Marku 15:15
Pilatu bá dá Baraba sílẹ̀ fún wọn kí ó lè baà tẹ́ wọn lọ́rùn. Lẹ́yìn tí ó ti ní kí wọ́n na Jesu tán, ó bá fà á fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.


Marku 15:21
Bí ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene, baba Alẹkisanderu ati Rufọsi, ti ń ti ọ̀nà ìgbèríko bọ̀, bí ó ti ń kọjá lọ, wọ́n fi tipátipá mú un láti gbé agbelebu Jesu.


Marku 15:22
Wọ́n wá mú Jesu lọ sí ibìkan tí à ń pè ní Gọlgọta (ìtumọ̀ èyí tíí ṣe “Ibi Agbárí”).


Marku 15:34
Nígbà tí ó di agogo mẹta ọ̀sán, Jesu kígbe tòò, ó ní, “Eloi, Eloi, lema sabakitani?” Ìtumọ̀ èyí ni, “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?”


Marku 15:37
Ṣugbọn Jesu kígbe tòò, ó mí kanlẹ̀ ó bá dákẹ́.


Marku 15:42
Ọjọ́ náà jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ tíí ṣe ọ̀sẹ̀ ku ọ̀la. Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, Josẹfu ará Arimatia, ọlọ́lá kan ninu àwọn ìgbìmọ̀, wá. (Ó ń retí àkókò ìjọba Ọlọrun), ó bá fi ìgboyà tọ Pilatu lọ láti bèèrè òkú Jesu.


Marku 15:44
Ṣugbọn ẹnu ya Pilatu pé Jesu ti yára kú! Ó pe ọ̀gágun, ó bèèrè bí Jesu ti kú tipẹ́.


Marku 15:45
Nígbà tí ó gbọ́ ìròyìn ọ̀gágun náà, ó yọ̀ǹda òkú Jesu fún Josẹfu.


Marku 15:46
Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.


Marku 16:1
Lẹ́yìn tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, Maria Magidaleni ati Maria ìyá Jakọbu ati Salomi ra òróró ìkunra, wọ́n fẹ́ lọ fi kun òkú Jesu.


Marku 16:6
Ṣugbọn ó wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù, ṣé Jesu ará Nasarẹti tí a kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá? Ó ti jí dìde. Kò sí níhìn-ín. Ẹ wò ó! Ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí nìyí.


Marku 16:10
Lẹ́yìn èyí, Jesu fúnrarẹ̀ rán wọn lọ jákèjádò ayé láti kéde ìyìn rere ìgbàlà ayérayé, ìyìn rere tí ó ní ọ̀wọ̀, tí kò sì lè díbàjẹ́ lae.] [ (ÌPARÍ ÌYÌN RERE TÍ Ó GÙN) Jesu Fara han Maria Magidaleni (Mat 28:9-10; Joh 20:11-18) Nígbà tí Jesu jí dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fara han Maria Magidaleni, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje kúrò ninu rẹ̀ nígbà kan. Ó lọ sọ fún àwọn tí ó ti ń bá Jesu gbé níbi tí wọn ti ń ṣọ̀fọ̀, tí wọn ń sunkún.


Marku 16:11
Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jesu wà láàyè ati pé Maria ti rí i, wọn kò gbàgbọ́.


Marku 16:19
Lẹ́yìn tí Jesu Oluwa ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, a gbé e lọ sí òkè ọ̀run, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.


Luku 1:31
O óo lóyún, o óo sì bí ọmọkunrin kan, Jesu ni o óo pe orúkọ rẹ̀.


Luku 2:21
Nígbà tí ọjọ́ kẹjọ pé láti kọ ọmọ náà ní ilà-abẹ́, wọ́n sọ orúkọ rẹ̀ ní Jesu, gẹ́gẹ́ bí angẹli ti wí, kí ìyá rẹ̀ tó lóyún rẹ̀.


Luku 2:33
Ẹnu ya baba ati ìyá Jesu nítorí ohun tí ó sọ nípa rẹ̀.


Luku 2:41
Àwọn òbí Jesu a máa lọ sí Àjọ̀dún Ìrékọjá ní Jerusalẹmu ní ọdọọdún.


Luku 2:42
Nígbà tí Jesu di ọmọ ọdún mejila, wọ́n lọ sí àjọ yìí gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn.


Luku 2:43
Nígbà tí àjọ̀dún parí, tí wọn ń pada lọ sí ilé, ọmọde náà, Jesu, dúró ní Jerusalẹmu, ṣugbọn àwọn òbí rẹ̀ kò fura.


Luku 2:52
Bí Jesu ti ń dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n rẹ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì ń bá ojurere Ọlọrun ati ti àwọn eniyan pàdé.


Luku 3:21
Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan ń ṣe ìrìbọmi, Jesu náà ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, bí ó ti ń gbadura, ọ̀run ṣí sílẹ̀.


Luku 3:23
Jesu tó ẹni ọgbọ̀n ọdún nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀. Ọmọ Josẹfu ni àwọn eniyan mọ̀ ọ́n sí. Josẹfu jẹ́ ọmọ Eli,


Luku 4:1
Jesu pada láti odò Jọdani, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ̀mí bá darí rẹ̀ lọ sí aṣálẹ̀.


Luku 4:4
Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Kì í ṣe oúnjẹ nìkan ni yóo mú kí eniyan wà láàyè.’ ”


Luku 4:6
Ó sọ fún Jesu pé, “Ìwọ ni n óo fún ní gbogbo àṣẹ yìí ati ògo rẹ̀, nítorí èmi ni a ti fi wọ́n lé lọ́wọ́, ẹni tí ó bá sì wù mí ni mo lè fún.


Luku 4:8
Jesu dá a lóhùn pé, “Ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Oluwa Ọlọrun rẹ ni kí o máa júbà, òun nìkan ni kí o sì máa sìn!’ ”


Luku 4:12
Jesu dá a lóhùn pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.’ ”


Luku 4:13
Nígbà tí Satani parí gbogbo ìdánwò yìí, ó fi Jesu sílẹ̀ títí di àkókò tí ó bá tún wọ̀.


Luku 4:14
Jesu pada sí Galili pẹlu agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Òkìkí rẹ̀ kàn ká gbogbo ìgbèríko.


Luku 4:31
Jesu bá lọ sí Kapanaumu, ìlú kan ní ilẹ̀ Galili. Ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi.


Luku 4:34
ó ní, “Háà! Kí ni ó pa tàwa-tìrẹ pọ̀, Jesu ará Nasarẹti? Ṣé o wá pa wá run ni? Mo mọ ẹni tí o jẹ́. Ẹni Mímọ́ ti Ọlọrun ni ọ́.”


Luku 4:35
Jesu bá bá a wí, ó ní, “Pa ẹnu mọ́, kí o jáde kúrò ninu ọkunrin yìí!” Ẹ̀mí èṣù náà bá gbé ọkunrin náà ṣánlẹ̀ lójú gbogbo wọn, ó bá jáde kúrò lára rẹ̀, láì pa á lára.


Luku 4:37
Òkìkí Jesu sì kàn ká gbogbo ìgbèríko ibẹ̀.


Luku 4:38
Nígbà tí Jesu dìde kúrò ní ilé ìpàdé, ó wọ ilé Simoni lọ. Ìyá iyawo Simoni ń ṣàìsàn akọ ibà. Wọ́n bá sọ fún Jesu.


Luku 4:40
Nígbà tí oòrùn wọ̀, gbogbo àwọn tí wọ́n ní oríṣìíríṣìí àrùn ni wọ́n mú wá sọ́dọ̀ Jesu. Ó bá gbé ọwọ́ lé ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, ó wò wọ́n sàn.


Luku 4:41
Àwọn ẹ̀mí èṣù jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan, wọ́n ń kígbe pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọrun.” Jesu ń bá wọn wí, kò jẹ́ kí wọ́n sọ̀rọ̀, nítorí wọ́n mọ̀ pé Jesu ni Mesaya.


Luku 4:42
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, Jesu jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí kò sí ẹnìkankan. Àwọn eniyan ń wá a kiri. Nígbà tí wọ́n rí i, wọ́n fẹ́ dá a dúró kí ó má kúrò lọ́dọ̀ wọn.


Luku 5:1
Ní àkókò kan, bí Jesu ti dúró létí òkun Genesarẹti, ọ̀pọ̀ eniyan péjọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun.


Luku 5:3
Jesu bá wọ inú ọ̀kan ninu àwọn ọkọ̀ náà tí ó jẹ́ ti Simoni, ó ní kí wọ́n tù ú kúrò létí òkun díẹ̀. Ni ó bá jókòó ninu ọkọ̀, ó ń kọ́ àwọn eniyan.


Luku 5:8
Nígbà tí Simoni Peteru rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó ní “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Oluwa.”


Luku 5:10
Ẹnu ya Jakọbu náà ati Johanu, àwọn ọmọ Sebede, tí wọ́n jẹ́ ẹlẹgbẹ́ Simoni. Jesu wá sọ fún Peteru pé, “Má bẹ̀rù. Láti ìgbà yìí lọ eniyan ni ìwọ yóo máa mú wá.”


Luku 5:12
Ní àkókò kan nígbà tí Jesu wà ninu ìlú kan, ọkunrin kan tí ẹ̀tẹ̀ bò ní gbogbo ara rí i. Ó bá wá dojúbolẹ̀, ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Alàgbà, bí o bá fẹ́, o lè sọ ara mi di mímọ́.”


Luku 5:13
Jesu bá na ọwọ́, ó fi kàn án, ó ní, “Mo fẹ́ kí ara rẹ di mímọ́.” Lẹsẹkẹsẹ àrùn ẹ̀tẹ̀ náà fi í sílẹ̀.


Luku 5:14
Jesu bá kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe sọ fún ẹnikẹ́ni, ṣugbọn lọ fi ara rẹ han alufaa, kí o ṣe ìrúbọ fún ìsọdi-mímọ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí Mose ti pàṣẹ. Èyí yóo jẹ́ ẹ̀rí fún wọn pé ara rẹ ti dá.”


Luku 5:17
Ní ọjọ́ kan bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn Farisi ati àwọn amòfin jókòó níbẹ̀. Wọ́n wá láti gbogbo ìletò Galili ati ti Judia ati láti Jerusalẹmu. Agbára Oluwa wà pẹlu Jesu láti fi ṣe ìwòsàn.


Luku 5:18
Àwọn ẹnìkan gbé ọkunrin arọ kan wá tí ó dùbúlẹ̀ sórí ibùsùn rẹ̀. Wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé e dé iwájú Jesu.


Luku 5:19
Nígbà tí wọn kò rí ọ̀nà gbé e dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ eniyan, wọ́n gbé e gun orí òrùlé. Wọ́n bá dá òrùlé lu kí wọ́n fi lè gbé arọ náà pẹlu ibùsùn rẹ̀ sí ààrin àwọn eniyan níwájú Jesu.


Luku 5:20
Nígbà tí Jesu rí igbagbọ wọn, ó ní, “Arakunrin, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”


Luku 5:22
Jesu ti mọ ohun tí wọ́n ń bá ara wọn sọ, ó bá dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ń ro irú èrò báyìí ní ọkàn yín?


Luku 5:27
Lẹ́yìn èyí Jesu jáde lọ. Ó rí agbowó-odè kan tí ó ń jẹ́ Lefi tí ó jókòó níbi tí ó ti ń gba owó-odè. Jesu sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”


Luku 5:29
Lefi bá se àsè ńlá fún Jesu ninu ilé rẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-odè wà níbẹ̀ pẹlu àwọn ẹlòmíràn, tí wọn ń bá wọn jẹun.


Luku 5:30
Àwọn Farisi ati àwọn amòfin tí wọ́n wà ninu ẹgbẹ́ wọn wá ń kùn sí Jesu. Wọ́n bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń bá àwọn agbowó-odè ati àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹ, tí ò ń bá wọn mu?”


Luku 5:31
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn tí ara wọn le kò nílò oníṣègùn, bíkòṣe àwọn tí ara wọn kò dá.


Luku 5:34
Jesu dá wọn lóhùn pé, “àwọn ọ̀rẹ́ ọkọ iyawo kò lè máa gbààwẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ọkọ iyawo bá wà pẹlu wọn.


Luku 5:36
Jesu wá pa òwe kan fún wọn pé, “Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ya lára ẹ̀wù titun kí ó fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ti ba ẹ̀wù titun jẹ́, aṣọ titun tí ó sì fi lẹ ògbólógbòó ẹ̀wù kò bá ara wọn mu.


Luku 6:1
Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, bí Jesu ti ń la oko ọkà kan kọjá, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí já ọkà, wọ́n ń fi ọwọ́ ra á, wọ́n bá ń jẹ ẹ́.


Luku 6:3
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ṣé ẹ kò ì tíì ka ohun tí Dafidi ṣe nígbà tí ebi ń pa òun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀?


Luku 6:5
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ọmọ-Eniyan ni Oluwa Ọjọ́ Ìsinmi.”


Luku 6:6
Nígbà tí ó di Ọjọ́ Ìsinmi mìíràn, Jesu wọ inú ilé ìpàdé lọ, ó ń kọ́ àwọn eniyan. Ọkunrin kan wà níbẹ̀ tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ rọ.


Luku 6:7
Àwọn amòfin ati àwọn Farisi ń ṣọ́ Jesu bí yóo ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi kí wọ́n lè rí ẹ̀sùn fi kàn án.


Luku 6:9
Jesu wá sọ fún wọn pé, “Mo bi yín, èwo ni ó bá òfin mu, láti ṣe nǹkan rere tabi nǹkan burúkú ní Ọjọ́ Ìsinmi? Láti gba ẹ̀mí là, tabi láti pa á run?”


Luku 6:11
Inú wọn ru sókè, wọ́n wá ń bá ara wọn jíròrò nípa ohun tí wọn ìbá ṣe sí Jesu.


Luku 6:12
Ní ọjọ́ kan, Jesu lọ sí orí òkè, ó lọ gbadura. Gbogbo òru ni ó fi gbadura sí Ọlọrun.


Luku 6:17
Nígbà tí Jesu sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè pẹlu wọn, ó dúró ní ibi tí ilẹ̀ gbé tẹ́jú. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ àwọn eniyan láti gbogbo Judia ati Jerusalẹmu ati Tire ati Sidoni, ní agbègbè ẹ̀bá òkun.


Luku 6:39
Jesu wá tún pa òwe yìí fún wọn. Ó ní, “Afọ́jú kò lè fi ọ̀nà han afọ́jú. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, inú kòtò ni àwọn mejeeji yóo bá ara wọn.


Luku 7:1
Nígbà tí Jesu parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá àwọn eniyan sọ, ó wọ inú ìlú Kapanaumu lọ.


Luku 7:3
Nígbà tí ó gbọ́ nípa Jesu, ó rán àwọn àgbààgbà Juu kan sí i pé kí wọn bá òun bẹ̀ ẹ́ kí ó wá wo ẹrú òun sàn.


Luku 7:4
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kí ó tètè. Wọ́n ní, “Ọ̀gágun náà yẹ ní ẹni tí o lè ṣe èyí fún,


Luku 7:6
Jesu bá ń bá wọn lọ. Ṣugbọn nígbà tí ó ṣì wà ní ọ̀nà jíjìn sí ilé ọ̀gágun náà, ọ̀gágun náà rán àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sí Jesu kí wọ́n sọ pé, “Alàgbà, má ṣe ìyọnu. Èmi kò yẹ ní ẹni tí ìwọ ìbá wọ ilé rẹ̀.


Luku 7:9
Nígbà tí Jesu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹnu yà á. Ó bá yipada sí àwọn eniyan tí ó ń tẹ̀lé e, ó ní, “Mò ń sọ fun yín, n kò rí irú igbagbọ báyìí ní Israẹli pàápàá!”


Luku 7:11
Láìpẹ́ lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Naini. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati ọ̀pọ̀ eniyan ń bá a lọ.


Luku 7:15
Ọdọmọkunrin tí ó ti kú yìí bá dìde jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀. Jesu bà fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.


Luku 7:20
Nígbà tí àwọn ọkunrin náà dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n ní, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó rán wa sí ọ láti bi ọ́ pé, ‘Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?’ ”


Luku 7:21
Ní àkókò náà, Jesu ń wo ọpọlọpọ eniyan sàn ninu àìsàn ati àrùn. Ó ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Ọpọlọpọ àwọn afọ́jú ni ó jẹ́ kí wọ́n ríran.


Luku 7:24
Lẹ́yìn tí àwọn oníṣẹ́ Johanu lọ tán, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ nípa Johanu fún àwọn eniyan. Ó ní, “Kí ni ẹ jáde lọ wò ní aṣálẹ̀? Igi légbélégbé tí afẹ́fẹ́ ń tì sọ́tùn-ún, ati sósì ni bí?


Luku 7:31
Jesu tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó ní, “Ta ni èmi ìbá fi àwọn eniyan òde òní wé? Ta ni kí a wí pé wọ́n jọ?


Luku 7:36
Ọ̀kan ninu àwọn Farisi pe Jesu pé kí ó wá bá òun jẹun. Jesu bà lọ sí ilé Farisi yìí lọ jẹun.


Luku 7:37
Obinrin kan báyìí wà ninu ìlú tí ó gbọ́ pé Jesu ń jẹun ní ilé Farisi, ó mú ìgò òróró olóòórùn dídùn lọ́wọ́,


Luku 7:38
ó lọ dúró lẹ́yìn lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń sunkún, omijé rẹ̀ ń dà sí ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi irun rẹ̀ nù ún, ó ń fi ẹnu kan ẹsẹ̀ Jesu, ó tún ń fi òróró kùn ún lẹ́sẹ̀.


Luku 7:39
Nígbà tí Farisi tí ó pe Jesu wá jẹun rí i, ó rò ninu ara rẹ̀ pé, “Ìbá jẹ́ pé wolii ni ọkunrin yìí, ìbá ti mọ irú ẹni tí obinrin yìí tí ó ń fọwọ́ kàn án jẹ́, nítorí ẹlẹ́ṣẹ̀ ni.”


Luku 7:40
Jesu sọ fún un pé, “Simoni, mo fẹ́ bi ọ́ léèrè ọ̀rọ̀ kan.” Simoni ní, “Olùkọ́ni, máa wí.”


Luku 7:41
Jesu ní, “Àwọn meji kan jẹ gbèsè. Wọ́n yá owó lọ́wọ́ ẹnìkan tí í máa ń yá eniyan lówó pẹlu èlé. Ọ̀kan jẹ ẹ́ ní àpò marun-un owó fadaka, ekeji jẹ ẹ́ ní aadọta owó fadaka.


Luku 7:43
Simoni dáhùn pé, “Ẹni tí ó fún ni owó pupọ ni.” Jesu wá sọ fún un pé, “O wí ire.”


Luku 7:44
Jesu bá yipada sí obinrin náà, ó sọ fún Simoni pé, “Ṣé o rí obinrin yìí? Mo wọ ilé rẹ, o kò fún mi ní omi kí n fi fọ ẹsẹ̀. Ṣugbọn obinrin yìí fi omijé rẹ̀ fọ ẹsẹ̀ mi, ó sì fi irun orí rẹ̀ nù ún.


Luku 7:50
Jesu bá sọ fún obinrin náà pé, “Igbagbọ rẹ ti gbà ọ́ là. Máa lọ ní alaafia.”


Luku 8:1
Lẹ́yìn èyí, Jesu ń rìn káàkiri láti ìlú dé ìlú, ati láti abúlé dé abúlé. Ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ń bá a kiri.


Luku 8:2
Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn obinrin kan tí Jesu ti wòsàn kúrò ninu ẹ̀mí èṣù ati àìlera ń bá a kiri. Ninu wọn ni Maria tí à ń pè ní Magidaleni wà, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje jáde ninu rẹ̀,


Luku 8:3
ati Joana iyawo Kusa, ọmọ-ọ̀dọ̀ Hẹrọdu, ati Susana ati ọpọlọpọ àwọn mìíràn. Àwọn yìí ni wọ́n ń fi ohun ìní wọn bá Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ gbọ́ bùkátà wọn.


Luku 8:19
Ìyá Jesu ati àwọn arakunrin rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ṣugbọn wọn kò lè dé ibi tí ó wà nítorí ọ̀pọ̀ eniyan.


Luku 8:21
Ṣugbọn Jesu wí fún gbogbo wọn pé, “Ìyá mi ati àwọn arakunrin mi ni àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun, tí wọ́n sì ń ṣe é.”


Luku 8:22
Ní ọjọ́ kan Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ inú ọkọ̀ ojú omi kan, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọjá lọ sí òdìkejì òkun.” Ni wọ́n bá lọ.


Luku 8:23
Bí wọ́n ti ń wakọ̀ lọ, Jesu bá sùn lọ. Ìjì líle kan bá bẹ̀rẹ̀ lójú òkun, omi bẹ̀rẹ̀ sí ya wọ inú ọkọ̀; ẹ̀mí wọn sì wà ninu ewu.


Luku 8:24
Ni wọ́n bá lọ jí Jesu, wọ́n ní, “Ọ̀gá! Ọ̀gá! Ọkọ̀ mà ń rì lọ!” Ni Jesu bá dìde, ó bá afẹ́fẹ́ ati ìgbì omi wí, ni ìgbì bá rọlẹ̀, gbogbo nǹkan bá dákẹ́ jẹ́.


Luku 8:28
Nígbà tí ó rí Jesu, ó kígbe, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀. Ó kébòòsí pé, “Kí ni ó pa èmi ati ìwọ pọ̀, Jesu, ọmọ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo? Mo bẹ̀ ọ́ má dá mi lóró!”


Luku 8:29
Nítorí Jesu ti pàṣẹ fún ẹ̀mí àìmọ́ náà láti jáde kúrò ninu ọkunrin yìí. Nítorí ní ọpọlọpọ ìgbà ní í máa ń dé sí i. Wọn á fi ẹ̀wọ̀n dè é lọ́wọ́, wọn á tún kó ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lẹ́sẹ̀. Ṣugbọn jíjá ni yóo já ohun tí wọ́n fi dè é, ni yóo bá sálọ sinu aṣálẹ̀.


Luku 8:30
Jesu bi í pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Ó ní, “Ẹgbaagbeje,” Nítorí àwọn ẹ̀mí èṣù tí ó ti wọ inú rẹ̀ pọ̀.


Luku 8:31
Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí bá bẹ Jesu pé kí ó má lé àwọn lọ sinu ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.


Luku 8:35
Àwọn eniyan bà jáde láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀, tí ó jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó wọ aṣọ, ojú rẹ̀ sì wálẹ̀. Ẹ̀rù ba àwọn eniyan.


Luku 8:37
Gbogbo àwọn eniyan agbègbè Geraseni bá bẹ Jesu pé kí ó kúrò lọ́dọ̀ àwọn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Ó bá tún wọ inú ọkọ̀ ojú omi, ó pada sí ibi tí ó ti wá.


Luku 8:38
Ọkunrin tí àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ninu rẹ̀ bẹ Jesu pé kí ó jẹ́ kí òun máa wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ṣugbọn Jesu kọ̀ fún un, ó ní,


Luku 8:39
“Pada lọ sí ilé rẹ, kí o lọ ròyìn ohun tí Ọlọrun ṣe fún ọ.” Ni ọkunrin náà bá ń káàkiri gbogbo ìlú, ó ròyìn ohun tí Jesu ṣe fún un.


Luku 8:40
Nígbà tí Jesu pada dé, àwọn eniyan fi tayọ̀tayọ̀ gbà á, nítorí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀.


Luku 8:41
Ọkunrin kan tí ó ń jẹ́ Jairu, tí ó jẹ́ alákòóso ilé ìpàdé, wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé kí ó bá òun kálọ sí ilé,


Luku 8:42
nítorí ọmọdebinrin rẹ̀ kan ṣoṣo tí ó ní ń kú lọ. Ọmọ yìí tó ọmọ ọdún mejila. Bí Jesu ti ń lọ àwọn eniyan ń bì lù ú níhìn-ín lọ́hùn-ún.


Luku 8:44
Ó bá gba ẹ̀yìn wá, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí ẹ̀wù Jesu, lẹsẹkẹsẹ ìsun ẹ̀jẹ̀ náà bá dá lára rẹ̀.


Luku 8:45
Jesu ní, “Ta ni fọwọ́ kàn mí?” Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́, Peteru ní, “Ọ̀gá, mélòó-mélòó ni àwọn eniyan tí wọn ń fún ọ, tí wọn ń tì ọ́?”


Luku 8:46
Ṣugbọn Jesu tún tẹnu mọ́ ọn pé, “Ẹnìkan fọwọ́ kàn mí sẹ́ẹ̀, nítorí mo mọ̀ pé agbára ti ara mi jáde.”


Luku 8:47
Nígbà tí obinrin náà rí i pé kò ṣe é fi pamọ́, ó bá jáde, ó ń gbọ̀n. Ó kúnlẹ̀ níwájú Jesu, ó bá sọ ìdí tí òun ṣe fọwọ́ kàn án lójú gbogbo eniyan ati bí òun ṣe rí ìwòsàn lẹsẹkẹsẹ.


Luku 8:48
Jesu wá wí fún un pé, “Ọmọbinrin, igbagbọ rẹ ti mú ọ lára dá, máa lọ ní alaafia.”


Luku 8:50
Ṣugbọn nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn pé, “Má bẹ̀rù, ṣá gbàgbọ́, ara ọmọ rẹ yóo dá.”


Luku 8:51
Nígbà tí Jesu dé ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé àfi Peteru, Johanu ati Jakọbu, baba ati ìyá ọmọ náà.


Luku 8:52
Gbogbo àwọn eniyan ń sunkún, wọ́n ń dárò nítorí ọmọ náà. Ṣugbọn Jesu ní, “Ẹ má sunkún mọ́, nítorí ọmọ náà kò kú, ó ń sùn ni.”


Luku 8:53
Ńṣe ni wọ́n ń fi Jesu rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, nítorí wọ́n mọ̀ pé ọmọ náà ti kú.


Luku 8:54
Jesu fa ọmọ náà lọ́wọ́, ó sọ fún un pé, “Ọmọ, dìde.”


Luku 8:55
Ẹ̀mí rẹ̀ bá pada sinu rẹ̀, ni ó bá dìde lẹsẹkẹsẹ. Jesu bá sọ fún wọn pé kí wọn fún un ní oúnjẹ.


Luku 9:1
Jesu pe àwọn mejila jọ. Ó fún wọn ní agbára ati àṣẹ láti lé gbogbo ẹ̀mí èṣù jáde ati láti ṣe ìwòsàn oríṣìíríṣìí àìsàn.


Luku 9:10
Àwọn aposteli tí Jesu rán níṣẹ́ pada wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe fún un. Ó bá rọra dá àwọn nìkan mú lọ sí ìlú kan tí ń jẹ́ Bẹtisaida.


Luku 9:13
Ṣugbọn Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni kí ẹ fún wọn ní oúnjẹ.” Wọ́n dáhùn pé, “A kò ní oúnjẹ pupọ, àfi burẹdi marun-un ati ẹja meji, ṣé kí àwa fúnra wa lọ ra oúnjẹ fún gbogbo àwọn eniyan wọnyi ni?”


Luku 9:16
Jesu bá mú burẹdi marun-un yìí ati ẹja meji, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó gbadura sí i, ó pín wọn sí wẹ́wẹ́, ó bá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n fún àwọn eniyan.


Luku 9:18
Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Jesu nìkan ń dá gbadura tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn eniyan rò pé mo jẹ́?”


Luku 9:21
Jesu wá kìlọ̀ fún wọn kí wọn má sọ fún ẹnikẹ́ni.


Luku 9:28
Ó tó bí ọjọ́ mẹjọ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, Jesu mú Peteru, Johanu ati Jakọbu lọ sí orí òkè kan láti gbadura.


Luku 9:33
Bí àwọn meji yìí ti ń kúrò lọ́dọ̀ Jesu, Peteru sọ fún un pé, “Ọ̀gá, ìbá dára tí a bá lè máa wà níhìn-ín. Jẹ́ kí á pa àgọ́ mẹta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún Mose, ati ọ̀kan fún Elija.” Ó sọ èyí nítorí kò mọ ohun tíì bá sọ.


Luku 9:36
Bí wọ́n ti gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, Jesu nìkan ni wọ́n rí. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bá pa ẹnu mọ̀, wọn kò sọ ohun tí wọ́n gbọ́ ati ohun tí wọ́n rí ní àkókò náà fún ẹnikẹ́ni.


Luku 9:41
Jesu dáhùn pé, “Ẹ̀yin ìran oníbàjẹ́ ati alaigbagbọ yìí! N óo ti wà pẹlu yín pẹ́ tó! N óo ti fara dà á fun yín tó! Mú ọmọ rẹ wá síhìn-ín.”


Luku 9:42
Bí ó ti ń mú un bọ̀, ẹ̀mí èṣù yìí bá gbé e ṣánlẹ̀, wárápá bá mú un. Jesu bá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó wo ọmọ náà sàn, ó bá fà á lé baba rẹ̀ lọ́wọ́.


Luku 9:43
Ẹnu ya gbogbo eniyan sí iṣẹ́ ńlá Ọlọrun. Bí ẹnu ti ń ya gbogbo eniyan sí gbogbo ohun tí Jesu ń ṣe, ó sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,


Luku 9:46
Àríyànjiyàn kan bẹ́ sílẹ̀ láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lórí pé ta ló ṣe pataki jùlọ láàrin wọn.


Luku 9:47
Jesu mọ ohun tí wọn ń rò lọ́kàn. Ó bá mú ọmọde kan, ó gbé e dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.


Luku 9:50
Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé. “Ẹ má dá a lẹ́kun, nítorí ẹni tí kò bá lòdì si yín, tiyín ní ń ṣe.”


Luku 9:51
Nígbà tí ó tó àkókò tí a óo gbé Jesu lọ sókè ọ̀run, ọkàn rẹ̀ mú un láti lọ sí Jerusalẹmu.


Luku 9:55
Ṣugbọn Jesu yipada, ó bá wọn wí.


Luku 9:58
Jesu dá a lóhùn pé, “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ìtẹ́, ṣugbọn Ọmọ-Eniyan kò ní ibi tí yóo gbé orí rẹ̀ lé.”


Luku 9:60
Ṣugbọn Jesu sọ fún un pé, “Jẹ́ kí àwọn òkú máa sin òkú ara wọn. Ìwọ ní tìrẹ, wá máa waasu ìjọba Ọlọrun.”


Luku 9:62
Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Kò sí ẹni tí ó bá ti dá ọwọ́ lé lílo ẹ̀rọ-ìroko, tí ó bá tún ń wo ẹ̀yìn tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọrun.”


Luku 10:21
Ní àkókò náà Jesu láyọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́. Ó ní, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye; ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè. Bẹ́ẹ̀ ni, Baba, nítorí bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ ni.


Luku 10:23
Jesu yipada sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ẹ ṣe oríire tí ojú yín rí àwọn ohun tí ẹ rí,


Luku 10:25
Amòfin kan wá, ó fi ìbéèrè yìí wá Jesu lẹ́nu wò. Ó ní, “Olùkọ́ni, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”


Luku 10:26
Jesu bi í pé, “Kí ni ó wà ní àkọsílẹ̀ ninu òfin? Báwo ni o ti túmọ̀ rẹ̀?”


Luku 10:28
Jesu sọ fún un pé, “O wí ire. Máa ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóo sì yè.”


Luku 10:29
Ṣugbọn amòfin náà fẹ́ wẹ ara rẹ̀ mọ́. Ó wá bi Jesu pé, “Ta ni ọmọnikeji mi?”


Luku 10:30
Jesu bá dá a lóhùn pé, “Ọkunrin kan ń ti Jerusalẹmu lọ sí Jẹriko, ni ó bá bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà. Wọ́n gba aṣọ lára rẹ̀, wọ́n lù ú, wọ́n bá fi í sílẹ̀ nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ kú tán.


Luku 10:37
Amòfin náà dáhùn pé, “Ẹni tí ó ṣàánú fún un ni.” Jesu sọ fún un pé, “Ìwọ náà lọ ṣe bẹ́ẹ̀ gan-an.”


Luku 10:38
Bí wọ́n ti ń lọ ninu ìrìn àjò wọn, Jesu wọ inú abúlé kan. Obinrin kan tí ń jẹ́ Mata bá gbà á lálejò.


Luku 10:39
Mata ní arabinrin kan tí ó ń jẹ́ Maria. Maria yìí jókòó lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.


Luku 11:1
Nígbà kan, Jesu wà níbìkan, ó ń gbadura. Nígbà tí ó parí, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ fún un pé, “Oluwa, kọ́ wa bí a ti í gbadura gẹ́gẹ́ bí Johanu ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”


Luku 11:14
Ní ìgbà kan, Jesu ń lé ẹ̀mí èṣù kan tí ó yadi jáde. Nígbà tí ẹ̀mí Èṣù náà ti jáde tán ọkunrin odi náà sọ̀rọ̀, ẹnu wá ya àwọn eniyan.


Luku 11:17
Ṣugbọn Jesu mọ èrò wọn, ó sọ fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó bá gbé ogun ti ara rẹ̀ yóo parun, ilé tí ó bá dìde sí ara rẹ̀ yóo tú ká.


Luku 11:27
Bí Jesu ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, obinrin kan láàrin àwọn eniyan fọhùn sókè pé, “Ẹni tí ó bí ọ, tí ó wò ọ́ dàgbà náà ṣe oríire lọpọlọpọ.”


Luku 11:37
Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, Farisi kan pè é pé kí ó wá jẹun ninu ilé rẹ̀. Ó bá wọlé, ó jókòó.


Luku 11:38
Ẹnu ya Farisi náà nígbà tí ó rí i pé Jesu kò kọ́kọ́ wẹwọ́ kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí jẹun.


Luku 11:46
Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹ̀yin amòfin náà gbé! Nítorí ẹ̀ ń di ẹrù bàràkàtà-bàràkàtà lé eniyan lórí nígbà tí ẹ̀yin fúnra yín kò jẹ́ fi ọwọ́ yín kan ẹrù kan.


Luku 11:53
Nígbà tí Jesu jáde kúrò ninu ilé, àwọn amòfin ati àwọn Farisi takò ó, wọ́n ń bi í léèrè ọ̀rọ̀ pupọ,


Luku 12:1
Ní àkókò yìí, ogunlọ́gọ̀ eniyan péjọ; wọ́n pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn fi ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀. Jesu kọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ná. Ó ní, “Ẹ ṣọ́ ara yín nípa ìwúkàrà àwọn Farisi, àwọn alágàbàgebè.


Luku 12:14
Jesu dá a lóhùn pé, “Arakunrin, ta ni ó yàn mí ní onídàájọ́ tabi ẹni tí ń pín ogún kiri?”


Luku 12:15
Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ẹ ṣọ́ra, ẹ ta kété sí ojúkòkòrò ní oríṣìíríṣìí ọ̀nà, nítorí ọ̀pọ̀ dúkìá nìkan kọ́ níí sọni di eniyan.”


Luku 12:16
Jesu bá pa òwe kan fún wọn. Ó ní, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ìkórè oko rẹ̀ pọ̀ pupọ.


Luku 12:22
Jesu bá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kí ẹ má máa páyà nípa ẹ̀mí yín, pé kí ni ẹ óo jẹ, tabi pé kí ni ẹ óo fi bora.


Luku 12:41
Peteru wá bi Jesu pé, “Oluwa, àwa ni o pa òwe yìí fún tabi fún gbogbo eniyan?”


Luku 12:54
Jesu tún sọ fún àwọn eniyan pé, “Nígbà tí ẹ bá rí i tí òjò ṣú ní ìwọ̀ oòrùn, ẹ óo sọ pé, ‘Òjò yóo rọ̀.’ Bẹ́ẹ̀ ni yóo sì rí.


Luku 13:2
Jesu sọ fún wọn pé, “Ẹ rò pé àwọn ará Galili wọnyi jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ju gbogbo ará Galili yòókù lọ ni, tí wọ́n fi jẹ irú ìyà yìí?


Luku 13:10
Jesu ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu ilé ìpàdé kan ní Ọjọ́ Ìsinmi.


Luku 13:12
Nígbà tí Jesu rí i, ó pè é, ó sọ fún un pé, “Obinrin yìí, a wò ọ́ sàn kúrò ninu àìlera rẹ.”


Luku 13:13
Jesu bá gbé ọwọ́ mejeeji lé e. Lẹsẹkẹsẹ ni ẹ̀yìn rẹ̀ bá nà, ó bá ń fi ògo fún Ọlọrun.


Luku 13:14
Ṣugbọn inú bí olórí ilé ìpàdé nítorí Jesu ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi. Ó bá sọ fún àwọn eniyan pé, “Ọjọ́ mẹfa wà tí a níláti fi ṣiṣẹ́. Ẹ wá fún ìwòsàn láàrin àwọn ọjọ́ mẹfa yìí. Ẹ má wá fún ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi mọ́!”


Luku 13:18
Nítorí náà Jesu sọ pé, “Kí ni à bá fi ìjọba Ọlọrun wé? Kí ni ǹ bá fi ṣe àkàwé rẹ̀?


Luku 13:22
Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ láti ìlú dé ìlú ati láti abúlé dé abúlé, ó ń kọ́ àwọn eniyan bí ó ti ń lọ sí Jerusalẹmu.


Luku 13:23
Ẹnìkan wá bi í pé, “Alàgbà, ǹjẹ́ àwọn eniyan tí yóo là kò ní kéré báyìí?” Jesu wá sọ fún àwọn eniyan pé,


Luku 13:31
Ní àkókò náà, àwọn Farisi kan wá sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín nítorí Hẹrọdu fẹ́ pa ọ́.”


Luku 14:1
Ní Ọjọ́ Ìsinmi kan, Jesu lọ jẹun ní ilé ọ̀kan ninu àwọn olóyè láàrin àwọn Farisi. Wọ́n bá ń ṣọ́ ọ.


Luku 14:3
Jesu bi àwọn amòfin ati àwọn Farisi tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ṣé ó dára láti ṣe ìwòsàn ní Ọjọ́ Ìsinmi, tabi kò dára?”


Luku 14:4
Wọ́n bá dákẹ́. Jesu bá mú ọkunrin náà, ó wò ó sàn, ó bá ní kí ó máa lọ.


Luku 14:7
Nígbà tí Jesu ṣe akiyesi bí àwọn tí a pè sí ibi àsè ti ń yan ipò ọlá, ó wá pa òwe kan fún wọn. Ó ní,


Luku 14:15
Nígbà tí ẹnìkan ninu àwọn tí ó wà níbi àsè gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ fún Jesu pé, “Ẹni tí ó bá jẹun ní ìjọba ọ̀run ṣe oríire!”


Luku 14:16
Jesu sọ fún un pé, “Ọkunrin kan se àsè ńlá kan; ó pe ọ̀pọ̀ eniyan sibẹ.


Luku 15:3
Jesu bá pa òwe yìí fún wọn. Ó ní:


Luku 15:11
Jesu ní, “Ọkunrin kan ní ọmọ meji.


Luku 16:1
Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà tí ó ní ọmọ-ọ̀dọ̀ kan. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan ọmọ-ọ̀dọ̀ yìí pé ó ń fi nǹkan ọ̀gá rẹ̀ ṣòfò.


Luku 17:1
Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “A kò lè ṣàì rí ohun ìkọsẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó ti ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀ gbé!


Luku 17:11
Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ó ń gba ààrin Samaria ati Galili kọjá.


Luku 17:13
wọ́n kígbe pé, “Ọ̀gá, Jesu, ṣàánú wa.”


Luku 17:16
Ó bá dojúbolẹ̀ níwájú Jesu, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria ni.


Luku 17:17
Jesu bèèrè pé, “Ṣebí àwọn mẹ́wàá ni mo mú lára dá. Àwọn mẹsan-an yòókù dà?


Luku 17:19
Jesu bá sọ fún un pé, “Dìde, máa lọ. Igbagbọ rẹ ni ó mú ọ lára dá.”


Luku 17:20
Àwọn Farisi bi Jesu nípa ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo dé. Ó dá wọn lóhùn pé, “Dídé ìjọba Ọlọrun kò ní àmì tí a óo máa fẹjú kí á tó ri pé ó dé tabi kò dé.


Luku 18:1
Jesu pa òwe kan fún wọn láti kọ́ wọn pé eniyan gbọdọ̀ máa gbadura nígbà gbogbo, láì ṣàárẹ̀.


Luku 18:16
Ṣugbọn Jesu pè wọ́n, ó ní, “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọde wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má dá wọn dúró, nítorí irú wọn ni ìjọba Ọlọrun.


Luku 18:18
Ìjòyè kan bi Jesu léèrè pé, “Olùkọ́ni rere, kí ni kí n ṣe kí n lè jogún ìyè ainipẹkun?”


Luku 18:19
Jesu sọ fún un pé, “Ìdí rẹ̀ tí o fi ń pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kan àfi Ọlọrun nìkan ṣoṣo.


Luku 18:22
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún un pé, “Nǹkankan ló kù ọ́ kù. Lọ ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó rẹ̀ fún àwọn talaka, ìwọ yóo wá ní ìṣúra ní ọ̀run. Kí o máa wá tọ̀ mí lẹ́yìn.”


Luku 18:24
Nígbà tí Jesu rí bí inú rẹ̀ ti bàjẹ́, ó ní, “Yóo ṣòro fún àwọn olówó láti wọ ìjọba Ọlọrun.


Luku 18:35
Nígbà tí Jesu súnmọ́ etí ìlú Jẹriko, afọ́jú kan wà lẹ́bàá ọ̀nà, ó jókòó, ó ń ṣagbe.


Luku 18:37
Wọ́n sọ fún un pé, “Jesu ará Nasarẹti ní ń kọjá.”


Luku 18:38
Ni alágbe náà bá pariwo pé, “Jesu, ọmọ Dafidi, ṣàánú mi!”


Luku 18:40
Jesu bá dúró, ó ní kí wọ́n lọ fà á lọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ òun. Nígbà tí ó dé, Jesu bi í pé,


Luku 18:42
Jesu sọ fún un pé, “Ǹjẹ́, ríran. Igbagbọ rẹ mú ọ lára dá.”


Luku 18:43
Lójú kan náà ó sì tún ríran, ó bá ń tẹ̀lé Jesu, ó ń yin Ọlọrun lógo. Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan rí i, wọ́n fi ìyìn fún Ọlọrun.


Luku 19:1
Nígbà tí Jesu dé Jẹriko, ó ń la ìlú náà kọjá.


Luku 19:3
Ó fẹ́ rí Jesu kí ó mọ ẹni tí í ṣe. Ṣugbọn kò lè rí i nítorí ọ̀pọ̀ eniyan ati pé eniyan kúkúrú ni.


Luku 19:4
Ó bá sáré lọ siwaju, ó gun igi sikamore kan kí ó lè rí i, nítorí ọ̀nà ibẹ̀ ni Jesu yóo gbà kọjá.


Luku 19:5
Nígbà tí Jesu dé ọ̀gangan ibẹ̀, ó gbé ojú sókè, ó sọ fún un pé, “Sakiu, tètè sọ̀kalẹ̀, nítorí ọ̀dọ̀ rẹ ni mo gbọdọ̀ dé sí lónìí.”


Luku 19:7
Nígbà tí àwọn eniyan rí i, gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí Jesu, wọ́n ní, “Lọ́dọ̀ ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ó lọ wọ̀ sí!”


Luku 19:9
Jesu bá dá a lóhùn pé, “Lónìí yìí ni ìgbàlà wọ inú ilé yìí, nítorí ọmọ Abrahamu ni Sakiu náà.


Luku 19:28
Nígbà tí Jesu sọ̀rọ̀ yìí tán ó tẹ̀síwájú, ó gòkè lọ sí Jerusalẹmu.


Luku 19:35
Wọ́n bá fà á lọ sọ́dọ̀ Jesu. Wọ́n tẹ́ ẹ̀wù wọn sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n bá gbé Jesu gùn ún.


Luku 19:45
Nígbà tí Jesu wọ inú Tẹmpili, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tajà jáde.


Luku 20:1
Ní ọjọ́ kan, bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili, tí ó ń waasu ìyìn rere fún wọn, àwọn olórí alufaa, àwọn amòfin, ati àwọn àgbà wá sọ́dọ̀ rẹ̀.


Luku 20:8
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Èmi náà kò ní sọ irú àṣẹ tí mo fi ń ṣe nǹkan wọnyi fún yín.”


Luku 20:17
Jesu bá wò wọ́n lójú, ó ní, “Ǹjẹ́ kí ni ìtumọ̀ àkọsílẹ̀ yìí, ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di òkúta pataki ní igun ilé.’


Luku 20:34
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àwọn eniyan ayé yìí ni wọ́n ń gbeyawo, tí wọn ń fi ọmọ fọ́kọ.


Luku 20:41
Jesu bi wọ́n léèrè pé, “Báwo ni wọ́n ṣe ń pe Mesaya ní ọmọ Dafidi?


Luku 20:45
Ní etí gbogbo àwọn eniyan, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,


Luku 21:1
Bí Jesu ti gbé ojú sókè ó rí àwọn ọlọ́rọ̀ bí wọ́n ti ń dá owó ọrẹ wọn sinu àpótí ìṣúra.


Luku 21:5
Àwọn kan ń sọ̀rọ̀ nípa Tẹmpili, wọ́n ń sọ nípa àwọn òkúta dáradára tí wọ́n fi ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́ ati ọrẹ tí wọ́n mú wá fún Ọlọrun. Jesu bá dáhùn pé,


Luku 21:37
Ní ọ̀sán, Jesu a máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ ninu Tẹmpili; lálẹ́, á lọ sùn ní orí Òkè Olifi.


Luku 22:2
Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe pa Jesu nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.


Luku 22:4
Ó bá lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili láti bá wọn sọ̀rọ̀ bí ọwọ́ wọn yóo ṣe tẹ Jesu.


Luku 22:6
Ó gbà bẹ́ẹ̀; ó bá bẹ̀rẹ̀ sí wá àkókò tí ó wọ̀ láti fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ lọ́nà tí ọ̀pọ̀ eniyan kò fi ní mọ̀.


Luku 22:8
Jesu rán Peteru ati Johanu, ó ní, “Ẹ lọ ṣe ìtọ́jú ohun tí a óo fi jẹ àsè Ìrékọjá.”


Luku 22:13
Ni wọ́n bá lọ, wọ́n rí ohun gbogbo bí Jesu ti sọ fún wọn. Wọ́n sì tọ́jú gbogbo nǹkan fún àsè Ìrékọjá.


Luku 22:25
Jesu sọ fún wọn pé, “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè alaigbagbọ a máa jẹ ọlá lórí wọn. Àwọn aláṣẹ wọn ni wọ́n ń pè ní olóore wọn.


Luku 22:34
Ṣugbọn Jesu dáhùn pé, “Peteru mò ń sọ fún ọ pé kí àkùkọ tó kọ lálẹ́ yìí, ẹẹmẹta ni ìwọ óo sọ pé o kò mọ̀ mí rí!”


Luku 22:39
Jesu bá jáde lọ sórí Òkè Olifi, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì tẹ̀lé e.


Luku 22:47
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ ni àwọn eniyan bá dé. Judasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn, ni ó ṣiwaju wọn. Ó bá súnmọ́ Jesu, ó fi ẹnu kò ó ní ẹ̀rẹ̀kẹ́.


Luku 22:48
Jesu sọ fún un pé, “Judasi! O sì fi ẹnu ko Ọmọ-Eniyan ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ láti fi í lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́?”


Luku 22:49
Nígbà tí àwọn tí ó wà pẹlu Jesu rí i, wọ́n ní, “Oluwa, ṣé kí á fa idà yọ?”


Luku 22:51
Ṣugbọn Jesu sọ pé, “Ẹ fi wọ́n sílẹ̀.” Ó bá fọwọ́ kan etí ẹrú náà, etí náà sì san.


Luku 22:54
Wọ́n bá mú Jesu, wọ́n fà á lọ sí ilé Olórí Alufaa. Ṣugbọn Peteru ń tẹ̀lé wọn lókèèrè.


Luku 22:56
Ọmọdebinrin kan wá rí i, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu.”


Luku 22:59
Nígbà tí ó tó bíi wakati kan, ọkunrin kan tún sọ pẹlu ìdánilójú pé, “Láìsí àní-àní ọkunrin yìí wà pẹlu Jesu, nítorí ará Galili ni.”


Luku 22:63
Àwọn ọkunrin tí wọn ń ṣọ́ Jesu ń fi í ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń lù ú.


Luku 22:66
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn àgbààgbà ati àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin péjọ, wọ́n fa Jesu lọ siwaju ìgbìmọ̀ wọn.


Luku 23:1
Ni gbogbo àwùjọ bá dìde, wọ́n fa Jesu lọ sọ́dọ̀ Pilatu.


Luku 23:6
Nígbà tí Pilatu gbọ́ èyí, ó bèèrè bí ará Galili bá ni Jesu.


Luku 23:8
Nígbà tí Hẹrọdu rí Jesu, inú rẹ̀ dùn pupọ. Nítorí ó ti pẹ́ tí ó ti fẹ́ rí i, nítorí ìró rẹ̀ tí ó ti ń gbọ́. Ó ń retí pé kí Jesu ṣe iṣẹ́ ìyanu lójú òun.


Luku 23:9
Ó bi Jesu ní ọpọlọpọ ìbéèrè ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn rárá.


Luku 23:20
Pilatu tún bá wọn sọ̀rọ̀, ó fẹ́ dá Jesu sílẹ̀.


Luku 23:25
Ó dá ẹni tí wọ́n ní àwọn fẹ́ sílẹ̀: ẹni tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n nítorí pé ó paniyan. Ó bá fi Jesu lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi ṣe ohun tí wọ́n bá fẹ́.


Luku 23:26
Bí wọ́n ti ń fa Jesu lọ, wọ́n bá fi ipá mú ọkunrin kan tí ń jẹ́ Simoni, ará Kirene tí ó ń ti ìgbèríko kan bọ̀. Wọ́n bá gbé agbelebu rù ú, wọ́n ní kí ó máa rù ú tẹ̀lé Jesu lẹ́yìn.


Luku 23:27
Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń tẹ̀lé Jesu, pẹlu àwọn obinrin tí wọn ń dárò, tí wọn ń sunkún nítorí rẹ̀.


Luku 23:28
Nígbà tí Jesu yipada sí wọn, ó ní, “Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu, ẹ má sunkún nítorí tèmi mọ́; ẹkún ara yín ati ti àwọn ọmọ yín ni kí ẹ máa sun.


Luku 23:34
Jesu ní, “Baba, dáríjì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọn ń ṣe.” Wọ́n pín aṣọ rẹ̀ mọ́ ara wọn lọ́wọ́, wọ́n ṣẹ́ gègé láti mọ èyí tí yóo kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn.


Luku 23:42
Ó bá sọ fún Jesu pé, “Ranti mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.”


Luku 23:43
Jesu bá sọ fún un pé, “Mo wí fún ọ, lónìí yìí ni ìwọ yóo wà pẹlu mi ní ọ̀run rere.”


Luku 23:46
Jesu kígbe, ó ní, “Baba, ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó mí kanlẹ̀, ó bá kú.


Luku 23:50
Ọkunrin kan wà ninu àwọn ìgbìmọ̀ tí ó ń jẹ́ Josẹfu. Ó jẹ́ eniyan rere ati olódodo. Òun kò bá wọn lóhùn sí ète tí wọ́n pa, ati ohun tí wọ́n ṣe sí Jesu. Ó jẹ́ ará Arimatia, ìlú kan ní Judia. Ó ń retí ìjọba Ọlọrun.


Luku 23:52
Òun ni ó lọ sọ́dọ̀ Pilatu, tí ó bèèrè òkú Jesu.


Luku 23:55
Àwọn obinrin tí wọn bá Jesu wá láti Galili tẹ̀lé Josẹfu yìí, wọ́n ṣe akiyesi ibojì náà, ati bí a ti ṣe tẹ́ òkú Jesu sinu rẹ̀.


Luku 24:3
Nígbà tí wọ́n wọ inú ibojì, wọ́n kò rí òkú Jesu Oluwa.


Luku 24:15
Bí wọ́n ti ń bá ara wọn jíròrò, tí wọn ń bá ara wọn jiyàn, Jesu alára bá súnmọ́ wọn, ó ń bá wọn rìn lọ.


Luku 24:19
Jesu bá bi í pé, “Bíi kí ni?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Jesu ará Nasarẹti ni. Wolii ni, iṣẹ́ rẹ̀ ati ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi agbára hàn níwájú Ọlọrun ati gbogbo eniyan.


Luku 24:25
Ni Jesu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀yin aláìmòye wọnyi! Ẹ lọ́ra pupọ láti gba ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii ti sọ!


Luku 24:27
Jesu wá bẹ̀rẹ̀ sí túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ nípa ara rẹ̀ fún wọn. Ó bẹ̀rẹ̀ pẹlu ìwé Mose, títí dé gbogbo ìwé àwọn wolii.


Luku 24:28
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ abúlé tí wọn ń lọ, Jesu ṣe bí ẹni pé ó fẹ́ máa bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ.


Luku 24:31
Ojú wọn bá là; wọ́n wá mọ̀ pé Jesu ni. Ó bá rá mọ́ wọn lójú.


Luku 24:36
Bí wọ́n ti ń sọ àwọn nǹkan wọnyi lọ́wọ́, Jesu alára bá dúró láàrin wọn. Ó ní, “Alaafia fun yín.”


Luku 24:50
Jesu bá kó wọn jáde lọ sí Bẹtani. Ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, ó súre fún wọn.


Johanu 1:17
Nípasẹ̀ Mose ni a ti fún wa ní Òfin, ṣugbọn nípasẹ Jesu Kristi ni oore-ọ̀fẹ́ ati òtítọ́ ti wá.


Johanu 1:29
Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ.


Johanu 1:36
ó tẹjú mọ́ Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun.”


Johanu 1:37
Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn meji náà gbọ́, wọ́n tẹ̀lé Jesu.


Johanu 1:38
Nígbà tí Jesu yipada, tí ó rí wọn tí wọn ń tẹ̀lé òun, ó bi wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní, “Rabi, níbo ni ò ń gbé?” (Ìtumọ̀ “Rabi” ni “Olùkọ́ni.”)


Johanu 1:40
Ọ̀kan ninu àwọn meji tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Johanu, tí ó tẹ̀lé Jesu ni Anderu arakunrin Simoni Peteru.


Johanu 1:42
Ó bá mú un lọ sọ́dọ̀ Jesu. Jesu tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ ni Simoni ọmọ Johanu; Kefa ni a óo máa pè ọ́.” (Ìtumọ̀ “Kefa” ni “àpáta”, “Peteru” ni ní èdè Giriki.)


Johanu 1:43
Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”


Johanu 1:45
Filipi wá rí Nataniẹli, ó wí fún un pé, “Àwa ti rí ẹni tí Mose kọ nípa rẹ̀ ninu Ìwé Òfin, tí àwọn wolii tún kọ nípa rẹ̀, Jesu ọmọ Josẹfu ará Nasarẹti.”


Johanu 1:47
Jesu rí Nataniẹli bí ó ti ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ nípa rẹ̀ pé, “Wo ọmọlúwàbí, ọmọ Israẹli tí kò ní ẹ̀tàn ninu.”


Johanu 1:48
Nataniẹli bi í pé, “Níbo ni o ti mọ̀ mí?” Jesu dá a lóhùn pé, “Kí Filipi tó pè ọ́, nígbà tí o wà ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́, mo ti rí ọ.”


Johanu 1:50
Jesu wí fún un pé, “Nítorí mo wí fún ọ pé mo rí ọ ní abẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ ni o ṣe gbàgbọ́? Ìwọ yóo rí ohun tí ó jù yìí lọ.”


Johanu 2:1
Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n ń ṣe igbeyawo kan ní Kana, ìlú kan ní Galili. Ìyá Jesu wà níbẹ̀.


Johanu 2:2
Wọ́n pe Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sí ibi igbeyawo náà.


Johanu 2:3
Nígbà tí ọtí tán, ìyá Jesu sọ fún un pé, “Wọn kò ní ọtí mọ́!”


Johanu 2:4
Jesu wí fún un pé, “Kí ni tèmi ati tìrẹ ti jẹ́, obinrin yìí? Àkókò mi kò ì tíì tó.”


Johanu 2:7
Jesu wí fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìkòkò wọnyi.” Wọ́n bá pọnmi kún wọn.


Johanu 2:11
Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.


Johanu 2:13
Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá àwọn Juu, Jesu gòkè lọ sí Jerusalẹmu.


Johanu 2:15
Jesu bá fi okùn kan ṣe ẹgba, ó bẹ̀rẹ̀ sí lé gbogbo wọn jáde kúrò ninu àgbàlá Ilé Ìrúbọ. Ó lé àwọn tí ń ta aguntan ati mààlúù jáde. Ó da gbogbo owó àwọn onípàṣípààrọ̀ nù, ó sì ti tabili wọn ṣubú.


Johanu 2:19
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá wó Tẹmpili yìí, èmi yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta.”


Johanu 2:22
Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ.


Johanu 2:23
Nígbà tí Jesu wà ní agbègbè Jerusalẹmu ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, ọpọlọpọ eniyan gba orúkọ rẹ̀ gbọ́ nígbà tí wọ́n ṣe akiyesi àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe.


Johanu 2:24
Ṣugbọn Jesu fúnrarẹ̀ kò gbára lé wọn, nítorí ó mọ gbogbo eniyan.


Johanu 3:2
Ọkunrin yìí fi òru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ó wí fún un pé, “Rabi, a mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni ọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ò ń ṣe wọnyi àfi ẹni tí Ọlọrun bá wà pẹlu rẹ̀.”


Johanu 3:3
Jesu bá gba ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, ó ní, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá tún bí láti ọ̀run kò lè rí ìjọba Ọlọrun.”


Johanu 3:5
Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá fi omi ati Ẹ̀mí bí, kò lè wọ ìjọba Ọlọrun.


Johanu 3:10
Jesu ní, “Mo ṣebí olùkọ́ni olókìkí ní Israẹli ni ọ́, sibẹ o kò mọ nǹkan wọnyi?


Johanu 3:22
Lẹ́yìn èyí, Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Judia, wọ́n ń gbé ibẹ̀, ó bá ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan.


Johanu 4:1
Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ ju àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu lọ; ati pé Jesu ń ṣe ìrìbọmi fún ọpọlọpọ eniyan ju Johanu lọ.


Johanu 4:2
Ṣugbọn ṣá, kì í ṣe Jesu fúnrarẹ̀ ni ó ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni.


Johanu 4:3
Nígbà tí Jesu mọ̀ pé àwọn Farisi ti gbọ́ ìròyìn yìí, ó kúrò ní Judia, ó tún pada lọ sí Galili.


Johanu 4:6
Kànga kan tí ó ní omi wà níbẹ̀, tí Jakọbu gbẹ́ nígbà ayé rẹ. Jesu jókòó létí kànga náà ní nǹkan bí agogo mejila ọ̀sán, àárẹ̀ ti mú un nítorí ìrìn àjò tí ó rìn.


Johanu 4:7
Obinrin kan ará Samaria wá pọn omi. Jesu wí fún un pé, “Fún mi ní omi mu.”


Johanu 4:9
Obinrin ará Samaria náà dá Jesu lóhùn pé, “Kí ló dé tí ìwọ tí ó jẹ́ Juu fi ń bèèrè omi lọ́wọ́ èmi tí mo jẹ́ obinrin ará Samaria?” (Gbolohun yìí jáde nítorí àwọn Juu kì í ní ohunkohun ṣe pẹlu àwọn ará Samaria.)


Johanu 4:10
Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.”


Johanu 4:13
Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi yìí òùngbẹ yóo tún gbẹ ẹ́.


Johanu 4:16
Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.”


Johanu 4:17
Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ,


Johanu 4:21
Jesu wí fún un pé, “Arabinrin, gbà mí gbọ́! Àkókò ń bọ̀ tí ó jẹ́ pé, ati ní orí òkè yìí ni, ati ní Jerusalẹmu ni, kò ní sí ibi tí ẹ óo ti máa sin Baba mọ́.


Johanu 4:26
Jesu wí fún un pé, “Èmi tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Mesaya náà.”


Johanu 4:30
Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu.


Johanu 4:31
Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.”


Johanu 4:34
Jesu wí fún wọn pé, “Ní tèmi, oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ati láti parí iṣẹ́ tí ó fún mi ṣe.


Johanu 4:43
Lẹ́yìn ọjọ́ meji, Jesu jáde kúrò níbẹ̀ lọ sí Galili.


Johanu 4:46
Jesu tún lọ sí ìlú Kana ti Galili níbi tí ó ti sọ omi di ọtí ní ìjelòó. Ìjòyè kan wà ní Kapanaumu tí ọmọ rẹ̀ ń ṣàìsàn.


Johanu 4:47
Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ.


Johanu 4:48
Jesu wí fún un pé, “Bí ẹ kò bá rí iṣẹ́ àmì ati iṣẹ́ ìyanu ẹ kò ní gbàgbọ́.”


Johanu 4:50
Jesu wí fún un pé, “Máa lọ, ọmọ rẹ yóo yè.” Ọkunrin náà gba ọ̀rọ̀ tí Jesu sọ fún un gbọ́, ó bá ń lọ sílé.


Johanu 4:53
Baba ọmọ náà mọ̀ pé àkókò náà gan-an ni Jesu sọ fún òun pé, “Ọmọ rẹ yóo yè.” Òun ati gbogbo ilé rẹ̀ bá gba Jesu gbọ́.


Johanu 4:54
Èyí ni iṣẹ́ abàmì keji tí Jesu ṣe nígbà tí ó kúrò ní Judia, tí ó wá sí Galili.


Johanu 5:1
Lẹ́yìn èyí, ó tó àkókò fún ọ̀kan ninu àjọ̀dún àwọn Juu: Jesu bá lọ sí Jerusalẹmu.


Johanu 5:6
Nígbà tí Jesu rí i tí ó dùbúlẹ̀ níbẹ̀, tí ó sì mọ̀ pé ó ti pẹ́ tí ó ti wà níbẹ̀, ó bi í pé, “Ṣé o fẹ́ ìmúláradá?”


Johanu 5:8
Jesu wí fún un pé, “Dìde, ká ẹní rẹ, kí o máa rìn.”


Johanu 5:13
Ṣugbọn ọkunrin náà tí Jesu wòsàn kò mọ ẹni tí ó wo òun sàn, nítorí pé eniyan pọ̀ níbẹ̀, ati pé Jesu ti yẹra kúrò níbẹ̀.


Johanu 5:14
Lẹ́yìn èyí, Jesu rí ọkunrin náà ninu Tẹmpili, ó wí fún un pé, “O rí i pé ara rẹ ti dá nisinsinyii, má dẹ́ṣẹ̀ mọ́ kí ohun tí ó burú ju èyí lọ má baà bá ọ.”


Johanu 5:15
Ọkunrin náà pada lọ sọ fún àwọn Juu pé, Jesu ni ẹni tí ó wo òun sàn.


Johanu 5:16
Nítorí èyí àwọn Juu dìtẹ̀ sí Jesu, nítorí ó ń ṣe nǹkan wọnyi ní Ọjọ́ Ìsinmi.


Johanu 5:17
Ṣugbọn Jesu dá wọn lóhùn pé, “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyìí, èmi náà sì ń ṣiṣẹ́.”


Johanu 5:19
Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe.


Johanu 6:1
Lẹ́yìn èyí, Jesu lọ sí òdìkejì òkun Galili tí ó tún ń jẹ́ òkun Tiberiasi.


Johanu 6:3
Jesu bá gun orí òkè lọ, ó jókòó níbẹ̀ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.


Johanu 6:5
Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó wá bi Filipi pé, “Níbo ni a ti lè ra oúnjẹ fún àwọn eniyan yìí láti jẹ?”


Johanu 6:10
Jesu ní, “Ẹ ní kí wọ́n jókòó.” Koríko pọ̀ níbẹ̀. Àwọn eniyan náà bá jókòó. Wọ́n tó bí ẹgbẹẹdọgbọn (5,000).


Johanu 6:11
Jesu wá mú burẹdi náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, ó bá pín in fún àwọn eniyan tí ó jókòó. Bákan náà ni ó ṣe sí ẹja, ó fún olukuluku bí ó ti ń fẹ́.


Johanu 6:12
Lẹ́yìn tí àwọn eniyan ti jẹ ẹja ní àjẹtẹ́rùn, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ kó oúnjẹ tí ó kù jọ, kí ohunkohun má baà ṣòfò.”


Johanu 6:15
Nígbà tí Jesu mọ̀ pé wọn ń fẹ́ wá fi ipá mú òun kí wọ́n sì fi òun jọba, ó yẹra kúrò níbẹ̀, òun nìkan tún pada lọ sórí òkè.


Johanu 6:17
wọ́n wọ ọkọ̀, wọ́n ń lọ sí Kapanaumu ní òdìkejì òkun. Òkùnkùn ti ṣú ṣugbọn Jesu kò ì tíì dé ọ̀dọ̀ wọn.


Johanu 6:19
Lẹ́yìn tí wọ́n ti wa ọkọ̀ bí ibùsọ̀ mẹta tabi mẹrin wọ́n rí Jesu, ó ń rìn lórí òkun, ó ti súnmọ́ etí ọkọ̀ wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n.


Johanu 6:22
Ní ọjọ́ keji, àwọn tí wọ́n dúró ní òdìkejì òkun rí i pé ọkọ̀ kanṣoṣo ni ó wà níbẹ̀. Wọ́n tún wòye pé Jesu kò bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wọ ọkọ̀; àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nìkan ni wọ́n lọ.


Johanu 6:24
Nígbà tí àwọn eniyan rí i pé Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò sí níbẹ̀, àwọn náà bọ́ sinu àwọn ọkọ̀ tí ó wà níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí tọpa Jesu lọ sí Kapanaumu.


Johanu 6:26
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí iṣẹ́ ìyanu mi ni ẹ ṣe ń wá mi, ṣugbọn nítorí ẹ jẹ oúnjẹ àjẹyó ni.


Johanu 6:29
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Iṣẹ́ Ọlọrun ni pé kí ẹ gba ẹni tí ó rán gbọ́.”


Johanu 6:32
Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe Mose ni ó fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá. Baba mi ni ó ń fun yín ní oúnjẹ láti ọ̀run wá;


Johanu 6:35
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae.


Johanu 6:42
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé, “Ṣebí Jesu ọmọ Josẹfu ni; ẹni tí a mọ baba ati ìyá rẹ̀? Ó ṣe wá sọ pé, láti ọ̀run ni òun ti sọ̀kalẹ̀ wá?”


Johanu 6:43
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ má ṣe kùn láàrin ara yín mọ́.


Johanu 6:53
Jesu wá wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, bí ẹ̀yin kò bá jẹ ẹran ara ọmọ eniyan, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò lè ní ìyè ninu yín.


Johanu 6:59
Jesu sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn ní Kapanaumu.


Johanu 6:61
Nígbà tí Jesu rí i pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń kùn nítorí rẹ̀, ó bi wọ́n pé, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí ni ó mú kí ọkàn yín dààmú?


Johanu 6:64
Ṣugbọn àwọn tí kò gbàgbọ́ wà ninu yín.” Jesu sọ èyí nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó ti mọ àwọn tí kò gbàgbọ́ ati ẹni tí yóo fi òun lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.


Johanu 6:67
Jesu bá bi àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila pé, “Ẹ̀yin náà fẹ́ lọ bí?”


Johanu 6:70
Jesu bá sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ̀yin mejila ni mo yàn. Ṣugbọn ẹni ibi ni ọ̀kan ninu yín.”


Johanu 7:1
Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á.


Johanu 7:3
Àwọn arakunrin Jesu sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín kí o lọ sí Judia, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ lè rí iṣẹ́ tí ò ń ṣe,


Johanu 7:6
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò tí ó wọ̀ fún mi kò ì tíì tó, ìgbà gbogbo ni ó wọ̀ fún ẹ̀yin.


Johanu 7:10
Lẹ́yìn tí àwọn arakunrin Jesu ti lọ sí ibi àjọ̀dún náà, òun náà wá lọ. Ṣugbọn, kò lọ ní gbangba, yíyọ́ ni ó yọ́ lọ.


Johanu 7:14
Nígbà tí àjọ̀dún ti fẹ́rẹ̀ kọjá ìdajì, Jesu lọ sí Tẹmpili, ó ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́.


Johanu 7:16
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ̀kọ́ tèmi kì í ṣe ti ara mi, ti ẹni tí ó rán mi níṣẹ́ ni.


Johanu 7:21
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣe iṣẹ́ kan, ẹnu ya gbogbo yín.


Johanu 7:28
Ni Jesu bá kígbe sókè bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili. Ó ní, “Òtítọ́ ni pe ẹ mọ̀ mí, ẹ sì mọ ibi tí mo ti wá. Ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, olóòótọ́ ni ẹni tí ó rán mi, tí ẹ̀yin kò mọ̀.


Johanu 7:32
Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn eniyan ń sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ báyìí láàrin ara wọn nípa Jesu. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá rán àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili pé kí wọ́n lọ mú Jesu wá.


Johanu 7:33
Jesu bá dáhùn pé, “Àkókò díẹ̀ ni ó kù tí n óo lò pẹlu yín, lẹ́yìn náà n óo lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.


Johanu 7:37
Nígbà tí ó di ọjọ́ tíí àjọ̀dún yóo parí, tíí ṣe ọjọ́ tí ó ṣe pataki jùlọ, Jesu dìde dúró, ó kígbe pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó mu omi.


Johanu 7:39
Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo.


Johanu 7:45
Nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili tí wọ́n rán lọ mú Jesu pada dé ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n bi wọ́n pé, “Kí ló dé tí ẹ kò fi mú un wá?”


Johanu 7:50
Ọ̀kan ninu àwọn Farisi ọ̀hún ni Nikodemu, ẹni tí ó lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan. Ó bi wọ́n léèrè pé,


Johanu 8:1
[ Ni olukuluku wọn bá lọ sí ilé wọn; ṣugbọn Jesu lọ sí Òkè Olifi.


Johanu 8:4
wọ́n wá sọ fún Jesu pé, “Olùkọ́ni, a ká obinrin yìí mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè, a ká a mọ́ ọn gan-an ni!


Johanu 8:6
Wọ́n sọ èyí láti fi ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu ni kí wọ́n lè fi ẹ̀sùn kàn án. Jesu bá bẹ̀rẹ̀, ó ń fi ìka kọ nǹkan sórí ilẹ̀.


Johanu 8:10
Nígbà tí Jesu gbé ojú sókè, ó bi obinrin náà pé, “Obinrin, àwọn dà? Ẹnìkan ninu wọn kò dá ọ lẹ́bi?”


Johanu 8:11
Ó ní, “Alàgbà, ẹnìkankan kò dá mi lẹ́bi.” Jesu wí fún un pé, “Èmi náà kò dá ọ lẹ́bi. Máa lọ; láti ìsinsìnyìí lọ, má ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́.”]


Johanu 8:12
Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”


Johanu 8:14
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá ń jẹ́rìí ara mi, sibẹ òtítọ́ ni ẹ̀rí mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn ẹ̀yin kò mọ ibi tí mo ti wá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì mọ ibi tí mò ń lọ.


Johanu 8:19
Wọ́n bi í pé, “Níbo ni baba rẹ wà?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ kò mọ̀ mí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mọ Baba mi. Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ̀ mí, ẹ̀ bá mọ Baba mi.”


Johanu 8:20
Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.


Johanu 8:21
Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ ní tèmi; ẹ óo máa wá mi kiri, ẹ óo sì kú sinu ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ kò ní lè dé ibi tí mò ń lọ.”


Johanu 8:25
Wọ́n bi í pé, “Ta ni ọ́?” Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ti sọ ẹni tí mo jẹ́ fun yín láti ìbẹ̀rẹ̀.


Johanu 8:28
Jesu tún wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ bá gbé Ọmọ-Eniyan sókè, nígbà náà ni ẹ óo mọ̀ pé èmi ni, ati pé èmi kò dá ohunkohun ṣe fúnra mi, ṣugbọn bí Baba ti kọ́ mi ni mò ń sọ̀rọ̀ yìí.


Johanu 8:30
Nígbà tí Jesu sọ ọ̀rọ̀ báyìí, ọpọlọpọ eniyan gbà á gbọ́.


Johanu 8:31
Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́;


Johanu 8:34
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.


Johanu 8:39
Wọ́n sọ fún un pé, “Abrahamu ni baba wa.” Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ọmọ Abrahamu ni yín, irú ohun tí Abrahamu ṣe ni ẹ̀ bá máa ṣe.


Johanu 8:42
Jesu wí fún wọn pé, “Ìbá jẹ́ pé Ọlọrun ni baba yín, ẹ̀ bá fẹ́ràn mi, nítorí ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni mo ti wá. Nítorí kì í ṣe èmi ni mo rán ara mi wá, ṣugbọn òun ni ó rán mi.


Johanu 8:49
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi kò ní ẹ̀mí èṣù rárá! Èmi ń bu ọlá fún Baba mi, ṣugbọn ẹ̀yin ń bu ẹ̀tẹ́ lù mí.


Johanu 8:54
Jesu dáhùn pé, “Bí mo bá bu ọlá fún ara mi, òfo ni ọlá mi. Baba mi ni ó bu ọlá fún mi, òun ni ẹ̀yin ń pè ní Ọlọrun yín.


Johanu 8:58
Jesu wí fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kí wọ́n tó bí Abrahamu ni èmi ti wà.”


Johanu 9:1
Bí Jesu ti ń kọjá lọ, ó rí ọkunrin kan tí ó fọ́jú láti inú ìyá rẹ̀ wá.


Johanu 9:3
Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni.


Johanu 9:11
Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”


Johanu 9:14
(Ọjọ́ Ìsinmi ni ọjọ́ tí Jesu po amọ̀, tí ó fi la ojú ọkunrin náà.)


Johanu 9:22
Àwọn òbí rẹ̀ fèsì báyìí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu; nítorí àwọn Juu ti pinnu láti yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu ni Mesaya kúrò ninu àwùjọ.


Johanu 9:35
Jesu gbọ́ pé wọ́n ti ti ọkunrin náà jáde kúrò ninu ilé ìpàdé. Nígbà tí ó rí i, ó bí i pé, “Ìwọ gba Ọmọ-Eniyan gbọ́ bí?”


Johanu 9:37
Jesu wí fún un pé, “Èmi tí ò ń wò yìí, tí mò ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni ẹni náà.”


Johanu 9:39
Jesu bá ní, “Kí n lè ṣe ìdájọ́ ni mo ṣe wá sí ayé yìí, kí àwọn tí kò ríran lè ríran, kí àwọn tí ó ríran lè di afọ́jú.”


Johanu 9:41
Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ fọ́jú, ẹ kò bá tí ní ẹ̀bi. Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ sọ pé, ‘Àwa ríran’ ẹ̀bi yín wà sibẹ.”


Johanu 10:6
Òwe yìí ni Jesu fi bá wọn sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ó ń bá wọn sọ kò yé wọn.


Johanu 10:7
Jesu tún sọ pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn aguntan.


Johanu 10:23
Jesu ń rìn kiri ní apá ọ̀dẹ̀dẹ̀ tí wọn ń pè ní Ọ̀dẹ̀dẹ̀ Solomoni ninu Tẹmpili.


Johanu 10:25
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo sọ fun yín, ẹ kò gbàgbọ́. Iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí mi,


Johanu 10:32
Jesu wá bi wọ́n pé, “Ọpọlọpọ iṣẹ́ rere ni mo ti fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba. Nítorí èwo ni ẹ fi fẹ́ sọ mí ní òkúta ninu wọn?”


Johanu 10:34
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo ṣebí àkọsílẹ̀ kan wà ninu Òfin yín pé, ‘Ọlọrun sọ pé ọlọrun ni yín.’


Johanu 11:2
Maria yìí ni obinrin tí ó tú òróró olóòórùn dídùn sára Oluwa ní ọjọ́ kan, tí ó fi irun orí rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jesu. Lasaru tí ó ń ṣàìsàn jẹ́ arakunrin Maria yìí.


Johanu 11:3
Àwọn arabinrin mejeeji yìí ranṣẹ lọ sọ́dọ̀ Jesu pé, “Oluwa, ẹni tí o fẹ́ràn ń ṣàìsàn.”


Johanu 11:4
Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.”


Johanu 11:5
Jesu fẹ́ràn Mata ati arabinrin rẹ̀ ati Lasaru.


Johanu 11:6
Nígbà tí Jesu gbọ́ pé Lasaru ń ṣàìsàn, kò kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ́ meji.


Johanu 11:9
Jesu ní, “Ṣebí wakati mejila ni ó wà ninu ọjọ́ kan? Bí ẹnikẹ́ni bá rìn ní ọ̀sán kò ní kọsẹ̀, nítorí ó ń fi ìmọ́lẹ̀ ayé yìí ríran.


Johanu 11:13
Ohun tí Jesu ń sọ̀rọ̀ bá ni ikú Lasaru, ṣugbọn wọ́n rò pé nípa oorun sísùn ni ó ń sọ.


Johanu 11:14
Nígbà náà ni Jesu wá wí fún wọn pàtó pé, “Lasaru ti kú.


Johanu 11:17
Nígbà tí Jesu dé, ó rí i pé ó ti tó ọjọ́ mẹrin tí òkú náà ti wà ninu ibojì.


Johanu 11:20
Nígbà tí Mata gbọ́ pé Jesu ń bọ̀, ó jáde lọ pàdé rẹ̀. Ṣugbọn Maria jókòó ninu ilé.


Johanu 11:21
Mata sọ fún Jesu pé, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú!


Johanu 11:23
Jesu wí fún un pé, “Arakunrin rẹ yóo jí dìde.”


Johanu 11:25
Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ajinde ati ìyè. Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, bí ó tilẹ̀ kú, sibẹ yóo yè.


Johanu 11:29
Bí Maria ti gbọ́, ó dìde kíá, ó bá lọ sọ́dọ̀ Jesu.


Johanu 11:30
(Jesu kò tíì wọ ìlú, ó wà ní ibi tí Mata ti pàdé rẹ̀.)


Johanu 11:32
Nígbà tí Maria dé ibi tí Jesu wà, bí ó ti rí i, ó kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó ní, “Oluwa, ìbá jẹ́ pé o wà níhìn-ín, arakunrin mi kì bá tí kú.”


Johanu 11:33
Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́.


Johanu 11:35
Ni Jesu bá bú sẹ́kún.


Johanu 11:38
Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀.


Johanu 11:39
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” Mata, arabinrin ẹni tí ó kú, sọ fún un pé, “Oluwa, ó ti ń rùn, nítorí ó ti di òkú ọjọ́ mẹrin!”


Johanu 11:40
Jesu wí fún un pé, “Ṣebí mo ti sọ fún ọ pé bí o bá gbàgbọ́ ìwọ yóo rí ògo Ọlọrun.”


Johanu 11:41
Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi.


Johanu 11:44
Ẹni tí ó ti kú náà bá jáde pẹlu aṣọ òkú tí wọ́n fi wé e lọ́wọ́ ati lẹ́sẹ̀ ati ọ̀já tí wọ́n fi dì í lójú. Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ tú aṣọ kúrò lára rẹ̀, kí ẹ jẹ́ kí ó máa lọ.”


Johanu 11:45
Ọpọlọpọ ninu àwọn Juu tí ó wá sọ́dọ̀ Maria gba Jesu gbọ́ nígbà tí wọ́n rí ohun tí ó ṣe.


Johanu 11:46
Ṣugbọn àwọn kan ninu wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Farisi, wọ́n lọ sọ ohun gbogbo tí Jesu ṣe.


Johanu 11:51
Kì í ṣe àròsọ ti ara rẹ̀ ni ó fi sọ gbolohun yìí, ṣugbọn nítorí ó jẹ́ olórí alufaa ní ọdún náà, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ ni, pé Jesu yóo kú fún orílẹ̀-èdè wọn.


Johanu 11:53
Láti ọjọ́ náà ni wọ́n ti ń gbèrò ọ̀nà tí wọn yóo fi pa Jesu.


Johanu 11:54
Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.


Johanu 11:56
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Jesu, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti dúró ninu Tẹmpili pé, “Kí ni ẹ rò? Ǹjẹ́ ó jẹ́ wá sí àjọ̀dún yìí?”


Johanu 11:57
Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.


Johanu 12:1
Nígbà tí Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ mẹfa, Jesu lọ sí Bẹtani níbi tí Lasaru wà, ẹni tí ó kú, tí Jesu jí dìde.


Johanu 12:2
Wọ́n se àsè kan fún un níbẹ̀. Mata ń ṣe ètò gbígbé oúnjẹ kalẹ̀; Lasaru wà ninu àwọn tí ó ń bá Jesu jẹun.


Johanu 12:3
Nígbà náà ni Maria dé, ó mú ìgò kékeré kan lọ́wọ́. Ojúlówó òróró ìpara kan, olówó iyebíye ni ó wà ninu ìgò náà. Ó bá tú òróró yìí sí Jesu lẹ́sẹ̀, ó ń fi irun orí rẹ̀ nù ún. Òórùn òróró náà bá gba gbogbo ilé.


Johanu 12:7
Jesu dá a lóhùn pé, “Fi í sílẹ̀! Jẹ́ kí ó fi pamọ́ di ọjọ́ ìsìnkú mi.


Johanu 12:9
Nígbà tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu mọ̀ pé Jesu wà ní Bẹtani, wọ́n lọ sibẹ, kì í ṣe nítorí ti Jesu nìkan, ṣugbọn nítorí kí wọ́n lè rí Lasaru tí Jesu jí dìde kúrò ninu òkú.


Johanu 12:11
nítorí pé nítorí rẹ̀ ni ọpọlọpọ àwọn Juu ṣe ń kúrò ninu ẹ̀sìn wọn, tí wọn ń gba Jesu gbọ́.


Johanu 12:12
Ní ọjọ́ keji, ọpọlọpọ eniyan tí ó wá ṣe àjọ̀dún gbọ́ pé Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu.


Johanu 12:14
Jesu rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó bá gùn un, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé,


Johanu 12:16
Gbogbo nǹkan wọnyi kò yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ní àkókò yìí, ṣugbọn nígbà tí a ti ṣe Jesu lógo, wọ́n ranti pé a ti kọ gbogbo nǹkan wọnyi nípa rẹ̀ ati pé wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan wọnyi sí i.


Johanu 12:17
Àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu Jesu nígbà tí ó fi pe Lasaru jáde kúrò ninu ibojì, tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú, ń ròyìn ohun tí wọ́n rí.


Johanu 12:21
Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Filipi tí ó jẹ́ ará Bẹtisaida, ìlú kan ní Galili, wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà, a fẹ́ rí Jesu.”


Johanu 12:22
Filipi lọ sọ fún Anderu, Anderu ati Filipi bá jọ lọ sọ fún Jesu.


Johanu 12:23
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo.


Johanu 12:27
Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé.


Johanu 12:30
Jesu wí fún wọn pé, “Ohùn yìí kò wá nítorí tèmi bí kò ṣe nítorí tiyín.


Johanu 12:35
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ.


Johanu 12:36
Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, ẹ gba ìmọ́lẹ̀ náà gbọ́, kí ẹ lè jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀.” Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó fara pamọ́ fún wọn.


Johanu 12:37
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́.


Johanu 12:41
Aisaya sọ nǹkan wọnyi nítorí ó rí ògo Jesu, ó wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.


Johanu 12:44
Jesu bá kígbe pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, kì í ṣe èmi ni ó gbàgbọ́ bíkòṣe ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.


Johanu 13:1
Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin.


Johanu 13:2
Bí wọ́n ti ń jẹun, Èṣù ti fi sí Judasi ọmọ Simoni Iskariotu lọ́kàn láti fi Jesu lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.


Johanu 13:3
Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ.


Johanu 13:7
Jesu dá a lóhùn pé, “O kò mọ ohun tí mò ń ṣe nisinsinyii; ṣugbọn yóo yé ọ tí ó bá yá.”


Johanu 13:8
Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!” Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.”


Johanu 13:10
Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.”


Johanu 13:21
Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó bá wí tẹ̀dùntẹ̀dùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, ọ̀kan ninu yín ni yóo fi mí lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́.”


Johanu 13:22
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú; nítorí ohun tí Jesu sọ rú wọn lójú.


Johanu 13:23
Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí.


Johanu 13:25
Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà túbọ̀ súnmọ́ Jesu sí i, ó bi í pé, “Oluwa, ta ni rí?”


Johanu 13:26
Jesu dáhùn pé, “Ẹni tí mo bá fún ní òkèlè lẹ́yìn tí mo bá ti fi run ọbẹ̀ tán ni ẹni náà.” Nígbà tí ó ti fi òkèlè run ọbẹ̀, ó mú un fún Judasi ọmọ Iskariotu.


Johanu 13:27
Lẹ́yìn tí Judasi ti gba òkèlè náà, Satani wọ inú rẹ̀. Jesu bá wí fún un pé, “Tètè ṣe ohun tí o níí ṣe.”


Johanu 13:28
Kò sí ẹnìkan ninu àwọn tí wọ́n jọ ń jẹun tí ó mọ ìdí tí Jesu fi sọ ọ̀rọ̀ yìí fún un.


Johanu 13:29
Nígbà tí ó jẹ́ pé Judasi ni akápò, àwọn mìíràn ń rò pé ohun tí Jesu sọ fún un ni pé, “Lọ ra àwọn ohun tí a óo lò fún Àjọ̀dún Ìrékọjá, tabi ohun tí a óo fún àwọn talaka.”


Johanu 13:31
Nígbà tí Judasi jáde, Jesu wí pé, “Nisinsinyii ni ògo Ọmọ-Eniyan wá yọ. Ògo Ọlọrun pàápàá yọ lára Ọmọ-Eniyan.


Johanu 13:36
Simoni Peteru bi í pé, “Oluwa, níbo ni ò ń lọ?” Jesu dá a lóhùn pé, “Níbi tí mò ń lọ, ìwọ kò lè tẹ̀lé mi nisinsinyii, ṣugbọn nígbà tí ó bá yá, ìwọ óo tẹ̀lé mi.”


Johanu 13:38
Jesu dá a lóhùn pé, “O ṣetán láti kú nítorí mi? Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, kí àkùkọ tó kọ ìwọ óo sẹ́ mi lẹẹmẹta.


Johanu 14:6
Jesu wí fún un pé, “Èmi ni ọ̀nà, ati òtítọ́ ati ìyè. Kò sí ẹni tí ó lè dé ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe nípasẹ̀ mi.


Johanu 14:9
Jesu wí fún un pé, “Bí mo ti pẹ́ lọ́dọ̀ yín tó yìí, sibẹ ìwọ kò mọ̀ mí, Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi ti rí Baba. Kí ló dé tí o fi tún ń sọ pé, ‘Fi Baba hàn wá?’


Johanu 14:23
Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ràn mi yóo tẹ̀lé ọ̀rọ̀ mi. Baba mi yóo fẹ́ràn rẹ̀, èmi ati Baba mi yóo wá sọ́dọ̀ rẹ̀, a óo fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùgbé.


Johanu 16:19
Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’


Johanu 16:31
Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ wá gbàgbọ́ nisinsinyii?


Johanu 17:1
Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ.


Johanu 17:3
Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́.


Johanu 18:1
Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.


Johanu 18:2
Judasi, ẹni tí ó fi í fún àwọn ọ̀tá, mọ ibẹ̀, nítorí ìgbà pupọ ni Jesu ti máa ń lọ sibẹ pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.


Johanu 18:4
Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”


Johanu 18:5
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.” Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.” Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn.


Johanu 18:7
Ó tún bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n dáhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.”


Johanu 18:8
Jesu wí fún wọn pé, “Mo sọ fun yín pé èmi gan-an nìyí. Bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ̀ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọnyi máa lọ.”


Johanu 18:11
Jesu bá sọ fún Peteru pé, “Ti idà rẹ bọ inú àkọ̀. Àbí kí n má jẹ ìrora ńlá tí Baba ti yàn fún mi ni?”


Johanu 18:12
Ni àwọn ọmọ-ogun ati ọ̀gágun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn Juu bá mú Jesu, wọ́n dè é,


Johanu 18:15
Ṣugbọn Simoni Peteru ń tẹ̀lé Jesu pẹlu ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn. Ọmọ-ẹ̀yìn keji yìí jẹ́ ẹni tí Olórí Alufaa mọ̀.


Johanu 18:19
Olórí Alufaa bi Jesu nípa àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ati nípa ẹ̀kọ́ rẹ̀.


Johanu 18:20
Jesu dá a lóhùn pé, “Ní gbangba ni èmi tí máa ń bá aráyé sọ̀rọ̀. Ninu ilé ìpàdé ati ninu Tẹmpili ni èmi tí máa ń kọ́ àwọn eniyan nígbà gbogbo, níbi tí gbogbo àwọn Juu ń péjọ sí, n kò sọ ohunkohun níkọ̀kọ̀.


Johanu 18:22
Bí ó ti sọ báyìí tán ni ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ó dúró níbẹ̀ bá gbá Jesu létí, ó ní, “Olórí Alufaa ni o dá lóhùn bẹ́ẹ̀!”


Johanu 18:23
Jesu dá a lóhùn pé, “Bí burúkú ni mo bá sọ, wí ohun tí ó burú níbẹ̀ kí ayé gbọ́. Tí ó bá jẹ́ rere ni mo sọ, kí ló dé tí o fi lù mí?”


Johanu 18:24
Nígbà náà ni Anasi fi Jesu ranṣẹ ní dídè sí Kayafa, Olórí Alufaa.


Johanu 18:28
Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá.


Johanu 18:32
Gbolohun yìí jáde kí ọ̀rọ̀ Jesu lè ṣẹ nígbà tí ó ń ṣàpẹẹrẹ irú ikú tí òun yóo kú.


Johanu 18:33
Pilatu bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”


Johanu 18:34
Jesu dáhùn pé, “O wí èyí fúnrarẹ ni àbí ẹlòmíràn ni ó sọ bẹ́ẹ̀ fún ọ nípa mi?”


Johanu 18:36
Jesu dá a lóhùn pé, “Ìjọba mi kì í ṣe ti ayé yìí. Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé yìí ni ìjọba mi, àwọn iranṣẹ mi ìbá jà; àwọn Juu kì bá tí lè mú mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi kì í ṣe ti ìhín.”


Johanu 18:37
Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”


Johanu 19:1
Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án.


Johanu 19:5
Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”


Johanu 19:9
Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn.


Johanu 19:11
Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.”


Johanu 19:12
Láti ìgbà náà ni Pilatu ti ń wá ọ̀nà láti dá Jesu sílẹ̀. Ṣugbọn àwọn Juu ń kígbe pé, “Bí o bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀, ìwọ kì í ṣe ọ̀rẹ́ Kesari, gbogbo ẹni tí ó bá fi ara rẹ̀ jọba lòdì sí Kesari.”


Johanu 19:13
Nígbà tí Pilatu gbọ́ bẹ́ẹ̀, ó mú Jesu jáde, ó wá jókòó lórí pèpéle ìdájọ́ níbìkan tí wọn ń pè ní “Pèpéle olókùúta,” tí ń jẹ́ “Gabata” ní èdè Heberu.


Johanu 19:16
Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu. Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu.


Johanu 19:18
Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin.


Johanu 19:19
Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.”


Johanu 19:23
Nígbà tí wọ́n kan Jesu mọ́ agbelebu tán, àwọn ọmọ-ogun pín àwọn aṣọ rẹ̀ sí ọ̀nà mẹrin, wọ́n mú un ní ọ̀kọ̀ọ̀kan. Ó wá tún ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ yìí kò ní ojúùrán, híhun ni wọ́n hun ún láti òkè dé ilẹ̀.


Johanu 19:25
Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu.


Johanu 19:26
Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.”


Johanu 19:27
Ó bá sọ fún ọmọ-ẹ̀yìn náà pé, “Wo ìyá rẹ.” Láti ìgbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà ti mú ìyá Jesu lọ sílé ara rẹ̀.


Johanu 19:28
Lẹ́yìn èyí, nígbà tí Jesu mọ̀ pé ohun gbogbo ti parí, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ, ó ní, “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”


Johanu 19:30
Lẹ́yìn tí Jesu ti gba ọtí náà tán, ó wí pé, “Ó ti parí!” Lẹ́yìn náà ó tẹrí ba, ó bá dákẹ́.


Johanu 19:32
Àwọn ọmọ-ogun bá lọ, wọ́n dá ekinni-keji àwọn tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu pẹlu Jesu lójúgun.


Johanu 19:33
Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu wọ́n rí i pé ó ti kú, nítorí náà wọn kò dá a lójúgun.


Johanu 19:38
Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ wọnyi, Josẹfu ará Arimatia bẹ Pilatu pé kí ó jẹ́ kí òun gbé òkú Jesu lọ. Josẹfu yìí jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó fara pamọ́ nítorí ó bẹ̀rù àwọn Juu. Pilatu bá fún un ní àṣẹ láti gbé òkú Jesu. Ó bá lọ gbé e.


Johanu 19:39
Nikodemu, tí ó fòru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu nígbà kan rí, mú àdàlú òróró olóòórùn dídùn olówó iyebíye oríṣìí meji wá, wíwúwo rẹ̀ tó ọgbọ̀n kilogiramu.


Johanu 19:40
Wọ́n fi òróró yìí tọ́jú òkú Jesu, wọ́n bá wé e ní aṣọ-ọ̀gbọ̀ gẹ́gẹ́ bí àṣà ìsìnkú àwọn Juu.


Johanu 19:41
Ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti kan Jesu mọ́ agbelebu. Ibojì titun kán wà ninu ọgbà náà, wọn kò ì tíì sin òkú kankan sinu rẹ̀ rí.


Johanu 19:42
Wọ́n tẹ́ òkú Jesu sibẹ, nítorí ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn Juu ni, ati pé ibojì náà súnmọ́ tòsí.


Johanu 20:2
Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”


Johanu 20:12
ó bá rí àwọn angẹli meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun, ọ̀kan jókòó níbi orí, ekeji jókòó níbi ẹsẹ̀ ibi tí wọ́n tẹ́ òkú Jesu sí.


Johanu 20:14
Bí ó ti sọ báyìí tán, ó bojú wẹ̀yìn, ó bá rí Jesu tí ó dúró, ṣugbọn kò mọ̀ pé òun ni.


Johanu 20:15
Jesu bi í pé, “Obinrin, kí ní dé tí ò ń sunkún? Ta ni ò ń wá?” Maria ṣebí olùṣọ́gbà ni. Ó sọ fún un pé, “Alàgbà, bí o bá ti gbé e lọ, sọ ibi tí o tẹ́ ẹ sí fún mi, kí n lè lọ gbé e.”


Johanu 20:16
Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!” Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”)


Johanu 20:17
Jesu bá sọ fún un pé, “Mú ọwọ́ kúrò lára mi, nítorí n kò ì tíì gòkè tọ Baba mi lọ. Ṣugbọn lọ sọ́dọ̀ àwọn arakunrin mi, kí o sọ fún wọn pé, ‘Mò ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi ati Baba yín, Ọlọrun mi ati Ọlọrun yín.’ ”


Johanu 20:18
Maria Magidaleni bá lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Mo ti rí Oluwa!” Ó bá sọ ohun tí Jesu sọ fún un fún wọn.


Johanu 20:19
Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà, tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu, Jesu dé, ó dúró láàrin wọn. Ó kí wọn pé, “Alaafia fun yín!”


Johanu 20:24
Ṣugbọn Tomasi, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila tí wọn ń pè ní Didimu (èyí ni “Ìbejì”) kò sí láàrin àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nígbà tí Jesu farahàn wọ́n.


Johanu 20:26
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹjọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tún wà ninu ilé, Tomasi náà wà láàrin wọn. Ìlẹ̀kùn wà ní títì bẹ́ẹ̀ ni Jesu bá tún dé, ó dúró láàrin wọn, ó ní, “Alaafia fun yín!”


Johanu 20:29
Jesu wí fún un pé, “O wá gbàgbọ́ nítorí o rí mi! Àwọn tí ó gbàgbọ́ láì rí mi ṣe oríire!”


Johanu 20:30
Ọpọlọpọ nǹkan ati iṣẹ́ abàmì mìíràn ni Jesu ṣe lójú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tí a kò kọ sinu ìwé yìí.


Johanu 20:31
Ṣugbọn a kọ ìwọ̀nyí kí ẹ lè gbàgbọ́ pé Jesu ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun, ati pé tí ẹ bá gbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè ní orúkọ rẹ̀.


Johanu 21:1
Lẹ́yìn èyí, Jesu tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní òkun Tiberiasi. Bí ó ṣe farahàn wọ́n nìyí:


Johanu 21:4
Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.


Johanu 21:5
Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!”


Johanu 21:7
Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté.


Johanu 21:10
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ mú wá ninu ẹja tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ pa.”


Johanu 21:12
Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ wá jẹun.” Kò sí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tí ó bi í pé, “Ta ni ọ́?” Wọ́n mọ̀ pé Oluwa ni.


Johanu 21:13
Jesu wá, ó mú burẹdi, ó fi fún wọn. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó fún wọn ní ẹja jẹ.


Johanu 21:14
Èyí ni ó di ìgbà kẹta tí Jesu fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lẹ́yìn ajinde rẹ̀ ninu òkú.


Johanu 21:15
Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jesu bi Simoni Peteru pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi ju àwọn wọnyi lọ?” Peteru dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ aguntan mi.”


Johanu 21:16
Jesu tún bi í lẹẹkeji pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó tún dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu wí fún un pé, “Máa tọ́jú àwọn aguntan mi.”


Johanu 21:17
Jesu tún bi í ní ẹẹkẹta pé, “Simoni ọmọ Johanu, ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó dun Peteru nítorí Jesu bi í ní ẹẹkẹta pé, “Ǹjẹ́ o fẹ́ràn mi?” Ó wá sọ fún Jesu pé, “Oluwa, o mọ ohun gbogbo, o mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.” Jesu sọ fún un pé, “Máa bọ́ àwọn aguntan mi.


Johanu 21:19
(Jesu sọ èyí bí àkàwé irú ikú tí Peteru yóo fi yin Ọlọrun lógo.) Nígbà tí Jesu sọ báyìí tán, ó wí fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”


Johanu 21:20
Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?”


Johanu 21:21
Nígbà tí Peteru rí i, ó bi Jesu pé, “Oluwa, eléyìí ńkọ́?”


Johanu 21:22
Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́? Ìwọ sá máa tẹ̀lé mi ní tìrẹ.”


Johanu 21:25
Ọpọlọpọ nǹkan mìíràn ni Jesu ṣe, bí a bá kọ wọ́n ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, mo rò pé kò ní sí ààyè tó ní gbogbo ayé tí yóo gba ìwé tí a bá kọ wọ́n sí.


Ìṣe àwọn Aposteli 1:1
Tiofilu mi ọ̀wọ́n: Ninu ìwé mi àkọ́kọ́, mo ti sọ nípa gbogbo ohun tí Jesu ṣe ati ẹ̀kọ́ tí ó ń kọ́ àwọn eniyan,


Ìṣe àwọn Aposteli 1:11
Wọ́n ní, “Ẹ̀yin ará Galili, kí ló dé tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ń wòkè bẹ́ẹ̀? Jesu kan náà, tí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, lọ sí ọ̀run yìí, yóo tún pada wá bí ẹ ṣe rí i tí ó ń lọ sí ọ̀run.”


Ìṣe àwọn Aposteli 1:14
Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 1:16
“Ẹ̀yin ará, dandan ni pé kí ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ ninu Ìwé Mímọ́ láti ẹnu Dafidi ṣẹ, nípa ọ̀rọ̀ Judasi tí ó ṣe amọ̀nà àwọn tí ó mú Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 1:21
“Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.”


Ìṣe àwọn Aposteli 2:22
“Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 2:32
Jesu yìí ni Ọlọrun jí dìde. Gbogbo àwa yìí sì ni ẹlẹ́rìí.


Ìṣe àwọn Aposteli 2:36
“Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!”


Ìṣe àwọn Aposteli 3:6
Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.”


Ìṣe àwọn Aposteli 3:13
Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó dá Ọmọ rẹ̀, Jesu lọ́lá. Jesu yìí ni ẹ fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, òun ni ẹ sẹ́ níwájú Pilatu nígbà tí ó fi dá a sílẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 3:16
Orúkọ Jesu ati igbagbọ ninu orúkọ yìí ni ó mú ọkunrin tí ẹ rí yìí lára dá. Ẹ ṣá mọ̀ ọ́n. Igbagbọ ninu rẹ̀ ni ó fún ọkunrin yìí ní ìlera patapata, gẹ́gẹ́ bí gbogbo yín ti rí i fúnra yín.


Ìṣe àwọn Aposteli 3:20
Nígbà náà, àkókò ìtura láti ọ̀dọ̀ Oluwa, yóo dé ba yín; Oluwa yóo wá rán Mesaya tí ó ti yàn tẹ́lẹ̀ si yín, èyí nnì ni Jesu,


Ìṣe àwọn Aposteli 4:2
Inú bí wọn nítorí wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan pé àwọn òkú yóo jí dìde. Wọ́n fi ajinde ti Jesu ṣe àpẹẹrẹ.


Ìṣe àwọn Aposteli 4:10
ẹ jẹ́ kí ó hàn sí gbogbo yín ati gbogbo eniyan Israẹli pé, ọkunrin yìí dúró níwájú yín pẹlu ara líle nítorí orúkọ Jesu Kristi ará Nasarẹti, ẹni tí ẹ kàn mọ́ agbelebu, tí Ọlọrun jí dìde kúrò ninu òkú.


Ìṣe àwọn Aposteli 4:11
Jesu yìí ni ‘Òkúta tí àwọn ọ̀mọ̀lé kọ̀ sílẹ̀, tí ó wá di òkúta pataki igun-ilé.’


Ìṣe àwọn Aposteli 4:13
Nígbà tí wọ́n rí ìgboyà Peteru ati ti Johanu, tí wọ́n wòye pé wọn kò mọ ìwé àtipé òpè eniyan ni wọ́n, ẹnu yà wọ́n. Wọ́n ṣe akiyesi wọn pé wọ́n ti wà pẹlu Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 4:17
Ṣugbọn kí ó má baà tún máa tàn kálẹ̀ sí i láàrin àwọn eniyan, ẹ jẹ́ kí á kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ dárúkọ Jesu fún ẹnikẹ́ni mọ́.”


Ìṣe àwọn Aposteli 4:18
Àwọn ìgbìmọ̀ bá tún pè wọ́n wọlé, wọ́n pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ tún dárúkọ Jesu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ tún fi orúkọ Jesu kọ́ àwọn eniyan mọ́.


Ìṣe àwọn Aposteli 4:27
Nítorí òdodo ni pé Hẹrọdu ati Pọntiu Pilatu pẹlu àwọn tí kì í ṣe Juu ati àwọn eniyan Israẹli péjọpọ̀ ní ìlú yìí, wọ́n ṣe ohun tí ó lòdì sí ọmọ mímọ́ rẹ, Jesu tí o ti fi òróró yàn ní Mesaya,


Ìṣe àwọn Aposteli 4:30
Kí o wá na ọwọ́ rẹ kí o ṣe ìwòsàn, ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu nípa orúkọ Jesu ọmọ mímọ́ rẹ.”


Ìṣe àwọn Aposteli 4:33
Àwọn aposteli ń fi ẹ̀rí wọn hàn pẹlu agbára ńlá nípa ajinde Jesu Oluwa. Gbogbo àwọn eniyan sì ń bọlá fún wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 5:30
Jesu tí ẹ̀yin pa, tí ẹ kàn mọ́ igi, Ọlọrun àwọn baba wa jí i dìde.


Ìṣe àwọn Aposteli 5:40
Wọ́n bá pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n nà wọ́n, wọ́n kìlọ̀ fún wọn pé wọn kò gbọdọ̀ fi orúkọ Jesu sọ̀rọ̀ mọ́. Wọ́n bá dá wọn sílẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 5:41
Wọ́n jáde kúrò níwájú ìgbìmọ̀, wọ́n ń yọ̀ nítorí a kà wọ́n yẹ kún àwọn tí a fi àbùkù kan nítorí orúkọ Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 5:42
Lojoojumọ, ninu Tẹmpili ati láti ilé dé ilé, wọn kò dẹ́kun láti máa kọ́ eniyan ati láti máa waasu pé Jesu ni Mesaya.


Ìṣe àwọn Aposteli 6:1
Nígbà tí ó yá, tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ sí i, ìkùnsínú bẹ̀rẹ̀ láàrin àwọn tí ó ń sọ èdè Giriki ati àwọn tí ó ń sọ èdè Heberu, nítorí wọ́n ń fojú fo àwọn opó àwọn tí ń sọ èdè Giriki dá, nígbà tí wọ́n bá ń pín àwọn nǹkan ní ojoojumọ.


Ìṣe àwọn Aposteli 6:2
Àwọn aposteli mejila bá pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yòókù jọ, wọ́n ní, “Kò yẹ kí á fi iṣẹ́ iwaasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílẹ̀, kí á máa ṣe ètò oúnjẹ.


Ìṣe àwọn Aposteli 6:7
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá ń gbilẹ̀. Iye àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn alufaa ni wọ́n sì di onigbagbọ.


Ìṣe àwọn Aposteli 6:14
Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.”


Ìṣe àwọn Aposteli 7:55
Ṣugbọn Ẹ̀mí Mímọ́ gbé Stefanu, ó tẹ ojú mọ́ òkè ọ̀run, ó rí ògo Ọlọrun, ó tún rí Jesu tí ó dúró lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọrun.


Ìṣe àwọn Aposteli 7:59
Bí wọ́n ti ń sọ òkúta lu Stefanu, ó ké pe Jesu Oluwa, ó ní, “Oluwa Jesu, gba ẹ̀mí mi.”


Ìṣe àwọn Aposteli 8:12
Ṣugbọn nígbà tí wọ́n gba ìyìn rere tí Filipi waasu nípa ìjọba Ọlọrun ati orúkọ Jesu Kristi gbọ́, tọkunrin tobinrin wọn ṣe ìrìbọmi.


Ìṣe àwọn Aposteli 8:16
nítorí Ẹ̀mí Mímọ́ kò ì tíì bà lé ẹnikẹ́ni ninu wọn. Ìrìbọmi ní orúkọ Oluwa Jesu nìkan ni wọ́n ṣe.


Ìṣe àwọn Aposteli 8:35
Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un.


Ìṣe àwọn Aposteli 8:37
Filipi sọ fún un pé, “Bí o bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ẹ̀tọ́ ni.” Ó dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi.”]


Ìṣe àwọn Aposteli 9:5
Saulu bèèrè pé, “Ta ni ọ́, Oluwa?” Ẹni náà bá dáhùn pé, “Èmi ni Jesu, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.


Ìṣe àwọn Aposteli 9:10
Ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan wà ní Damasku tí ń jẹ́ Anania. Oluwa pè é ní ojú ìran, ó ní, “Anania!” Anania bá dáhùn pé, “Èmi nìyí, Oluwa.”


Ìṣe àwọn Aposteli 9:17
Anania bá lọ, ó wọ inú ilé náà, ó fi ọwọ́ kan Saulu. Ó ní, “Saulu arakunrin mi, Oluwa ni ó rán mi sí ọ. Jesu tí ó farahàn ọ́ ní ojú ọ̀nà tí o gbà wá, ni ó rán mi wá, kí o lè tún ríran, kí o sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.”


Ìṣe àwọn Aposteli 9:19
Ó bá jẹun, ara rẹ̀ bá tún mókun. Ó wà pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu tí ó wà ní Damasku fún ọjọ́ díẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 9:20
Láì jáfara ó bẹ̀rẹ̀ sí waasu ninu ilé ìpàdé àwọn Juu pé Jesu ni Ọmọ Ọlọrun.


Ìṣe àwọn Aposteli 9:22
Ṣugbọn ńṣe ni Saulu túbọ̀ ń lágbára sí i. Àwọn Juu tí ó ń gbé Damasku kò mọ ohun tí wọ́n le wí mọ́, nítorí ó fi ẹ̀rí hàn pé Jesu ni Mesaya.


Ìṣe àwọn Aposteli 9:26
Nígbà tí Saulu dé Jerusalẹmu, ó fẹ́ darapọ̀ mọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ṣugbọn ẹ̀rù rẹ̀ ń bà wọ́n; wọn kò gbàgbọ́ pé ó ti di ọmọ-ẹ̀yìn Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 9:27
Ṣugbọn Banaba mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn aposteli, ó ròyìn fún wọn bí ó ti rí Oluwa lọ́nà, bí Oluwa ti bá a sọ̀rọ̀, ati bí ó ti fi ìgboyà waasu lórúkọ Jesu ní Damasku.


Ìṣe àwọn Aposteli 9:34
Peteru bá sọ fún un pé, “Iniasi, Jesu Kristi wò ọ́ sàn. Dìde, kà ẹní rẹ.” Lẹsẹkẹsẹ, ó bá dìde.


Ìṣe àwọn Aposteli 9:38
Lida kò jìnnà sí Jọpa, nítorí náà àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Jọpa ti gbọ́ pé Peteru wà ní Lida. Wọ́n bá rán ọkunrin meji lọ sibẹ, kí wọ́n lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má jáfara kí ó yára wá sọ́dọ̀ wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 10:36
Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan.


Ìṣe àwọn Aposteli 10:38
Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 10:42
Ó wá pàṣẹ fún wa láti waasu fún àwọn eniyan, kí á fi yé wọn pé Jesu yìí ni ẹni tí Ọlọrun ti yàn láti jẹ́ onídàájọ́ àwọn tí ó ti kú ati àwọn tí ó wà láàyè.


Ìṣe àwọn Aposteli 10:48
Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jesu Kristi. Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ díẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 11:17
Nítorí náà bí Ọlọrun bá fún wọn ní ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kan náà bí ó ti fún àwa tí a gba Oluwa Jesu Kristi gbọ́, tèmi ti jẹ́, tí n óo wá dí Ọlọrun lọ́nà?”


Ìṣe àwọn Aposteli 11:20
Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ninu àwọn ará Kipru ati Kirene dé Antioku, wọ́n bá àwọn ará Giriki sọ̀rọ̀, wọ́n ń waasu Oluwa Jesu fún wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 13:6
Wọ́n la erékùṣù náà kọjá, wọ́n dé Pafọsi. Níbẹ̀ ni wọ́n rí ọkunrin Juu kan, tí ó ń pidán, tí ó fi ń tú àwọn eniyan jẹ. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ba-Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 13:23
Láti inú ìran rẹ̀ ni Ọlọrun ti gbé Jesu dìde bí Olùgbàlà fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.


Ìṣe àwọn Aposteli 13:24
Kí Jesu tó yọjú, Johanu ti ń waasu fún gbogbo àwọn eniyan Israẹli pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi bí àmì pé wọ́n ronupiwada.


Ìṣe àwọn Aposteli 13:27
Àwọn tí ó ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn olóyè wọn, wọn kò mọ ẹni tí Jesu jẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ohun tí àwọn wolii ń sọ kò yé wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n ń kà á. Wọ́n mú àkọsílẹ̀ wọnyi ṣẹ nígbà tí wọ́n dá a lẹ́bi ikú.


Ìṣe àwọn Aposteli 13:32
A wá mú ìyìn rere wá fun yín pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa ti ṣẹ, fún àwọn ọmọ wa, nígbà tí ó jí Jesu dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Orin Dafidi keji pé, ‘Ọmọ mi ni ọ́, lónìí yìí ni mo bí ọ.’


Ìṣe àwọn Aposteli 13:52
Ayọ̀ kún ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sì kún inú wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 14:1
Nígbà tí wọ́n dé Ikoniomu, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn. Wọ́n sọ̀rọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ọpọlọpọ ninu àwọn Juu ati àwọn Giriki fi gba Jesu gbọ́.


Ìṣe àwọn Aposteli 14:2
Àwọn Juu tí kò gbà pé Jesu ni Mesaya wá gbin èrò burúkú sí ọkàn àwọn tí kì í ṣe Juu, wọ́n rú wọn sókè sí àwọn onigbagbọ.


Ìṣe àwọn Aposteli 15:7
Àríyànjiyàn pupọ ni ó bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn. Peteru bá dìde, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin, ẹ̀yin gan-an mọ̀ pé ní àtijọ́ Ọlọrun yàn mí láàrin yín pé láti ẹnu mi ni àwọn tí kì í ṣe Juu yóo ti gbọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere, kí wọ́n lè gba Jesu gbọ́.


Ìṣe àwọn Aposteli 15:9
Kò fi ìyàtọ̀ kankan sáàrin àwa ati àwọn; ó wẹ ọkàn wọn mọ́ nítorí wọ́n gba Jesu gbọ́.


Ìṣe àwọn Aposteli 15:11
A gbàgbọ́ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ Jesu Oluwa ni a fi gbà wá là, gẹ́gẹ́ bí a ti fi gba àwọn náà là.”


Ìṣe àwọn Aposteli 15:26
àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn lélẹ̀ nítorí orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi.


Ìṣe àwọn Aposteli 16:1
Paulu dé Dabe ati Listira. Onigbagbọ kan tí ń jẹ́ Timoti wà níbẹ̀. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Juu tí ó gba Jesu gbọ́; ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 16:7
Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 16:18
Ó ń ṣe báyìí fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí ara Paulu kò gbà á mọ́, ó yipada, ó sọ fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu, jáde kúrò ninu rẹ̀.” Ni ó bá jáde lẹ́sẹ̀ kan náà.


Ìṣe àwọn Aposteli 16:31
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.”


Ìṣe àwọn Aposteli 17:3
Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 17:7
Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!”


Ìṣe àwọn Aposteli 17:18
Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan ninu àwọn ọmọlẹ́yìn Epikurusi ati àwọn Sitoiki bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Kí ni aláhesọ yìí ń wí?” Àwọn mìíràn ní, “Ó jọ pé òjíṣẹ́ oriṣa àjèjì kan ni!” Nítorí ó ń waasu nípa Jesu ati ajinde.


Ìṣe àwọn Aposteli 18:5
Nígbà tí Sila ati Timoti dé láti Masedonia, Paulu wá fi gbogbo àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún iwaasu, ó ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu pé Jesu ni Mesaya.


Ìṣe àwọn Aposteli 18:23
Ó dúró níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. Ó bá tún kúrò, ó la agbègbè Galatia ati ti Firigia já, ó ń mú gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn le.


Ìṣe àwọn Aposteli 18:25
A ti fi ọ̀nà Oluwa kọ́ ọ, a máa sọ̀rọ̀ pẹlu ìtara; a sì máa kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jesu ní àkọ́yé. Ṣugbọn ìrìbọmi tí Johanu ṣe nìkan ni ó mọ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 18:27
Nígbà tí ó fẹ́ kọjá lọ sí Akaya, àwọn onigbagbọ ní Efesu fún un ní ìwúrí, wọ́n kọ ìwé sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Akaya pé kí wọ́n gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀. Nígbà tí Apolo dé Akaya, ó wúlò lọpọlọpọ fún àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nípa oore-ọ̀fẹ́ níbẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 18:28
Bí ó bá bá àwọn Juu jiyàn níwájú gbogbo àwùjọ, a máa borí wọn, kedere ni ó ń fihàn láti inú Ìwé Mímọ́ pé Jesu ni Mesaya.


Ìṣe àwọn Aposteli 19:1
Nígbà tí Apolo wà ní Kọrinti, Paulu gba ọ̀nà ilẹ̀ la àwọn ìlú tí ó wà ní àríwá Antioku kọjá títí ó fi dé Efesu. Ó rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu mélòó kan níbẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 19:2
Ó bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí ẹ gba Jesu gbọ́?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o! A kò tilẹ̀ gbọ́ ọ rí pé nǹkankan wà tí ń jẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.”


Ìṣe àwọn Aposteli 19:4
Paulu bá sọ pé, “Ìrìbọmi pé a ronupiwada ni Johanu ṣe. Ó ń sọ fún àwọn eniyan pé kí wọ́n gba ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́. Ẹni náà ni Jesu.”


Ìṣe àwọn Aposteli 19:5
Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbà fún Paulu, ó sì rì wọ́n bọmi lórúkọ Oluwa Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 19:9
Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ṣe agídí, tí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ burúkú sí ọ̀nà Oluwa níwájú gbogbo àwùjọ, Paulu yẹra kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó kó àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ sí gbọ̀ngàn Tirani, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ níbẹ̀ lojoojumọ.


Ìṣe àwọn Aposteli 19:13
Àwọn Juu kan tí wọ́n ti ń kiri láti ìlú dé ìlú, tí wọn ń lé ẹ̀mí burúkú jáde kúrò ninu àwọn eniyan, fẹ́ máa ṣe bíi Paulu nípa pípe orúkọ Oluwa Jesu lé àwọn tí ó ní ẹ̀mí burúkú lórí. Wọ́n á máa wí pé, “Mo pàṣẹ fun yín lórúkọ Jesu tí Paulu ń ròyìn nípa rẹ̀.”


Ìṣe àwọn Aposteli 19:15
Ẹni tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá bi wọ́n pé, “Mo mọ Jesu; mo sì mọ Paulu. Tiyín ti jẹ́?”


Ìṣe àwọn Aposteli 19:17
Gbogbo àwọn Juu ati àwọn Giriki tí ó ń gbé Efesu ni wọ́n gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ̀rù ba gbogbo wọn; wọ́n sì gbé orúkọ Jesu Oluwa ga.


Ìṣe àwọn Aposteli 19:30
Paulu fẹ́ wọ ibẹ̀ lọ bá àwọn èrò ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kò gbà fún un.


Ìṣe àwọn Aposteli 20:1
Nígbà tí rògbòdìyàn náà kásẹ̀, Paulu ranṣẹ pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Ó gbà wọ́n níyànjú, ó sì dágbére fún wọn, ó bá lọ sí Masedonia.


Ìṣe àwọn Aposteli 20:21
Mò ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu ati àwọn Giriki pé kí wọn yipada sí Ọlọrun, kí wọn ní igbagbọ ninu Oluwa Jesu.


Ìṣe àwọn Aposteli 20:24
Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.


Ìṣe àwọn Aposteli 20:30
Mo mọ̀ pé láàrin yín àwọn ẹlòmíràn yóo dìde tí wọn yóo fi irọ́ yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ́kàn pada láti tẹ̀lé wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 20:35
Mo ti fihàn yín pé bẹ́ẹ̀ ni a níláti ṣiṣẹ́ láti ran àwọn aláìlera lọ́wọ́. Kí á máa ranti àwọn ọ̀rọ̀ Oluwa Jesu, nítorí òun fúnra rẹ̀ sọ pé, ‘Ayọ̀ pọ̀ ninu kí a máa fúnni ní nǹkan ju kí á máa gbà lọ.’ ”


Ìṣe àwọn Aposteli 21:4
A bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan níbẹ̀, a bá dúró tì wọ́n níbẹ̀ fún ọjọ́ meje. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yìí sọ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn wọ́n fún Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu.


Ìṣe àwọn Aposteli 21:13
Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.”


Ìṣe àwọn Aposteli 21:16
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́.


Ìṣe àwọn Aposteli 21:20
Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n fi ògo fún Ọlọrun. Àwọn náà wá sọ fún un pé, “Wò ó ná, arakunrin, ṣé o mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn Juu tí ó gba Jesu gbọ́, tí gbogbo wọn sì ní ìtara sí Òfin Mose.


Ìṣe àwọn Aposteli 21:25
Ní ti àwọn tí kì í ṣe Juu tí wọ́n gba Jesu gbọ́, a ti kọ ìwé sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún oúnjẹ tí a ti fi rúbọ sí oriṣa, ati ẹ̀jẹ̀, ati ẹran tí a lọ́ lọ́rùn pa; kí wọn sì ṣọ́ra fún àgbèrè.”


Ìṣe àwọn Aposteli 22:4
Mo ṣe inúnibíni sí ọ̀nà ẹ̀sìn yìí. Gbogbo àwọn tí ń tẹ̀lé Jesu ni mò ń lé kiri: ẹni tí mo bá sì bá ninu wọn pípa ni. Èmi a mú wọn, èmi a dè wọ́n, wọn a sì sọ wọ́n sẹ́wọ̀n, atọkunrin atobinrin wọn.


Ìṣe àwọn Aposteli 22:8
Mo wá dáhùn, mo ní, ‘Ta ni ọ́, Oluwa?’ Ó bá sọ fún mi pé, ‘Èmi ni Jesu ará Nasarẹti, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí.’


Ìṣe àwọn Aposteli 24:24
Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀.


Ìṣe àwọn Aposteli 25:19
Àríyànjiyàn nípa ẹ̀sìn oriṣa wọn, ati nípa ẹnìkan tí ń jẹ́ Jesu ni ohun tí wọn ń jà sí. Jesu yìí ti kú, ṣugbọn Paulu ní ó wà láàyè.


Ìṣe àwọn Aposteli 26:9
“Nígbà kan rí èmi náà rò pé ó jẹ mí lógún láti tako orúkọ Jesu ará Nasarẹti. Kí ni n ò ṣe tán?


Ìṣe àwọn Aposteli 26:15
Mo wá bèèrè pé, ‘Ìwọ ta ni, Oluwa?’ Oluwa bá dáhùn ó ní, ‘Èmi ni Jesu tí ò ń ṣe inúnibíni sí.


Ìṣe àwọn Aposteli 28:23
Wọ́n bá dá ọjọ́ tí wọn yóo wá fún un. Nígbà tí ọjọ́ pé, pupọ ninu wọn wá kí i. Ó bá dá ọ̀rọ̀ sílẹ̀, ó ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn ṣe àlàyé ìjọba Ọlọrun fún wọn, ó sì ń fi ẹ̀rí tí ó wà ninu ìwé Òfin Mose ati ìwé wolii nípa Jesu hàn wọ́n láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.


Ìṣe àwọn Aposteli 28:31
Ó ń waasu ìjọba Ọlọrun. Ó ń kọ́ àwọn eniyan nípa Oluwa Jesu Kristi láì bẹ̀rù ohunkohun. Ẹnikẹ́ni kò sì dí i lọ́wọ́.


Romu 1:1
Èmi Paulu, iranṣẹ Kristi Jesu, ni mò ń kọ ìwé yìí. Ọlọrun pè mí, ó fi mí ṣe òjíṣẹ́, ó sì yà mí sọ́tọ̀ láti máa waasu ìyìn rere rẹ̀.


Romu 1:4
Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa,


Romu 1:5
nípa ẹni tí a ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà, tí a sì gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní orúkọ rẹ̀, pé kí gbogbo eniyan lè gba Jesu gbọ́, kí wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.


Romu 1:6
Ẹ̀yin tí mò ń kọ ìwé yìí sí náà wà lára àwọn tí Jesu Kristi pè.


Romu 1:7
Gbogbo ẹ̀yin àyànfẹ́ Ọlọrun tí ẹ wà ní Romu, ẹ̀yin tí a pè láti jẹ́ eniyan ọ̀tọ̀. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa ati Oluwa Jesu Kristi, kí ó wà pẹlu yín.


Romu 1:8
Kí á tó máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun mi nípasẹ̀ Jesu Kristi nítorí gbogbo yín; nítorí àwọn eniyan ń ròyìn igbagbọ yín ní gbogbo ayé.


Romu 1:16
Ojú kò tì mí láti waasu ìyìn rere Jesu, nítorí ìyìn rere yìí ni agbára Ọlọrun, tí a fi ń gba gbogbo àwọn tí ó bá gbà á gbọ́ là. Ó kọ́kọ́ lo agbára yìí láàrin àwọn Juu, lẹ́yìn náà ó lò ó láàrin àwọn Giriki.


Romu 2:16
ní ọjọ́ tí Ọlọrun yóo rán Jesu láti ṣe ìdájọ́ ohun ìkọ̀kọ̀ gbogbo tí ó wà ninu eniyan gẹ́gẹ́ bí ìyìn rere tí mò ń waasu.


Romu 3:22
Gbogbo àwọn tí ó bá gba Jesu gbọ́ yóo yege lọ́dọ̀ Ọlọrun láìsí ìyàtọ̀ kan.


Romu 3:24
Gbogbo wọn ni Ọlọrun ti ṣe lóore: ó dá wọn láre lọ́fẹ̀ẹ́ nípa ìràpadà tí Kristi Jesu ṣe.


Romu 3:25
Jesu yìí ni Ọlọrun fi ṣe ètùtù ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹni tí ó bá gbàgbọ́, nípa ikú rẹ̀. Èyí ni láti fi ọ̀nà tí Ọlọrun yóo fi dá eniyan láre hàn, nítorí pé ó fi ojú fo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àtijọ́ dá, nípa ìyọ́nú rẹ̀, kí ó lè fi òdodo rẹ̀ hàn ní àkókò yìí, kí ó lè hàn pé olódodo ni òun, ati pé òun ń dá ẹni tí ó bá gba Jesu gbọ́ láre.


Romu 4:24
A kọ ọ́ nítorí ti àwa náà tí a óo kà sí ẹni rere, gbogbo àwa tí a ní igbagbọ ninu ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde kúrò ninu òkú,


Romu 5:1
Níwọ̀n ìgbà tí a ti dá wa láre nítorí pé a gba Ọlọrun gbọ́, kò sí ìjà mọ́ láàrin àwa ati Ọlọrun: Jesu Kristi Oluwa wa ti parí ìjà.


Romu 5:11
Kì í ṣe bẹ́ẹ̀ nìkan, ṣugbọn à ń yọ̀ ninu Ọlọrun nítorí ohun tí ó ṣe nípa Oluwa wa Jesu Kristi, ẹni tí ó sọ wá di ọ̀rẹ́ Ọlọrun ní àkókò yìí.


Romu 5:15
Kì í ṣe bí eniyan ṣe rú òfin tó ni Ọlọrun fi ń wọn ìfẹ́ ati àánú rẹ̀. Bí gbogbo eniyan bá jogún ikú nítorí aṣemáṣe ẹnìkan, oore-ọ̀fẹ́ ati àánú tí Ọlọrun fún gbogbo eniyan láti ọwọ́ ẹnìkan, àní Jesu Kristi, ó pọ̀ pupọ; ó pọ̀ ju ogún ikú lọ.


Romu 5:17
Bí ikú bá torí òfin tí ẹnìkan rú jọba lé wa lórí, àwọn tí ó ti gba ibukun lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí wọ́n sì gba ìdáláre lọ́fẹ̀ẹ́, yóo ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ: wọn óo jọba, wọn óo sì yè pẹlu àṣẹ ẹnìkan, Jesu Kristi.


Romu 5:21
Nípa bẹ́ẹ̀, bí ikú ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ di ọba, bẹ́ẹ̀ ni ìdáláre náà ń fi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jọba, ó sì mú wa wọnú ìyè ainipẹkun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.


Romu 6:3
Àbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo àwa tí a ti rì bọmi lórúkọ Jesu a ti kú bí Jesu ti kú?


Romu 6:5
Bí a bá sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu Jesu ninu ikú, a óo sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu rẹ̀ ninu ajinde.


Romu 6:6
Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.


Romu 6:8
Bí a bá jọ bá Jesu kú, a ní igbagbọ pé a óo jọ bá Jesu yè.


Romu 6:23
Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa.


Romu 7:25
Háà! Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun! Òun nìkan ló lè gbà mí là nípa Jesu Kristi Oluwa wa. Bí ọ̀rọ̀ ara mi ti wá rí nìyí: ní ìdà kinni, mò ń tẹ̀lé ìlànà òfin Ọlọrun ninu àwọn èrò ọkàn mi: ní ìdà keji ẹ̀wẹ̀, èmi yìí kan náà, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran-ara, mo tún ń tọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀.


Romu 8:1
Nisinsinyii, kò sí ìdálẹ́bi kan mọ́ fún àwọn tí ó wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu.


Romu 8:11
Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Ọlọrun, ẹni tí ó jí Jesu dìde kúrò ninu òkú, bá ń gbé inú yín, òun náà tí ó jí Kristi dìde kúrò ninu òkú yóo sọ ara yín, tí yóo kú, di alààyè nípa Ẹ̀mí rẹ̀, tí ó ń gbé inú yín.


Romu 8:39
yálà àwọn àlùjọ̀nnú ojú-ọ̀run tabi àwọn ẹbọra inú ilẹ̀; lọ́rọ̀ kan, kò sí ẹ̀dá náà tí ó lè yà wá kúrò ninu ìfẹ́ tí Ọlọrun ní sí wa nípasẹ̀ Kristi Jesu Oluwa wa.


Romu 10:9
bí ìwọ bá fi ẹnu rẹ jẹ́wọ́ pé, “Jesu ni Oluwa,” tí o sì gbàgbọ́ lọ́kàn rẹ pé Ọlọrun jí i dìde kúrò ninu òkú, a óo gbà ọ́ là.


Romu 13:14
Ṣugbọn ẹ gbé Oluwa Jesu Kristi wọ̀ bí ihamọra. Ẹ má jẹ́ kí á máa gbèrò láti ṣe àwọn ohun tí ara fẹ́.


Romu 14:14
Mo mọ èyí, ó sì dá mi lójú nípa àṣẹ Oluwa Jesu pé kò sí ohunkohun tí ó jẹ́ èèwọ̀ ní jíjẹ fún ara rẹ̀. Ṣugbọn tí ẹnìkan bá ka nǹkan sí èèwọ̀, èèwọ̀ ni fún irú ẹni bẹ́ẹ̀.


Romu 14:15
Nítorí bí o bá mú ìdààmú bá arakunrin rẹ nípa ọ̀ràn oúnjẹ tí ò ń jẹ, a jẹ́ pé, kì í ṣe ìfẹ́ ni ń darí ìgbésí-ayé rẹ mọ́. Má jẹ́ kí oúnjẹ tí ò ń jẹ mú ìparun bá ẹni tí Jesu ti ìtorí rẹ̀ kú.


Romu 15:5
Kí Ọlọrun, tí ó ń fún wa ní ìrọ́jú ati ìwúrí, jẹ́ kí ẹ ní ọkàn kan náà sí ara yín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Kristi Jesu,


Romu 15:6
kí ẹ fi inú kan ati ohùn kan yin Ọlọrun ati Baba Oluwa Jesu Kristi.


Romu 15:16
láti jẹ́ iranṣẹ Kristi Jesu sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Mò ń ṣe iṣẹ́ alufaa láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nípa wiwaasu ìyìn rere Ọlọrun, kí wọ́n lè jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun, ọrẹ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà sí mímọ́.


Romu 15:17
Nítorí náà, mo ní ohun tí mo lè fi ṣògo ninu Kristi Jesu, ninu iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún Ọlọrun.


Romu 15:30
Ará, mo fi Oluwa wa Jesu Kristi ati ìfẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ bẹ̀ yín pé, kí ẹ máa fi ìtara bá mi gbadura sí Ọlọrun pé


Romu 16:3
Ẹ kí Pirisila ati Akuila, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi ninu iṣẹ́ Kristi Jesu.


Romu 16:20
Kí Ọlọrun orísun alaafia mu yín ṣẹgun Satani ní kíákíá. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu kí ó wà pẹlu yín.


Romu 16:24
Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin.]


Romu 16:25
Ògo ni fún ẹni tí ó lágbára láti mu yín dúró gbọningbọnin, gẹ́gẹ́ bí ìyìn