A A A A A
Yoruba Bible (BMY) 2014

Numeri 61
OLÚWA sọ fún Mósè pé:
2
“Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-ṣọ́tọ̀ sí OLÚWA nípa àìgé irun orí (Násírì):
3
Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èṣo àjàrà tútù tàbí gbígbẹ.
4
Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ Násírì, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èṣo àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀.
5
“ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí OLÚWA yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.
6
Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí OLÚWA kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn.
7
Ìbá à ṣe òkú baba, àti ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí àbúrò rẹ̀, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí wọn, nítorí pé àmì ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run wà ní orí rẹ̀.
8
Ní gbogbo àsìkò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA.
9
“ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje.
10
Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
11
Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà. Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an.
12
Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí OLÚWA fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.
13
“ ‘Èyí ni òfin fún Násírì nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé.
14
Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún OLÚWA, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọ̀rọ̀-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà,
15
pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò pọ̀ mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí.
16
“ ‘Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá ṣíwájú OLÚWA, yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun.
17
Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí OLÚWA, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.
18
“ ‘Nígbà náà ni Násírì náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé. Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà.
19
“ ‘Lẹ́yìn tí Násírì bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20
Àlùfáà yóò fí gbogbo rẹ̀ níwájú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú ìgẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyi, Násírì náà lè mu wáìnì.
21
“ ‘Èyí ni òfin Násírì tó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ rẹ̀ sí OLÚWA, yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Násírì, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tó lágbára láti mú wá. Ó gbọdọ̀ mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Násírì.’ ”
22
OLÚWA sọ fún Mósè pé,
23
“Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ sọ fún wọn pé:
24
“ ‘ “Kí OLÚWA bùkún un yín Kí ó sì pa yín mọ́.
25
Kí OLÚWA kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
26
Kí OLÚWA bojú wò yín; Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’
27
“Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Èmi ó sì bùkún wọn.”Numeri 6:1

Numeri 6:2

Numeri 6:3

Numeri 6:4

Numeri 6:5

Numeri 6:6

Numeri 6:7

Numeri 6:8

Numeri 6:9

Numeri 6:10

Numeri 6:11

Numeri 6:12

Numeri 6:13

Numeri 6:14

Numeri 6:15

Numeri 6:16

Numeri 6:17

Numeri 6:18

Numeri 6:19

Numeri 6:20

Numeri 6:21

Numeri 6:22

Numeri 6:23

Numeri 6:24

Numeri 6:25

Numeri 6:26

Numeri 6:27Numeri 1 / Num 1

Numeri 2 / Num 2

Numeri 3 / Num 3

Numeri 4 / Num 4

Numeri 5 / Num 5

Numeri 6 / Num 6

Numeri 7 / Num 7

Numeri 8 / Num 8

Numeri 9 / Num 9

Numeri 10 / Num 10

Numeri 11 / Num 11

Numeri 12 / Num 12

Numeri 13 / Num 13

Numeri 14 / Num 14

Numeri 15 / Num 15

Numeri 16 / Num 16

Numeri 17 / Num 17

Numeri 18 / Num 18

Numeri 19 / Num 19

Numeri 20 / Num 20

Numeri 21 / Num 21

Numeri 22 / Num 22

Numeri 23 / Num 23

Numeri 24 / Num 24

Numeri 25 / Num 25

Numeri 26 / Num 26

Numeri 27 / Num 27

Numeri 28 / Num 28

Numeri 29 / Num 29

Numeri 30 / Num 30

Numeri 31 / Num 31

Numeri 32 / Num 32

Numeri 33 / Num 33

Numeri 34 / Num 34

Numeri 35 / Num 35

Numeri 36 / Num 36