A A A A A
Facebook Instagram Twitter
Yoruba Bible (BMY) 2014

Numeri 51
OLÚWA sọ fún Mósè pé:
2
“Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.
3
Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má báà ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrin wọn”
4
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ fún Mósè.
5
OLÚWA sọ fún Mósè pé:
6
“Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìsòótọ́ sí OLÚWA, ẹni náà jẹ̀bi.
7
Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn ún rẹ̀ lée, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀.
8
Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó sún mọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti OLÚWA, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà
9
Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀.
10
Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti oun nikan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”
11
OLÚWA sọ fún Mósè wí pé,
12
“Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìsòótọ́ sí i,
13
Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lò pọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà).
14
Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ débi pé ó ń furà sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́,
15
nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n éfà ìyẹ̀fun bálì. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.
16
“ ‘Àlùfáà yóò sì mú-un wá ṣíwájú OLÚWA.
17
Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀,
18
Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú OLÚWA yóò sì tú irun orí obìnrin náà lée lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.
19
Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní se ọ́ níbi.
20
Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í se ọkọ rẹ bá ọ lò pọ̀,”
21
nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí OLÚWA sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrin àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ sì wú.
22
Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹra dànù.” “ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”
23
“ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé, yóò sì sìn ín sínú omi kíkoro náà.
24
Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi.
25
Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í ṣíwájú OLÚWA, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ.
26
Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi.
27
Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì se àìsòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
28
Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.
29
“ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe aṣemá ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́
30
Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó fura sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú OLÚWA yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un.
31
Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’ ”Numeri 5:1

Numeri 5:2

Numeri 5:3

Numeri 5:4

Numeri 5:5

Numeri 5:6

Numeri 5:7

Numeri 5:8

Numeri 5:9

Numeri 5:10

Numeri 5:11

Numeri 5:12

Numeri 5:13

Numeri 5:14

Numeri 5:15

Numeri 5:16

Numeri 5:17

Numeri 5:18

Numeri 5:19

Numeri 5:20

Numeri 5:21

Numeri 5:22

Numeri 5:23

Numeri 5:24

Numeri 5:25

Numeri 5:26

Numeri 5:27

Numeri 5:28

Numeri 5:29

Numeri 5:30

Numeri 5:31Numeri 1 / Num 1

Numeri 2 / Num 2

Numeri 3 / Num 3

Numeri 4 / Num 4

Numeri 5 / Num 5

Numeri 6 / Num 6

Numeri 7 / Num 7

Numeri 8 / Num 8

Numeri 9 / Num 9

Numeri 10 / Num 10

Numeri 11 / Num 11

Numeri 12 / Num 12

Numeri 13 / Num 13

Numeri 14 / Num 14

Numeri 15 / Num 15

Numeri 16 / Num 16

Numeri 17 / Num 17

Numeri 18 / Num 18

Numeri 19 / Num 19

Numeri 20 / Num 20

Numeri 21 / Num 21

Numeri 22 / Num 22

Numeri 23 / Num 23

Numeri 24 / Num 24

Numeri 25 / Num 25

Numeri 26 / Num 26

Numeri 27 / Num 27

Numeri 28 / Num 28

Numeri 29 / Num 29

Numeri 30 / Num 30

Numeri 31 / Num 31

Numeri 32 / Num 32

Numeri 33 / Num 33

Numeri 34 / Num 34

Numeri 35 / Num 35

Numeri 36 / Num 36