A A A A A
Facebook Instagram Twitter
Yoruba Bible (BMY) 2014

Òwe 111
OLÚWA kórìíra òṣùwọ̀n èké ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.
2
Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.
3
Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìsòótọ́ wọn.
4
Ọ̀rọ̀ kò níláárí ní ọjọ́ ìbínú ṣùgbọ́n òdodo a máa gba ni lọ́wọ́ ikú.
5
Òdodo aláìlẹ́gàn ṣe ọ̀nà tààrà fún wọn ṣùgbọ́n ìwà búburú ènìyàn búburú yóò fàá lulẹ̀.
6
Òdodo ẹni ìdúró ṣinṣin gbà wọ́n là ṣùgbọ́n ìdẹkùn ètè búburú mú aláìsòótọ́.
7
Nígbà tí ènìyàn búburú bá kú, ìrètí rẹ̀ a parun gbogbo ohun tó ń fojú sọ́nà fún nípa agbára rẹ̀ já sófo.
8
A gba olódodo kúrò lọ́wọ́ ibi dípò o rẹ̀, ibi wá sórí ènìyàn búburú.
9
Aláìmọ̀ Ọlọ́run fi ẹnu rẹ̀ ba aládùúgbò rẹ̀ jẹ́, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìmọ̀ Olódodo sá àsálà.
10
Nígbà tí Olódodo ń gbèrú, ìlú a yọ̀ nígbà tí ènìyàn búburú parun, ariwo ayọ̀ gba ìlú kan.
11
Nípaṣẹ̀ ìbùkún, Olódodo a gbé ìlú ga: ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ẹnu ènìyàn búburú, a pa ìlú run.
12
Ẹni tí kò gbọ́n fojú kékeré wo aládùúgbò rẹ̀ ṣùgbọ́n ẹni tí ó ní òye pa ẹnu rẹ̀ mọ́.
13
Olófòófó tú àsírí ìkọ̀kọ̀ ṣùgbọ́n ẹni tó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé a pa àsírí mọ́.
14
Nítorí àìní ìtọ́sọ́nà orílẹ̀ èdè ṣubú ṣùgbọ́n nípaṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ olùbádámọ̀ràn ìṣẹ́gun dájú.
15
Ẹni tí ó ṣe onídùúró fún ẹlòmíràn yóò jìyà dájúdájú, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó kọ̀ láti ṣe onídùúró yóò wà láì léwu.
16
Obìnrin oníwà rere gba ìyìn ṣùgbọ́n alágbára aláìbìkítà ènìyàn gba ọrọ̀ nìkan.
17
Ènìyàn rere ń ṣe ara rẹ̀ lóore ṣùgbọ́n ènìyàn ìkà ń mú ìyọnu wá sórí ara rẹ̀.
18
Ènìyàn búburú gba èrè ìtànjẹ ṣùgbọ́n ẹni tó fúrúgbìn òdodo yóò gba èrè tó dájú.
19
Olódodo tòótọ́ rí ìyè ṣùgbọ́n ẹni tí ń lépa ibi lé e sí ibi ikú ara rẹ̀.
20
OLÚWA kórìíra àwọn ènìyàn ọlọ́kàn búburú ṣùgbọ́n ó ní inú dídùn sí àwọn tí ọ̀nà wọn kò lábùkù.
21
Mọ èyí dájú pé: ènìyàn búburú kì yóò lọ láì jìyà, ṣùgbọ́n àwọn Olódodo yóò lọ láì jìyà.
22
Bí òrùka wúrà ní imú ẹlẹ́dẹ̀ ni arẹwà obìnrin tí kò lọ́gbọ́n.
23
Ìfẹ́ inú Olódodo yóò yọrí sí ohun rere ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn búburú yóò yọrí sí ìbínú.
24
Ènìyàn kan ń fún ni lọ́fẹ̀ ẹ́, síbẹ̀ ó ń ní sí i; òmíràn ń háwọ́ ju bí ó ti yẹ ṣùgbọ́n ó di aláìní.
25
Ẹni tí ń ṣoore yóò máa gbèrú sí i; ẹni tí ó tu ẹlòmíràn lára yóò ní ìtura.
26
Àwọn ènìyàn a ṣépè lé ènìyàn tí ń kó oúnjẹ pamọ́ ṣùgbọ́n ìbùkún a máa wá sórí ẹni tí ó ṣetán láti tà.
27
Ẹni tí ń lépa ohun rere yóò rí ohun rere ṣùgbọ́n ibi yóò dé bá ẹni tí ń lépa ibi.
28
Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ rẹ̀ yóò ṣubú; ṣùgbọ́n Olódodo yóò gbilẹ̀ bí i koríko tútù.
29
Ẹni tí ó ń mú ìdàámú dé bá ìdílé rẹ̀ yóò jogún afẹ́fẹ́ lásán aláìgbọ́n yóò sì máa ṣe ìránṣẹ́ fún Ọlọgbọ́n.
30
Èṣo òdodo ni igi ìyè ẹni tí ó sì jèrè ọkàn jẹ́ Ọlọgbọ́n.
31
Bí àwọn Olódodo bá gba ìpín wọn lórí ilẹ̀ ayé mélòó mélòó ni aláìwà bí Ọlọ́run àti ẹlẹ́ṣẹ̀.Òwe 11:1

Òwe 11:2

Òwe 11:3

Òwe 11:4

Òwe 11:5

Òwe 11:6

Òwe 11:7

Òwe 11:8

Òwe 11:9

Òwe 11:10

Òwe 11:11

Òwe 11:12

Òwe 11:13

Òwe 11:14

Òwe 11:15

Òwe 11:16

Òwe 11:17

Òwe 11:18

Òwe 11:19

Òwe 11:20

Òwe 11:21

Òwe 11:22

Òwe 11:23

Òwe 11:24

Òwe 11:25

Òwe 11:26

Òwe 11:27

Òwe 11:28

Òwe 11:29

Òwe 11:30

Òwe 11:31Òwe 1 / Òwe 1

Òwe 2 / Òwe 2

Òwe 3 / Òwe 3

Òwe 4 / Òwe 4

Òwe 5 / Òwe 5

Òwe 6 / Òwe 6

Òwe 7 / Òwe 7

Òwe 8 / Òwe 8

Òwe 9 / Òwe 9

Òwe 10 / Òwe 10

Òwe 11 / Òwe 11

Òwe 12 / Òwe 12

Òwe 13 / Òwe 13

Òwe 14 / Òwe 14

Òwe 15 / Òwe 15

Òwe 16 / Òwe 16

Òwe 17 / Òwe 17

Òwe 18 / Òwe 18

Òwe 19 / Òwe 19

Òwe 20 / Òwe 20

Òwe 21 / Òwe 21

Òwe 22 / Òwe 22

Òwe 23 / Òwe 23

Òwe 24 / Òwe 24

Òwe 25 / Òwe 25

Òwe 26 / Òwe 26

Òwe 27 / Òwe 27

Òwe 28 / Òwe 28

Òwe 29 / Òwe 29

Òwe 30 / Òwe 30

Òwe 31 / Òwe 31