A A A A A
Facebook Instagram Twitter
Yoruba Bible (BMY) 2014

Òwe 101
Àwọn òwe Sólómónì: Ọlọgbọ́n ọmọ ń mú inú baba rẹ̀ dùn ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ọmọ ń ba inú ìyá rẹ̀ jẹ́.
2
Ìṣúra tí a kójọ nípa ìwà búburú kò ní èrè ṣùgbọ́n òdodo a máa gbani lọ́wọ́ ikú.
3
OLÚWA kì í jẹ́ kí ebi máa pa Olódodo ṣùgbọ́n ó ba ète àwọn ènìyàn búburú jẹ́.
4
Ọwọ́ tí ó lẹ máa ń sọ ènìyàn di talákà, ṣùgbọ́n ọwọ́ tí ó múra síṣẹ́ a máa sọni di ọlọ́rọ̀.
5
Ẹni tí ó kó irúgbìn jọ ní àsìkò òjò jẹ́ Ọlọ́gbọ́n ọmọ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó sùn ní àsìkò ìkórè jẹ́ adójútini ọmọ.
6
Ìbùkún ní ó máa ń kún orí Olódodo ṣùgbọ́n ìwà ipá máa ń kún ẹnu ènìyàn búburú.
7
Ìrántí Olódodo yóò jẹ́ ìbùkún ṣùgbọ́n orúkọ ènìyàn búburú yóò jẹrà.
8
Ẹni tí ó gbọ́n nínú ọkàn rẹ̀ máa ń gba àṣẹ ṣùgbọ́n ètè wérewère yóò parun.
9
Ẹni oníwà títọ́ ń rìn láìléwu ṣùgbọ́n àsírí ẹni tí ń rin ọ̀nà pálapàla yóò tú.
10
Ẹni tí ń sẹ́jú pàkòpàkò fún ibi ń fa àìbalẹ̀ ọkàn Aláìgbọ́n tí ń ṣàròyé kiri yóò parun.
11
Ẹnu Olódodo jẹ́ oríṣun ìyè ṣùgbọ́n ìwà ipá ni ó gba gbogbo ẹnu ènìyàn búburú.
12
Ìríra a máa dá ìjà sílẹ̀, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo àṣìṣe mọ́lẹ̀.
13
Ọgbọ́n ni a ń bá lẹ́nu àwọn olóye ṣùgbọ́n kùmọ wà fún ẹ̀yìn àwọn aláìlóye.
14
Ọlọ́gbọ́n ènìyàn kó ìmọ̀ jọ ṣùgbọ́n ẹnu aláìgbọ́n a máa ṣokùnfà ìparun.
15
Ọrọ̀ àwọn Olódodo ni ìlú olódi wọn, ṣùgbọ́n òsì ni ìparun aláìní.
16
Èrè Olódodo ń mú ìyè wá fún wọn ṣùgbọ́n èrè ènìyàn búburú ń mú ìjìyà wá fún wọn.
17
Ẹni tí ó gbọ́ ìbáwí fi ọ̀nà sí ìyè hàn ṣùgbọ́n ẹni tí ó kọ ìbáwí mú àwọn mìíràn sìnà.
18
Ẹni tí ó pa ìkórìíra rẹ̀ mọ́ jẹ́ òpùrọ́ ẹni tí ó sì ń báni jẹ́ jẹ́ aláìgbọ́n.
19
Nínú ọ̀rọ̀ púpọ̀ a kò le fẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kù ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ẹnu rẹ̀ mọ́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n.
20
Ètè Olódodo jẹ́ àṣàyan fàdákà ṣùgbọ́n ọkàn ènìyàn buburú kò níye lórí.
21
Ètè Olódodo ń bọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣùgbọ́n aláìgbọ́n ń kú nítorí àìlóye.
22
Ìbùkún OLÚWA ń mú ọrọ̀ wá, kì í sìí fi ìdàámú sí i.
23
Aláìgbọ́n a máa ní inú dídùn sí ìwà búburú ṣùgbọ́n olóye ènìyàn a máa ní inú dídùn sí ọgbọ́n.
24
Ohun tí ènìyàn búburú bẹ̀rù yóò dé bá a; Olódodo yóò rí ohun tí ó fẹ́ gbà.
25
Nígbà tí ìjì bá ti jà kọjá, ènìyàn búburú a kọjá lọ, ṣùgbọ́n Olódodo yóò dúró ṣinṣin láéláé.
26
Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.
27
Ìbẹ̀rù OLÚWA ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá, ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.
28
Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.
29
Ọ̀nà OLÚWA jẹ́ ààbò fún Olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.
30
A kì yóò fa Olódodo tu láéláé ṣùgbọ́n ènìyàn buburú kì yóò dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
31
Ẹnu Olódodo ń mú ọgbọ́n jáde wá, ṣùgbọ́n ètè àyípadà ni a ó gé kúrò.
32
Ètè Olódodo mọ ohun tí ó tọ́, ṣùgbọ́n ètè ènìyàn búburú kò mọ̀ ju èké lọ.Òwe 10:1

Òwe 10:2

Òwe 10:3

Òwe 10:4

Òwe 10:5

Òwe 10:6

Òwe 10:7

Òwe 10:8

Òwe 10:9

Òwe 10:10

Òwe 10:11

Òwe 10:12

Òwe 10:13

Òwe 10:14

Òwe 10:15

Òwe 10:16

Òwe 10:17

Òwe 10:18

Òwe 10:19

Òwe 10:20

Òwe 10:21

Òwe 10:22

Òwe 10:23

Òwe 10:24

Òwe 10:25

Òwe 10:26

Òwe 10:27

Òwe 10:28

Òwe 10:29

Òwe 10:30

Òwe 10:31

Òwe 10:32Òwe 1 / Òwe 1

Òwe 2 / Òwe 2

Òwe 3 / Òwe 3

Òwe 4 / Òwe 4

Òwe 5 / Òwe 5

Òwe 6 / Òwe 6

Òwe 7 / Òwe 7

Òwe 8 / Òwe 8

Òwe 9 / Òwe 9

Òwe 10 / Òwe 10

Òwe 11 / Òwe 11

Òwe 12 / Òwe 12

Òwe 13 / Òwe 13

Òwe 14 / Òwe 14

Òwe 15 / Òwe 15

Òwe 16 / Òwe 16

Òwe 17 / Òwe 17

Òwe 18 / Òwe 18

Òwe 19 / Òwe 19

Òwe 20 / Òwe 20

Òwe 21 / Òwe 21

Òwe 22 / Òwe 22

Òwe 23 / Òwe 23

Òwe 24 / Òwe 24

Òwe 25 / Òwe 25

Òwe 26 / Òwe 26

Òwe 27 / Òwe 27

Òwe 28 / Òwe 28

Òwe 29 / Òwe 29

Òwe 30 / Òwe 30

Òwe 31 / Òwe 31