1 |
Ìran Jésù Kírísítì, ẹni tí í ṣe ọmọ Dáfídì, ọmọ Ábúráhámù: |
2 |
Ábúráhámù ni baba Ísáákì; Ísáákì ni baba Jákọ́bù; Jákọ́bù ni baba Júdà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, |
3 |
Júdà ni baba Pérésì àti Ṣérà, Támárì sì ni ìyá rẹ̀, Pérésì ni baba Ésírónù: Ésírónù ni baba Rámù; |
Yoruba Bible (BMY) 2014 |
|
1 |
Èyí ni àkọsílẹ̀ ìran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi, ọmọ Abrahamu. |
2 |
Abrahamu bí Isaaki, Isaaki bí Jakọbu, Jakọbu bí Juda ati àwọn arakunrin rẹ̀. |
3 |
Juda bí Peresi ati Sera, ìyá wọn ni Tamari. Peresi bí Hesironi, Hesironi bí Ramu. |
Yoruba Bible (BM) 2010 |
|
1 |
IWE iran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu. |
2 |
Abrahamu bí Isaaki; Isaaki si bí Jakọbu; Jakọbu si bí Juda ati awọn arakunrin rẹ̀; |
3 |
Juda si bí Faresi ati Sara ti Tamari; Faresi si bí Esromu; Esromu si bí Aramu; |
Yoruba Bible |
|