A A A A A
Bible in one year
April 19

Onidajọ 3:1-31
1. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí OLÚWA fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran túntún ní Ísírẹ́lì wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun, àwọn ará Kénánì.
2. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Ísírẹ́lì tí kò rí ogun rí ní bí a ti ṣe ń jagun):
3. Àwọn ìjòyè ìlú Fílístínì máràrùn, gbogbo àwọn ará Kénánì, àwọn ará Ṣídónì, àti àwọn ará Hífì tí ń gbé ní àwọn òkè Lébálónì bẹ̀rẹ̀ láti òkè Báálì-Aámónì títí dé Lébò Hámátì.
4. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Ísírẹ́lì wò bóyá wọn yóò gbọ́ran sí àwọn òfin OLÚWA, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipaṣẹ̀ Móṣè.
5. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé láàárin àwọn ará Kénánì, àwọn ará Hítì àwọn ará Ámórì, àwọn ará Pérísì, àwọn ará Hífítì àti àwọn ará Jébúsì.
6. Dípò kí wọ́n run àwọn ènìyàn wọ̀nyí, Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọbìnrin Ísírẹ́lì fún àwọn ará ilẹ̀ náà ní aya, wọ́n sì ń sin àwọn òrìṣà wọn.
7. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe èyí tí ó burú níwájú OLÚWA. Wọ́n gbàgbé OLÚWA Ọlọ́run wọn, wọ́n sì ń sin Báálímù àti Áṣérótù.
8. Ìbínú OLÚWA sì ru sí Ísírẹ́lì tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi jẹ́ kí Kúṣánì Rísíkítaímù ọba Árámù-Náháráímù (ìlà oòrùn Síríà) bá wọn jà kí ó sì ṣẹ́gun wọn, Ísírẹ́lì sì ṣe ẹrú rẹ̀ fún ọdún mẹ́jọ.
9. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì kígbe sí OLÚWA, Òun gbé olùgbàlà kan dìde fún wọn, ẹni náà ni Ótíníẹ́lì ọmọ Kénánì àbúrò Kálẹ́bù tí ó jẹ́ ọkùnrin, ẹni tí ó gbà wọ́n sílẹ̀.
10. Ẹ̀mí OLÚWA bà lé e, ó sì di onídàájọ́ (aṣíwájú) Ísírẹ́lì ó sì ṣíwájú wọn lọ sí ogun. OLÚWA sì fi Kúṣánì-Ríṣátaímù lé Ótíníẹ́lì lọ́wọ́ ó sì ṣẹ́gun rẹ̀.
11. Ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún títí tí Ótíníẹ́lì fi kú.
12. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì tún padà sí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n sì ṣe èyí tí ó burú ní iwájú OLÚWA, fún ìdí iṣẹ́ búburú yìí. OLÚWA fún Égílónì, ọba àwọn Móábù ní agbára ní orí Ísírẹ́lì.
13. Pẹ̀lú ìfi ọwọ́ ṣowọ́pọ̀ ogun àwọn Ámórì àti àwọn ọmọ ogun Ámálékì ní Égílónì gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì gba ìlú Ọ̀pẹ (Jẹ́ríkò).
14. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì sin Égílónì ọba Móábù fún ọdún méjìdínlógún
15. Ṣùgbọ́n nígbà tí Ísírẹ́lì tún ké pe OLÚWA, OLÚWA rán olùgbàlà sí wọn, Éhúdù ẹni tí ń lo ọwọ́ òsì, ọmọ Gérà ti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì. Éhúdù ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń fi owó orí wọn rán sí Égílónì olú ìlú Móábù ní ọdọọdún fún ọdún mẹ́rìndínlógún.
16. Ṣùgbọ́n kí ó tó lọ ní ọdún yìí Éhúdù ti ṣe idà mímú olójú méjì kan tí gígùn rẹ̀ fẹ́ ẹ̀ tó ẹṣẹ̀ kan ààbọ̀, ó sì fi pamọ́ sínú àwọn aṣọ rẹ̀ tí ó so mọ́ itan rẹ̀ ọ̀tún.
17. Éhúdù gbé owó orí náà lọ bí ó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ ó sì fi fún Égílónì ẹni tí ó sanra púpọ̀.
18. Lẹ́yìn tí ó ti fi ẹ̀bùn náà fún ọba tan, ó rán àwọn tí ó kó ẹrú náà wá lọ sí ọ̀nà wọn.
19. Ṣùgbọ́n ní ẹ̀yìn odi ìlú níbi tí wọ́n ti gbẹ́ òkúta, òun padà ṣẹ́yìn, ó sì wí fún ọba pé, “Mo ní ọ̀rọ̀ àsírí láti bá ọ sọ.” Ọba sì wí pé “Ẹ dákẹ́!” Gbogbo àwọn tí ń sọ sì jáde síta kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
20. Éhúdù lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ níbi tí ó ti jókòó ní iyàrá ìtura rẹ̀, Éhúdù sì wí fún-un pé: “Mo ní ọ̀rọ̀ kan fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” Bí ọba sì ti dìde ní orí ìtẹ́ rẹ̀,
21. Éhúdù fi ọwọ́ òsì rẹ̀ yọ idà láti ibi itan ọ̀tún rẹ̀ ó sì fi gún ọba nínú ikùn rẹ̀.
22. Àti idà àti èèkù rẹ̀ sì wọlé ó sì yọ ní ẹ̀yìn rẹ̀. Éhúdù kò yọ idà náà, ọ̀rá sì bo idà náà.
23. Éhúdù ti àwọn ìlẹ̀kùn ní àtì-sínú òun sì bá yàrá òkè jáde, ó sì sálọ.
24. Lẹ́yìn tí ó ti lọ àwọn ìránṣẹ́ ọba dé, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n rí ilẹ̀kùn yàrá òkè ní títì, wọ́n rò pé, “Bóyá ó wà ní ilé ìyàgbẹ́ ní yàrá nínú ilé.”
25. Nígbà tí wọ́n dúró dé ibi pé ó jẹ́ ìyànu fún wọn, wọ́n mú kọ́kọ́rọ́, wọ́n sì sí ilẹ̀kùn. Níbẹ̀ ni wọ́n ti rí Olúwa wọn tí ó ti ṣubú, ó sì ti kú.
26. Nígbà tí wọ́n dúró tí wọn sì ń retí, Éhúdù ti sálọ. Ó ti gba ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́ òkúta lére, ó sì sálọ sí Ṣéírà.
27. Nígbà tí ó dé ibẹ̀ ó fọn fèrè ní orí òkè Éfúráímù, fèrè ìpè ogun, ó sì kó ogun jọ lábẹ́ ara rẹ̀ bí olórí ogun.
28. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa tẹ̀lé mi, nítorí OLÚWA ti fi Móábù ọ̀ta yín lé yín lọ́wọ́.” Wọ́n sì tẹ̀lé e, wọ́n sì gba ìwọdò Jọ́dánì tí ó lọ sí ilẹ̀ Móábù, wọn ò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kọjá.
29. Ní báyìí, wọ́n ti pa tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ará Móábù tí wọ́n jẹ́ alágbára àti onígboyà ènìyàn, kò sí ènìyàn tí ó sálà.
30. Ní ọjọ́ náà ni Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ará Móábù, ilẹ̀ náà sì wà ní àlàáfíà fún ọgọ́rin ọdún.
31. Lẹ́yìn Éhúdù, ni ṣáḿgárì ọmọ Ánátì ẹni tí ó pa ọgọ́rùn ún mẹ́fà Fílístínì pẹ̀lú ọ̀pá tí a fi ń da akọ màlúù, òun pẹ̀lú sì gba Ísírẹ́lì kúrò nínú ìpọ́njú.

Onidajọ 4:1-24
1. Lẹ́yìn ikú Éhúdù, àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì tún ṣẹ̀, wọ́n ṣe ohun tí ó burú ní ojú OLÚWA.
2. Nítorí náà OLÚWA jẹ́kí Jábínì, ọba àwọn Kénánì, ẹni tí ó jọba ní Haṣórì, ṣẹ́gun wọn. Orúkọ olórí ogun rẹ̀ ni Ṣísérà ẹni tí ń gbé Hároṣeti-Hágóyímù.
3. Nítorí tí ó ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (900) kẹ̀kẹ́ ogun irin, ó sì ń pọ́n Ísírẹ́lì lójú gidigidi fún ogún ọdún. Ísírẹ́lì ké pe OLÚWA fún ìrànlọ́wọ́.
4. Dèbórà, wòlíì-obìnrin, aya Lápídótì ni olórí àti asíwájú àwọn ará Ísírẹ́lì ní àsìkò náà.
5. Òun a máa jókòó ṣe ìdájọ́ ní abẹ́ igi ọ̀pẹ tí a ṣọ orúkọ rẹ̀ ní ọ̀pẹ Dèbórà láàárin Rámà àti Bẹ́tẹ́lì ní ilẹ̀ òkè Éfúráímù, àwọn ará Ísírẹ́lì a sì máa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti yanjú èdè àìyedè tí wọ́n bá ní sí ara wọn, tàbí láti gbọ́ ohùn OLÚWA láti ẹnu rẹ̀.
6. Ní ọjọ́ kan, ó ránṣẹ́ pe Bárákì ọmọ Ábínóámù ẹni tí ń gbé ní Kádésì ní ilẹ̀ Náfítalì, ó sì wí fún-un pé OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì pa á ní àṣẹ fún-un pé kí ó kó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá àwọn akọni ọkùnrin jọ láti ẹ̀yà Náfítalì àti ẹ̀yà Ṣébúlúnì bí ẹgbẹ́ ogun, kí o sì ṣíwájú wọn lọ sí òkè Tábórì.
7. Èmi yóò sì fa Sísérà olórí ogun Jábínì, pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun rẹ àti àwọn ogun rẹ, sí odò Kíṣónì èmi yóò sì fi lé ọ lọ́wọ́ ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn níbẹ̀.
8. Bárákì sì dá a lóhùn pé, “Èmi yóò lọ tí ìwọ ó bá bá mi lọ, ṣùgbọ́n tí ìwọ kì yóò bá bá mi lọ, èmi kì yóò lọ.”
9. Dèbórà dá a lóhùn pé, “ó dára, èmi yóò bá ọ lọ ṣùgbọ́n ọlá ìṣẹ́gun tí o ń lọ yìí kò ní jẹ́ tìrẹ, nítorí OLÚWA yóò fi Sísérà lé obìnrin lọ́wọ́” Báyìí Dèbórà bá Bárákì lọ sí Kédésì.
10. Nígbà tí Bárákì pe ẹ̀yà ṣébúlúnì àti ẹ̀yà Náfítalì sí Kédésì ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá akíkanjú ọkùnrin ogun tẹ̀lé e, Dèbórà pẹ̀lú bá wọn lọ.
11. Ní àsìkò yìí Hébérì, ọ̀kan nínú ẹ̀yà Kẹ́nì, ti ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Kénì, òun sì ń gbé ibòmíràn títí dé ibi igi óákù Ṣánanímù, tí ó wà ni agbégbé Kédésì (àwọn ẹ̀yà Kénì jẹ́ ìran Hóbábù ẹni tí i ṣe àna Móṣè).
12. Nígbà tí a sọ fún Ṣísérà pé Bárákì ọmọ Ábínóámù ti kó ogun jọ sí òkè Tábósì,
13. Ṣísérà kó gbogbo kẹ̀kẹ́ ogun irin rẹ̀ tí ṣe ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀run (900) àti gbogbo àwọn ènìyàn (ọmọ ogun) tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, láti Háróṣétì tí àwọn orílẹ̀ èdè wá sí ọ̀dọ̀ Kíṣónì.
14. Dèbórà sì wí fún Bárákì pé, “Lọ! Lónìí ni OLÚWA fi Ṣísérà lé ọ lọ́wọ́, OLÚWA ti lọ ṣíwájú rẹ.” Bárákì sì ṣíwájú, àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì tẹ̀le e lẹ́yìn, wọ́n sì kọjá sí òkè Tábórì.
15. OLÚWA sì mú ìdàrúdàpọ̀ wá sí àárin ogun Sísérà, OLÚWA sì fi ojú idà ṣẹ́gun Sísérà àti àwọn oníkẹ̀kẹ́ ogun àti ọmọ ogun orí ilẹ̀ ní iwájú Bárákì. Sísérà sì sọ̀kalẹ̀ lórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ó sì fi ẹṣẹ̀ sálọ.
16. Bárákì àti àwọn ogun rẹ̀ sì lé àwọn ọ̀tá náà, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀ àti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn títí dé Háróṣétì ti àwọn orílẹ̀ èdè, títí ó fi pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Ṣísérà kò sí ọ̀kan tí ó lè sálà tàbí tí ó wà láàyè.
17. Ṣùgbọ́n Ṣísérà ti fi ẹṣẹ̀ sá lọ sí àgọ́ Jáélìa aya Hébérì ẹ̀yà Kénì: nítorí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ àlàáfíà wà láàárin Jábínì ọba Háṣórì àti ìdílé Hébérì ti ẹ̀yà Kénì.
18. Jáélì sì jáde síta láti pàdé Sísérà, ó sì wí fún-un pé, “Wọlé sínú àgọ́ mi, OLÚWA mi, wọlé wá má ṣe bẹ̀rù nítorí pé ààbò ń bẹ fún ọ.” Ó sì yà sínú àgọ́ rẹ̀, ó sì fi aṣọ bò ó.
19. Sísérà wí pé, “Òrùngbẹ ń gbẹ́ mí, jọ̀wọ́ fún mi ní omi mu.” Ó sì sí awọ wàrà kan, ó sì fún-un mu ó sì tún daṣọ bò ó padà.
20. Sísérà sọ fún Jáélì pé, “Kí ó dúró lẹ́nu ọ̀nà àgọ́, àti pé bí ẹnikẹ́ni bá béèrè bóyá òun wà níbẹ̀ kí ó sọ pé, ‘Kò sí ẹnìkankan ní ibẹ̀.’ ”
21. Ṣùgbọ́n Jáélì ìyàwó Hébérì mú ìṣó àgọ́ tí ó mú àti òlù ní ọwọ́ rẹ̀, ó sì yọ́ wọ inú ibi tí ó ṣùn, nígbà tí ó ti sùn fọnfọn, nígbà náà ni ó kan ìṣó náà mọ́ òkè ìpéǹpéjú rẹ̀, ó sì wọlé ṣinṣin ó sì kú.
22. Nígbà tí Bárákì dé bí ó ti ń lépa Sísérà, Jáélì láti pàdé rẹ̀, wá, èmi yóò fi ẹni tí ìwọ ń wá hàn ọ́, báyìí ni ó tẹ̀lé e wọ inú àgọ́ lọ, kíyèsí Ṣísérà dùbúlẹ̀ síbẹ̀ pẹ̀lú ìṣó àgọ́ ní agbárí rẹ̀ tí a ti kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin tí ó sì ti kú.
23. Ní ọjọ́ náà ni Ọlọ́run ṣẹ́gun Jábínì ọba àwọn ará Kénánì ní iwájú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
24. Ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì le, ó sì ń lágbára síwájú àti síwájú sí i lára Jábínì ọba Kénánì, títí wọ́n fi run òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

Saamu 48:9-14
9. Láàrin tẹ́ḿpìlì Rẹ, Ọlọ́run àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ Rẹ
10. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ Rẹ Ọlọ́run ìyìn Rẹ̀ dé òpin ayé ọwọ́ ọ̀tún Rẹ kún fún òdodo
11. Jẹ́ kí òkè Síónì kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin Júdà kí ó dùn nítorí ìdájọ́ Rẹ̀.
12. Rìn Síónì kiri lọ yíká Rẹ̀, ka ilé ìsọ́ Rẹ̀
13. Kíyèsí odi Rẹ̀ kíyèsí àwọn ààfin Rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀
14. Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Òwe 14:18-19
18. Òpè jogún ìwà òmùgọ̀ ṣùgbọ́n a dé ọlọgbọ́n ní adé ìmọ̀.
19. Ènìyàn ìkà yóò tẹríba níwájú àwọn ènìyàn rere àti ènìyàn búburú níbi ìlẹ̀kùn àwọn olódodo.

Luku 14:25-35
25. Àwọn ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn ń bá a lọ; ó sì yípadà, ó sì wí fún wọn pé,
26. “Bí ẹnìkan bá tọ̀ mí wá, tí kò sì kóríra bàbá rẹ̀, àti ìyá, àti aya, àti ọmọ, àti arákùnrin, àti arábìnrin, àní àti ọkàn ara rẹ̀ pẹ̀lú, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
27. Ẹnikẹ́ni tí kò bá ru àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
28. “Nítorí tani nínú yín tí ń pète láti kọ́ ilé ìṣọ́, tí kì yóò kọ́kọ́ jòkòó kí ó ṣírò iye owó rẹ̀, bí òun ní tó tí yóò fi parí rẹ̀.
29. Kí ó má baà jẹ́ pé nígbà tí ó bá fi ìpìlẹ̀ ilé sọlẹ̀ tan, tí kò lè parí rẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn tí ó rí i a bẹ̀rẹ̀ sí í fi í ṣe ẹlẹ́yà.
30. Wí pé, ‘Ọkùnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé, kò sì lè parí rẹ̀.’
31. “Tàbí ọba wo ni ó ń lọ bá ọba mìíràn jà, tí kì yóò kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbèrò bí yóò lè fi ẹgbàarún-ún pàdégun ẹni tí ń mú ẹgbàawàá bọ̀ wá ko òun lójú?
32. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, nígbà tí onítọ̀hún bá sì wà ní òkèrè, òun a rán ikọ̀ sí i, a sì bẹ̀rẹ̀ àdéhùn àlààáfíà.
33. Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ẹnikẹ́ni tí ó wù kí ó ṣe nínú yín, tí kò kọ ohun gbogbo tí ó ní sílẹ̀, kò lè ṣe ọmọ-ẹ̀yìn mi.
34. “Iyọ̀ dára: ṣùgbọ́n bí iyọ̀ bá di òbu, kínni a ó fi mú un dùn?
35. Kò yẹ fún ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò yẹ fún ààtàn; bí kò ṣe pé kí a kó o dànù. “Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”