A A A A A
Bible in one year
April 12

Joṣua 13:1-33
1. Nígbà tí Jóṣúà sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, OLÚWA sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.
2. “Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù: gbogbo àwọn agbègbè àwọn Fílístínì, àti ti ara Gésúrì:
3. láti odò Ṣíhónì ní ìlà oòrùn Éjíbítì sí agbégbé Ékírónì ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kénánì (agbégbé ìjòyè Fílístínì márùnún ní Gásà, Ásídódù, Áṣíkélónì, Gátì àti Ékírónì ti àwọn ará Áfítì):
4. láti gúsù, gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kénánì, láti Árà ti àwọn ará Sídónì títí ó fi dé Áfékì, agbègbè àwọn ará Ámórì,
5. Àti ilẹ̀ àwọn ara Gíbálì, àti gbogbo àwọn Lẹ́bánónì dé ìlà-oòrùn, láti Baalì-Gádì ní ìṣàlẹ̀ Okè Hámónì dé Lebo-Hámátì.
6. “Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbégbé òkè, láti Lẹ́bánónì sí Mísiréífótì-Máímù, àní, gbogbo àwọn ará Sídónì, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ,
7. pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀-ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn án àti ìdajì ẹ̀yà Mànásè.”
8. Àwọn ìdajì ẹ̀yà Mánásè tí ó kù, àti àwọn Rúbẹ́nì àti àwọn Gádì ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mósè ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jọ́dánì bí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA ti fi fún wọn.
9. Ó sì lọ títí láti Áreórì tí ń bẹ létí Ánónì-Gógì, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárin Gógì, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Médébà títí dé Díbónì.
10. Gbogbo ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, tí ó ṣe àkóso ní Hésíbónì, títí dé ààlà àwọn ará Ámónì.
11. Àti Gílíádì, ní agbégbé àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, gbogbo Okè Hámónì àti gbogbo Básánì títí dé Sálẹ́kà,
12. Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ógù ní Básánì, tí ó jọba ní Áṣítarótù àti Édérì, ẹni tí ó kù nínú àwọn Réfáítì ìyókù. Mósè ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn.
13. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì kò lé àwọn ará Géṣúrì àti Máákà jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárin àwọn ará Ísírẹ́lì títí di òní yìí.
14. Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Léfì ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.
15. Èyí ni Mósè fi fún ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni agbo ilé sí agbo ilé:
16. Láti agbégbé Áréórì ní etí Ánónì Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrin Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Médébà
17. sí Héṣibónì àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Débónì, Bámótì, Báálì, Bẹti-Báálì Míónì,
18. Jáhásì, Kédẹ́mótì, Méfáátì,
19. Kíríátaímù, Síbímà, Sẹrétì Sháárì lórí òkè ní àfonífojì.
20. Bẹti-Péórì, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Písígà, àti Bẹti-Jésímátì
21. gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀e àti gbogbo agbégbé Síhónì ọba Ámórì, tí ó ṣe àkóso Héṣíbónì. Mósè sì ti sẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Mídíánì, Éfì, Rékémì, Súrì, Húrì àti Rébà, àwọn ọmọ ọba pàmọ̀pọ̀ pẹ̀lú Síhónì tí ó gbé ilẹ̀ náà.
22. Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi idà pa Bálámù ọmọ Béórì alásọtẹ́lẹ̀.
23. Ààlà àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ni etí odò Jọ́dánì. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Rúbẹ́nì ní agbo ilé ní agbo ilé.
24. Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ẹ̀yà Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé:
25. Agbègbè ìlú Jásérì, gbogbo ìlú Gílíádì àti ìdajì orílẹ̀ èdè àwọn ọmọ ará Ámónì títí dé Áróérì ní ẹ̀bá Rábà;
26. àti láti Hésíbónì lọ sí Ramati-Mísífà àti Bétónímù, àti láti Móhánáimù sí agbégbé ìlú Débírì,
27. àti ní àfonífojì Bẹti-Hárámù, Bẹti-Nímírà, Súkótìọ àti Sáfónì pẹ̀lú ìyókù agbégbé ilẹ̀ Síhónì ọba Héṣíbónì (ní ìhà ìlà oòrùn Jọ́dánì, agbégbé rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kínẹ́rítì).
28. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gádì, ní agbo ilé ní agbo ilé.
29. Èyí ni ohun tí Mósè ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Mánásè, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú ọmọ Mánásè, ní agbo ilé ní agbo ilé:
30. Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Máháníámù àti gbogbo Básánì, gbogbo agbégbé ilẹ̀ Ógù ọba Básánì, èyí tí í se ibùgbé Jáírì ní Básánì, ọgọ́ta ìlú,
31. ìdajì Gílíádì, àti Ásítarótù àti Édírérì (àwọn ìlú ọba Ógù ní Básánì). Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Mákírì ọmọ Mánásè fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Mákírì, ní agbo ilé ní agbo ilé.
32. Èyí ni ogún tí Mósè fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Móábù ní ìhà kéjì Jọ́dánì ní ìlà-oòrùn Jẹ́ríkò.
33. Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Léfì, Mósè kò fi ogún fún un; OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

Joṣua 14:1-15
1. Ìwọ̀nyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gẹ́gẹ́ bí ogún ní ilẹ̀ Kénánì, tí Élíásérì àlùfáà, Jósúà ọmọ Núnì àti olórí ẹ̀yà àwọn agbo ilé Ísírẹ́lì pín fún wọn.
2. Ìbò ni a fi pín ìní wọn fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn án ààbọ̀ gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ láti ọwọ́ Mósè.
3. Mósè ti fún àwọn ẹ̀yà méjì àti ààbọ̀ ní ogún wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Léfì ni kò fi ìní fún ní àárin àwọn tí ó kù.
4. Àwọn ọmọ Jósẹ́fù sì di ẹ̀yà méjì, Mánásè àti Éfíráimù. Àwọn ọmọ Léfì kò gba ìpín ní ilẹ̀ náà bí kò ṣe àwọn ìlú tí wọn yóò máa gbé, pẹ̀lú pápá oko tútù fún ọ̀wọ́ ẹran àti agbo ẹran wọn.
5. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Ísírẹ́lì pín ilẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.
6. Àwọn ọkùnrin Júdà wá sí ọ̀dọ̀ Jósúà ní Gílígálì. Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè ti Kénísì wí fún un pé, “Ìwọ rántí ohun tí OLÚWA sọ fún Mósè ènìyàn Ọlọ́run ní Kadesi-Báníyà nípa ìwọ àti èmi.
7. Mo jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA rán mi láti Kádesi-Báníyà lọ rin ilẹ̀ náà wò. Mo sì mú ìròyìn wá fún un gẹ́gẹ́ bí o ti dá mi lójú,
8. ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin mi tí wọ́n bá mi lọ mú àyà àwọn ènìyàn já. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi fi gbogbo ọkàn tẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run mi.
9. Ní ọjọ́ náà, Mósè búra fún mi pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ ti rìn ni yóò jẹ́ ìní rẹ àti ti àwọn ọmọ rẹ láéláé, nítorí pé ìwọ fi tọkàntọkàn wà Pẹ̀lú OLÚWA Ọlọ́run mi.’
10. “Bí OLÚWA ti ṣe ìlérí, o ti mú mi wà láàyè fún ọdún márùn-úndínláàádọ́ta láti ìgbà tí ó ti sọ fún Mósè. Nígbà tí Ísírẹ́lì ń rìn kiri nínú aṣálẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà sì nìyí lónìí, ọmọ ọgọ́rin ọdún ó lé márùn-ún.
11. Síbẹ̀ èmi ní agbára lónìí, bí ìgbà tí Mósè rán mi jáde. Èmi sì ní agbára láti jáde fún ogun nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí mo ti wà ní ígbà náà.
12. Nísinsìnyí fi ìlú orí òkè fún mi èyí tí OLÚWA ṣe ìlérí fún mi ní ọjọ́ náà. Ìwọ gbọ́ ní ìgbà náà pé àwọn ọmọ Ánákì ti wà ní ibẹ̀, àti àwọn ìlú wọn tóbi, pé ó sì se olódi, ṣùgbọ́n bí OLÚWA ba fẹ́, èmi yóò lé wọn jáde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ.”
13. Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua súre fun Kélẹ́bù ọmọ Jéfún ó si fun un ní Hébúrónì ni ilẹ̀ ìni
14. Bẹ́ẹ̀ ni Hébúrónì jẹ́ ti Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ará Kánísì láti ìgbà náà, nítorí tí ó tẹ̀lé OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì tọkàntọkàn.
15. (Hébúrónì a sì máa jẹ́ Kíríàtì Áríbà ní ẹ̀yìn Áríbà, èyí tí ó jẹ́ ènìyàn ńlá nínú àwọn ọmọ Ánákì.) Nígbà náà ni ilẹ̀ náà sinmi ogun.

Saamu 44:20-26
20. Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa tàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.
21. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí Rẹ̀, níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kò inú ọkàn?
22. Ṣíbẹ̀, nítorí Rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojojúmọ́ a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.
23. Jí, OLÚWA! Èéṣe tí ìwọ ń sùn? Dìde fún ra Rẹ! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.
24. Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú Rẹ mọ́ tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?
25. Nítorí a tẹrí ọkàn wa ba sínú eruku; ara wa sì dì mọ́ erùpẹ̀ ilẹ̀.
26. Dìde kí o sì ràn wá lọ́wọ́; ràwápadà nítorí ìfẹ́ Rẹ tí ó dúró ṣinṣin.

Òwe 14:3-3
3. Ọ̀rọ̀ aṣiwèrè a máa ṣokùnfà pàsán fún ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ètè ọlọ́gbọ́n a máa dáàbò bò ó.

Luku 11:1-28
1. Bí ó ti ń gbàdúrà ní ibi kan, bí ó ti dákẹ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ti ń gbàdúrà, bí Jòhánù ti kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.”
2. Ó sì wí fún wọn pé, “Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbàdúrà, ẹ máa wí pé: “ ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bí i ti ọrun, Bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.
3. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lójoojúmọ́.
4. Kí o sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá; nítorí àwa tìkarawa pẹ̀lú a máa dáríji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbésè, Má sì fà wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ bìlísì.’ ”
5. Ó sì wí fún wọn pé, “Ta ni nínú yín tí yóò ní ọ̀rẹ́ kan, tí yóò sì tọ̀ ọ́ lọ láàrin ọ̀gànjọ́, tí yóò sì wí fún un pé, ‘Ọ̀rẹ́, yá mi ní ìṣù àkàrà mẹ́ta.
6. Nítorí ọ̀rẹ́ mi kan ti àjò dé sọ́dọ̀ mi, èmi kò sì ní nǹkan tí èmi ó gbé kalẹ̀ níwájú rẹ̀.’
7. “Tí òun ó sì gbé inú ilé dáhùn wí fún un pé, ‘Má yọ mí lẹ́nu: a ti sé ìlẹ̀kùn, àwọn ọmọ mi si ń bẹ lórí ẹní pẹ̀lú mi: èmi kò lè dìde fi fún ọ!’
8. Mo wí fún yín, bí òun kò tilẹ̀ ti fẹ́ dìde kí ó fifún un nítorí tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí àwíìyánu rẹ̀, yóò dìde, yóò sì fún un pọ̀ tó bí ó ti ń fẹ́.
9. “Èmí sì wí fún yín, Ẹ bèèrè, a ó sì fifún un yín; ẹ wá kiri, ẹ̀yin ó sì rí; ẹ kànkùn, a ó sì ṣí i sílẹ̀ fún yín.
10. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá bèèrè, yóò rí gbà; ẹni tí ó sì ń wá kiri, yóò rí; àti ẹni tí ó kànkùn ni a ó ṣí i sílẹ̀ fún.
11. “Ta ni baba nínú yín tí ọmọ rẹ̀ yóò bèèrè (àkàrà lọ́dọ̀ rẹ̀, tí yóò fún un ní òkúta? Tàbí bí ó bèèrè) ẹja, tí yóò fún un ní ejò dípò ẹja?
12. Tàbí bí ó sì bèèrè ẹ̀yin, tí yóò fún un ní àkéekée?
13. Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin tí ó jẹ́ ènìyàn búburú bá mọ bí a ti í fi ẹ̀bùn dáradára fún àwọn ọmọ yín: mélóméló ha ni Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi Ẹ̀mí-Mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí ó bèèrè lọ́dọ̀ rẹ̀!”
14. Ó sì ń lé ẹ̀mí ẹ̀sù kan jáde, tí ó sì yadi. Nígbà tí ẹ̀mí ẹ̀ṣù náà jáde, odi sọ̀rọ̀; ẹnu sì ya ìjọ ènìyàn.
15. Ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn nínú wọn wí pé, “Nípa Béélísébúbù olórí àwọn ẹ̀mí èṣù ni ó fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.”
16. Àwọn ẹlòmíràn sì ń dán an wò, wọ́n ń fẹ́ àmì lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ọ̀run wá.
17. Ṣùgbọ́n òun mọ ìrò inú wọn, ó wí fún wọn pé, “Gbogbo ìjọba tí ó ya ara rẹ̀ ní ipá, ni a ń sọ di àhoro; ilé tí ó sì ya ara rẹ̀ nípá yóò wó.
18. Bí Sàtánì sì yapa sí ara rẹ̀, ìjọba rẹ̀ yóò ha ṣe dúró? Nítorí ẹ̀yin wí pé, nípa Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde.
19. Bí ó ba ṣe pé nípa Béélísébúbù ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀ṣù jáde, nípa tani àwọn ọmọ yín fi ń lé wọn jáde, nítorí náà àwọn ni yóò ṣe onídájọ́ yín.
20. Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe pé Ọlọ́run ni èmi fi ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde, ǹjẹ́ ìjọba Ọlọ́run dé bá yín tán.
21. “Nígbà tí alágbára ọkùnrin tí ó ìhámọ́ra bá ń ṣọ́ ààfin rẹ̀, ẹrù rẹ̀ yóò wà ní àlàáfíà.
22. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹni tí ó ní agbára jù ú bá kọlù ú, tí ó sì ṣẹ́gun rẹ̀ a gba gbogbo ìhámọ́ra rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé lọ́wọ́ rẹ̀, a sì pín ìkógun rẹ̀.
23. “Ẹni tí kò bá wà pẹ̀lú mi, ó lòdì sí mi: ẹni tí kò bá sì bá mi kópọ̀, ó fọ́nká
24. “Nígbà tí ẹ̀mí àìmọ́ bá jáde kúrò lára ènìyàn, a máa rìn kiri ní ibi gbígbẹ, a máa wá ibi ìsinmi; nígbà tí kò bá sì rí, a wí pé, ‘Èmi yóò padà lọ sí ilé mi ní ibi tí mo gbé ti jáde wá.’
25. Nígbà tí ó bá sì dé, tí ó sì rí tí a gbá a, tí a sì ṣe é ní ọ̀sọ́.
26. Nígbà náà ni yóò lọ, yóò sì mú ẹ̀mí méje mìíràn tí ó burú ju òun tìkárarẹ̀ lọ wá: wọn yóò wọlé, wọn yóò sì máa gbé níbẹ̀: ìgbẹ̀hìn ọkùnrin náà yóò sì burú ju ìṣáájú rẹ̀ lọ.”
27. Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí, obìnrin kan nahùn rẹ̀ sókè nínú ìjọ, ó sì wí fún un pé, “Ìbùkún ni fún inú tí ó bí ọ, àti ọmú tí ìwọ mu!”
28. Ṣùgbọ́n oun wí pé, Nítòótọ́, kí ó kúkú wí pé, “Ìbùkún ni fún àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì pa á mọ́!”