A A A A A
Bible in one year
March 4

Numeri 5:1-31
1. OLÚWA sọ fún Mósè pé:
2. “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọn ó lé ẹnikẹ́ni tó bá ní ẹ̀tẹ̀, ìtújáde ara ní oríṣìíríṣìí tàbí ẹni tó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífọwọ́ kan òkú.
3. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ yálà ọkùnrin tàbí obìnrin, ẹ lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó kí wọn má báà ba ibùdó wọn jẹ́ níbi tí èmi ń gbé láàrin wọn”
4. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe bẹ́ẹ̀; wọ́n lé wọn jáde kúrò nínú ibùdó. Wọn ṣe gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti sọ fún Mósè.
5. OLÚWA sọ fún Mósè pé:
6. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì: ‘Nígbà tí ọkùnrin kan tàbí obìnrin kan bá ṣẹ̀ ara wọn lọ́nà kan tàbí òmíràn, tí wọ́n sì ṣe àìsòótọ́ sí OLÚWA, ẹni náà jẹ̀bi.
7. Ó gbọdọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sẹ̀. Ó gbọdọ̀ san ẹ̀san rẹ̀ ní ojú owó, kí ó sì fi ìdámárùn ún rẹ̀ lée, kí ó sì fi fún ẹni tí Òun jẹ̀bi rẹ̀.
8. Ṣùgbọ́n bí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò bá ní ìbátan tí ó sún mọ́ ọn tí ó lè ṣe àtúnṣe àṣìṣe rẹ̀ náà fún, àtúnṣe náà jẹ́ ti OLÚWA, ẹ sì gbọdọ̀ ko fún àlùfáà pẹ̀lú àgbò tí a fi ṣe ètùtù fún ẹni náà
9. Gbogbo ọrẹ ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú wá fún àlùfáà jẹ́ tirẹ̀.
10. Ọrẹ ohun mímọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ti oun nikan Ṣùgbọ́n ohunkóhun tó bá fún àlùfáà yóò jẹ́ ti àlùfáà.’ ”
11. OLÚWA sọ fún Mósè wí pé,
12. “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀ kí o sọ fún wọn pé: ‘Bí ìyàwó ọkùnrin kan bá yapa tó sì ṣe àìsòótọ́ sí i,
13. Nípa mímú kí ọkùnrin mìíràn bá a lò pọ̀ tí ó sì fi èyí pamọ́ fún ọkọ rẹ̀, tí a kò si gbá a mú nínú ìwà àìmọ́ rẹ̀ (nítorí pé kò sí ẹlẹ́rìí àti pé wọn kò ká a mọ́ nígbà tí ó ń dẹ́ṣẹ̀ náà).
14. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkọ rẹ̀ débi pé ó ń furà sí ìyàwó rẹ̀ yìí tí ìyàwó rẹ̀ sì wà ní àìmọ́ nítòótọ́, tàbí tí ẹ̀mí owú bá bà lé ọkùnrin kan tó sì ń jowú ìyàwó rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà ní mímọ́,
15. nígbà náà ni ọkùnrin yìí yóò mú ìyàwó rẹ̀ lọ sọ́dọ̀ àlùfáà. Ọkùnrin náà yóò sì mú ọrẹ tí a yàn fún obìnrin náà, ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n éfà ìyẹ̀fun bálì. Kò gbọdọ̀ da òróró sí i, bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ fi tùràrí dídùn sí i nítorí pé ẹbọ ohun jíjẹ fún owú ni, èyí ti n mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ìrántí.
16. “ ‘Àlùfáà yóò sì mú-un wá ṣíwájú OLÚWA.
17. Àlùfáà yóò sì bu erùpẹ̀ ilẹ̀ àgọ́ sínú omi mímọ́ tó bù láti ìkòkò amọ̀,
18. Lẹ́yìn èyí, àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú OLÚWA yóò sì tú irun orí obìnrin náà lée lọ́wọ́, èyí ni ẹbọ ohun jíjẹ ti owú, àlùfáà fúnra rẹ̀ yóò sì gbé omi kíkorò tí ń mú ègún lọ́wọ́.
19. Àlùfáà yóò sì mú obìnrin náà búra, yóò wí pé, “Bí ọkùnrin mìíràn kò bá bá ọ lòpọ̀, tí ó kò sì yapa, tí o kò sì di aláìmọ́ níwọ̀n ìgbà tí ó wà lábẹ́ àṣẹ ọkọ rẹ̀, a jẹ́ pé omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí kò ní se ọ́ níbi.
20. Ṣùgbọ́n tí ìwọ bá ti yapa kúrò lọ́dọ̀ ọkọ rẹ, tí o bá ti ba ara rẹ jẹ́ nípa jíjẹ́ kí ọkùnrin tí kì í se ọkọ rẹ bá ọ lò pọ̀,”
21. nígbà náà ni àlùfáà yóò mú obìnrin náà búra, yóò sọ fún obìnrin náà pé: “Kí OLÚWA sọ ọ́ di ẹni ègún àti ẹni ìbáwí láàrin àwọn ènìyàn rẹ nípa mímú kí itan rẹ jẹrà, kí ikùn rẹ sì wú.
22. Ǹjẹ́ kí omi yìí tí ń mú ègún wá wọ inú ara rẹ, kí ó mú ikùn rẹ̀ wú, kí ó sì mú itan rẹ̀ jẹra dànù.” “ ‘Obìnrin náà yóò sì wí pé, “Àmín. Bẹ́ẹ̀ ni kó rí.”
23. “ ‘Nígbà náà ni àlùfáà yóò kọ ègún yìí sínú ìwé, yóò sì sìn ín sínú omi kíkoro náà.
24. Àlùfáà yóò sì mú kí obìnrin náà mu omi kíkorò tí ń mú ègún wá yìí, omi náà yóò wọ inú rẹ̀ yóò sì fa ìrora kíkorò fún obìnrin náà bí ó bá jẹ̀bi.
25. Àlùfáà yóò gba ọrẹ ohun jíjẹ náà lọ́wọ́ rẹ̀, yóò fì í ṣíwájú OLÚWA, yóò sì mú iná sórí pẹpẹ.
26. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ọrẹ ohun jíjẹ nàà, yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lẹ́yìn tí ó ti mú kí obìnrin náà mu omi.
27. Bí ó bá ti mú obìnrin yìí mu omi náà, bí ó bá sì jẹ́ pé obìnrin náà ti ba ara rẹ̀ jẹ́, tí ó sì se àìsòótọ́ sí ọkọ rẹ̀, omi tí ń mú ègún wá, yóò wọ ara rẹ̀, yóò fa ìrora kíkorò fún un, ikùn rẹ̀ yóò wú, itan rẹ̀ yóò sì jẹrà dànù, yóò sì di ẹni ègún láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.
28. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé obìnrin náà kò ba ara rẹ̀ jẹ́, tó sì jẹ́ mímọ́, yóò bọ́ nínú ẹ̀bi, yóò sì le bímọ.
29. “ ‘Èyí ni òfin owú jíjẹ nígbà tí obìnrin tó wà lábẹ́ ọkọ bá ṣe aṣemá ṣe, tí ó bá ba ara rẹ̀ jẹ́
30. Tàbí nígbà tí ẹ̀mí owú jíjẹ bá bà lé ọkùnrin kan nítorí pé ó fura sí ìyàwó rẹ̀. Àlùfáà yóò mú obìnrin náà dúró níwájú OLÚWA yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin ti wí fún un.
31. Ara ọkọ rẹ̀ mọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ yìí ṣùgbọ́n obìnrin náà yóò ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’ ”

Numeri 6:1-27
1. OLÚWA sọ fún Mósè pé:
2. “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: ‘Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ pàtàkì, ẹ̀jẹ́ ìyara-ẹni-ṣọ́tọ̀ sí OLÚWA nípa àìgé irun orí (Násírì):
3. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ yàgò fún wáìnì tàbí ọtí líle, ọtí wáìnì kíkan àti àwọn ohun mímu mìíràn tó bá kan. Kò gbọdọ̀ mu èso àjàrà tàbí kí ó jẹ èṣo àjàrà tútù tàbí gbígbẹ.
4. Níwọ̀n ìgbà tí ó sì jẹ́ Násírì, ní kò gbọdọ̀ jẹ ohunkóhun tí a fi èṣo àjàrà ṣe, ìbá à ṣe kóró tàbí èèpo rẹ̀.
5. “ ‘Ní gbogbo ìgbà ẹ̀jẹ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, kí abẹ kankan má ṣe kàn án ní orí. Ó gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ títí tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí OLÚWA yóò fi pé; ó gbọdọ̀ jẹ́ kí irun orí rẹ̀ gùn.
6. Ní gbogbo àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí OLÚWA kò gbọdọ̀ súnmọ́ òkú ènìyàn.
7. Ìbá à ṣe òkú baba, àti ìyá rẹ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin tàbí obìnrin tàbí àbúrò rẹ̀, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di aláìmọ́ nítorí wọn, nítorí pé àmì ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run wà ní orí rẹ̀.
8. Ní gbogbo àsìkò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ yìí, ó jẹ́ mímọ́ sí OLÚWA.
9. “ ‘Bí ẹnìkan bá kú ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní òjijì, tí ó sì ba irun rẹ̀ tó yà sọ́tọ̀ jẹ́; ó gbọdọ̀ gé irun rẹ̀ ní ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe ọjọ́ keje.
10. Ní ọjọ́ kẹjọ, yóò mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé méjì wá sọ́dọ̀ àlùfáà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.
11. Àlùfáà yóò fi ọ̀kan rúbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun láti fi ṣe ètùtù fún un nítorí pé ó ti ṣẹ̀ nípa wíwà níbi tí òkú ènìyàn wà. Yóò sì ya orí rẹ̀ sí mímọ́ ní ọjọ́ náà gan an.
12. Ó gbọdọ̀ ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ sí OLÚWA fún àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀, ó sì gbọdọ̀ mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀bi. Kò sì ní í ka àwọn ọjọ́ ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ti tẹ́lẹ̀ nítorí pé ó tí ba ara rẹ̀ jẹ́ ní àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀.
13. “ ‘Èyí ni òfin fún Násírì nígbà tí àkókò ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ bá pé. Wọn ó mu wá sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé.
14. Níbẹ̀ ni yóò ti mú ọrẹ wá fún OLÚWA, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan tí kò ní àbùkù fún ẹbọ sísun àti ẹgbọ̀rọ̀-àgùntàn ọlọ́dún kan, tí kò ní àbùkù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò kan tí kò ní àbùkù fún ọrẹ àlàáfíà,
15. pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu, apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí a kò fi ìwúkàrà ṣe, àkàrà tí a fi ìyẹ̀fun dáradára pò pọ̀ mọ́ òróró àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a fi òróró sọjọ̀ lé lórí.
16. “ ‘Àlùfáà yóò gbé gbogbo rẹ̀ wá ṣíwájú OLÚWA, yóò sì rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ sísun.
17. Àlùfáà yóò fi àgbò náà rú ẹbọ àlàáfíà sí OLÚWA, pẹ̀lú apẹ̀rẹ̀ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà; yóò rú ẹbọ ohun jíjẹ àti ọrẹ ohun mímu.
18. “ ‘Nígbà náà ni Násírì náà yóò fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ ní ẹnu ọ̀nà Àgọ́ Ìpàdé. Yóò fi irun náà sínú iná tó wà lábẹ́ ẹbọ àlàáfíà.
19. “ ‘Lẹ́yìn tí Násírì bá ti fá irun ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ tan, àlùfáà yóò mú apá àgbò bíbọ̀, àkàrà aláìwú kan àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí kò ní ìwúkàrà láti inú apẹ̀rẹ̀ yóò sì kó gbogbo rẹ̀ lé e lọ́wọ́.
20. Àlùfáà yóò fí gbogbo rẹ̀ níwájú OLÚWA gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, wọ́n jẹ́ mímọ́, wọ́n sì jẹ́ ti àlùfáà pẹ̀lú ìgẹ̀ tí a fì àti itan tí wọ́n mú wá. Lẹ́yìn èyi, Násírì náà lè mu wáìnì.
21. “ ‘Èyí ni òfin Násírì tó jẹ́ ẹ̀jẹ́, ọrẹ rẹ̀ sí OLÚWA, yóò wà ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsọ́tọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Násírì, ní àfikún sí àwọn ohun mìíràn tó lágbára láti mú wá. Ó gbọdọ̀ mú ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bí òfin Násírì.’ ”
22. OLÚWA sọ fún Mósè pé,
23. “Sọ fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, ‘Báyìí ni kí ẹ ṣe máa súre fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Ẹ sọ fún wọn pé:
24. “ ‘ “Kí OLÚWA bùkún un yín Kí ó sì pa yín mọ́.
25. Kí OLÚWA kí o mú ojú rẹ̀ kí ó mọ́lẹ̀ sí i yín lára. Kí ó sì ṣàánú fún un yín.
26. Kí OLÚWA bojú wò yín; Kí ó sì fún un yín ní àlàáfíà.” ’
27. “Báyìí ni wọn ó ṣe fi orúkọ mi sára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Èmi ó sì bùkún wọn.”

Saamu 30:8-12
8. Sí ọ OLÚWA, ni mo képè; àti sí OLÚWA ni mo sunkún fún àánú:
9. “Èrè kí ni ó wà nínú ikú ìparun mi, nínú lílọ sí ihò mi? Eruku yóò a yìn ọ́ bí? Ǹjẹ́ yóò sọ nípa òdodo Rẹ?
10. Gbọ́, OLÚWA, kí o sì ṣàánú fún mi; ìwọ OLÚWA, jẹ́ olùrànlọ́wọ́ mi.”
11. Ìwọ ti yí ìkáànú mi di ijó fún mi; ìwọ sì ti bọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mi, o sì fi aṣọ ayọ̀ wọ̀ mí,
12. nítorí ìdí èyí ni kí ọkàn mi máa yìn ọ́, kí ó má sì ṣe dákẹ́. Ìwọ OLÚWA Ọlọ́run mi, èmi yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ títí láé.

Òwe 11:1-3
1. OLÚWA kórìíra òṣùwọ̀n èké ṣùgbọ́n òṣùwọ̀n òtítọ́ jẹ́ inú dídùn un rẹ̀.
2. Nígbà tí ìgbéraga bá dé, nígbà náà ni ìdójútì dé ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ni ọgbọ́n ń wá.
3. Òtítọ́ inú ẹni dídúró ṣinṣin ń ṣe amọ̀nà rẹ̀ ṣùgbọ́n aláìṣòótọ́ yóò parun nípasẹ̀ àìsòótọ́ wọn.

Marku 8:22-38
22. Nígbà tí wọ́n dé Bẹtisáídà, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn.
23. Jésù fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yin ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsìn yìí?”
24. Ọkùnrin náà wò àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”
25. Nígbà náà, Jésù tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.
26. Jésù sì rán an sí àwọn ẹbí rẹ̀. Ó kìlọ̀ fún un pé, “Má ṣe lọ sí ìlú, kí o má sì sọ fún ẹnikẹni ní ìlú.”
27. Nisinsìn yìí, Jésù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Gálílì. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Ṣísáríà Fílípì. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn rò wí pé mo jẹ́?”
28. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Jòhánù Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Èlíjà tàbí àwọn wòlíì mìíràn àtijọ́ ni ó tún padà wá ṣáyé.”
29. Nígbà náà, Jésù bèèrè, “Ta ni ẹ̀yin gan-an rò pé mo jẹ́?” Pétérù dáhùn pé, “Ìwọ ni Kírísítì náà.”
30. Ṣùgbọ́n Jésù kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni.
31. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le má sàì jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́-òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ijọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde.
32. Jésù bá wọn sọ̀rọ̀ yìí, láìfi ohunkóhun pamọ́ fún wọn, ṣùgbọ́n Pétérù pe Jésù sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ si bá a wí.
33. Jésù yípadà, ó wo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó sì wí fún Pétérù pẹ̀lú ìtara pé, “Kúrò lẹ́yìn mi Sátánì, nítorí ìwọ kò ro ohun tí Ọlọ́run bí kò ṣe ohun tí ènìyàn.”
34. Nígbà náà ni Jésù pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ àti ọ̀pọ̀ ènìyàn láti bá wọn sọ̀rọ̀, ó wí fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó ṣe ara rẹ̀, kí ó si gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó si máa tọ̀ mi lẹ́yìn.
35. Nítorí ẹni tó bá gbìyànjú láti gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù. Iye àwọn tí ó sọ ẹ̀mí wọn nù nìkan nítorí í tèmi àti nítorí ìyìn rere, òun náà ni yóò gbà á là.
36. Nítorí èrè kí ni ó jẹ fún ẹni tí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù.?
37. Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi ṣe pàsípàrọ̀ ẹ̀mí rẹ̀?
38. Nítorí náà, bí ẹnikẹ́ni bá tijú àti gbà mí tàbí ọ̀rọ̀ mi nínú ìran panságà àti ẹlẹ́sẹ̀ yìí, tí ó kún fún àìgbàgbọ́ àti ẹ̀ṣẹ̀ báyìí, Ọmọ-Ènìyàn yóò tijú rẹ nígbà tí o bá padà dé nínú ògo Baba rẹ, pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì mímọ́.”