A A A A A
Bible in one year
March 2

Numeri 1:1-54
1. OLÚWA bá Mósè sọ̀rọ̀ ní ihà Ṣínáì nínú àgọ́ àjọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì ní ọdún kejì tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì, ó wí pé:
2. “Ka gbogbo àgbájọ ènìyàn Ísírẹ́lì nípa ẹbí wọn, àti nípa ìdílé baba wọn, to orúkọ wọn olúkúlùkù ọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan.
3. Ìwọ àti Árónì ni kí ẹ kà gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn láti ọmọ ogún ọdún sókè, àwọn tí ó tó lọ sójú ogun.
4. Kí ẹ mú ọkùnrin kọ̀ọ̀kan tí ó jẹ́ olórí ìdílé rẹ̀ láti ràn yín lọ́wọ́.
5. Orúkọ àwọn ọkùnrin tí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ nìyí: Láti ọ̀dọ̀ Rúbẹ́nì, Élísúrì ọmọ Ṣédéúrì;
6. Láti ọ̀dọ̀ Símónì, Ṣélúmíélì ọmọ Ṣúrísáddáì;
7. Láti ọ̀dọ̀ Júdà, Násónì ọmọ Ámínádàbù;
8. Láti ọ̀dọ̀ Íssákárì, Nítaníẹ́lì ọmọ Ṣúárì;
9. Láti ọ̀dọ̀ Ṣébúlúnì, Élíábù ọmọ Hélónì;
10. Láti ọ̀dọ̀ àwọn sọmọ Jósẹ́fù: láti ọ̀dọ̀ Éfraimù, Elisámà ọmọ Ámíhúdì; Láti ọ̀dọ̀ Mánásè, Gámáélì ọmọ Pedasúrù;
11. Láti ọ̀dọ̀ Bẹ́ńjámínì, Ábídánì ọmọ Gídíónì;
12. Láti ọ̀dọ̀ Dánì, Áhíésérì ọmọ Ámísádáì;
13. Láti ọ̀dọ̀ Áṣérì, Págíélì ọmọ Ókíránì;
14. Láti ọ̀dọ̀ Gáádì, Élíásàfu ọmọ Déúélì;
15. Láti ọ̀dọ̀ Náfítalì, Áhírà ọmọ Énánì.”
16. Àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n yàn nínú àwùjọ ènìyàn, olórí àwọn ẹ̀yà baba wọn. Àwọn ni olórí àwọn ẹbí Ísírẹ́lì.
17. Mósè àti Árónì mú àwọn ènìyàn tí a dárúkọ wọ̀nyí
18. wọ́n sì pe gbogbo àwùjọ ènìyàn Ísírẹ́lì jọ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kejì. Àwọn ènìyàn sì dárúkọ baba ńlá wọn nípa ẹbí àti ìdílé wọn. Wọ́n sì se àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọmọkùnrin ní ọ̀kọ̀ọ̀kan láti ọmọ ogún ọdún sókè,
19. gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti paṣẹ fún Mósè. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe kà wọ́n nínú ihà Ṣínáì.
20. Láti ìran Rúbẹ́nì tí í se àkọ́bí Ísírẹ́lì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn, lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
21. Àwọn tí a kà ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹgbẹ̀ta (46,500).
22. Láti ìran Símónì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà, wọ́n sì to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
23. Iye àwọn tí á kà nínú ẹ̀ya Símónì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún-ó-lé ọ̀ọ́dúnrún (59,300).
24. Láti ìran Gáádì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí ẹbí àti ìdílé wọn.
25. Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Gáádì jẹ́ ẹgbàá-ó-lé-àádọ́ta-lé-lẹ́gbẹ̀jọ (45,650).
26. Láti ìran Júdà: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
27. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Júdà jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì-ó-lé-ẹgbẹ́ta (74,600).
28. Láti ìran Ísákárì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
29. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Íṣákárì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì-ó-lé-irinwó (54,400).
30. Láti ìran Ṣébúlúnì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
31. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Ṣébúlúnì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlógún-ó-lé-egbéje (57,400).
32. Láti inú àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù: Láti ìran Éfúráímù: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọ́n jẹ́ ogún ọdún sókè tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
33. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Éfúráímù jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (40,500).
34. Láti ìran Mánássè: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
35. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbàá ẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba (32,200).
36. Láti ìran Bẹ́ńjámínì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
37. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógún-ó-lé-egbéje (35,400).
38. Láti ìran Dánì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ọmọ ogún ọdún sókè, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
39. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélọ́gbọ̀n-ó-lé-ẹẹ̀dẹ́gbẹ̀rin (62,700).
40. Láti ìran Ásérì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún sókè, tí wọ́n le lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
41. Iye tí a kà nínú ẹ̀yà Áṣérì jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).
42. Láti ìran Náfítalì: Gbogbo ọmọkùnrin tí ọjọ́ orí wọn jẹ́ ogún ọdún ó lé, tí wọ́n lè lọ sójú ogun ni wọ́n to orúkọ wọn lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ ẹbí àti ìdílé wọn.
43. Iye àwọn tí a kà nínú ẹ̀yà Náfítalì jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (53,400).
44. Wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn tí Mósè àti Árónì kà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn olórí méjìlá (12) fún Ísírẹ́lì, tí ẹnìkọ̀ọ̀kan sojú fún ìdílé rẹ̀.
45. Gbogbo ọmọkùnrin Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọmọ ogún ọdún (20) sókè, tó sì lè lọ sójú ogun ni wọ́n kà gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn.
46. Àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín-àádọ́ta, (603,550).
47. A kò ka àwọn ìdílé ẹ̀yà Léfì mọ́ àwọn ìyókù.
48. Nítorí OLÚWA ti sọ fún Mósè pé,
49. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ka ẹ̀yà Léfì, tàbí kí o kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì:
50. Dípò èyí yan àwọn ọmọ Léfì láti jẹ́ alábojútó àgọ́. Ẹrí, lórí gbogbo ohun èlò àti ohun gbogbo tó jẹ́ ti àgọ́ ẹ̀rí. Àwọn ni yóò máa gbé àgọ́ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, wọn ó máa mójú tó o, kí wọn ó sì máa pàgọ́ yí i ká.
51. Ìgbàkígbà tí àgọ́ yóò bá tẹ̀ṣíwájú, àwọn ọmọ Léfì ni yóò tu palẹ̀, nígbàkígbà tí a bá sì tún pa àgọ́, àwọn ọmọ Léfì náà ni yóò ṣe é. Ẹnikẹ́ni tó bá súnmọ́ tòsí ibẹ̀, pípa ni kí ẹ pa á
52. kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àgọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn olúkúlùkù ní ibùdó tirẹ̀ lábẹ́ ọ̀págun tirẹ̀.
53. Àwọn ọmọ Léfì yóò jẹ́ alábojútó àti olùtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà, kí ìbínú má ba à sí lára ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; kí àwọn ọmọ Léfì sì máa ṣe ìtọ́jú Àgọ́ Ẹ̀rí náà.”
54. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pàṣẹ fún Mósè.

Numeri 2:1-34
1. OLÚWA sọ fún Mósè àti Árónì pé:
2. “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa Àgọ́ wọn yí àgọ́ ìpàdé ká, kí wọ́n jẹ́ kí àgọ́ wọn jìnnà sí i díẹ̀, oníkálùkù lábẹ́ ọ̀págun pẹ̀lú àṣíá ìdílé wọn.”
3. Ní ìlà oòrùn, ní ìdojúkọ àtiyọ oòrùn ni kí ìpín ti Júdà pa ibùdó wọn sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Júdà ni Náṣónì ọmọ Ámínádábù.
4. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlógójì ó lé ẹgbẹ̀ta (74,600).
5. Ẹ̀yà Ísákárì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ísákárì ni Nìtaníẹ́lì ọmọ Súárì.
6. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tadínlọ́gbọ̀n ó lé irínwó (54,400).
7. Ẹ̀yà Sébúlúnì ni yóò tẹ̀lé e. Olórí Sébúlónì ni Élíábù ọmọ Hélónì.
8. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gbọ̀n-ó-lé-egbéje (57,400).
9. Gbogbo àwọn tí a yàn sí ibùdó Júdà, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́taléláàdọ́rin ó lé irínwó (186,400). Àwọn ni yóò kọ́kọ́ ṣáájú.
10. Ní ìhà gúsù ni ìpín ti Rúbẹ́nì pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olórí Rúbẹ́nì ni Elisúrì ọmọ Ṣedúérì.
11. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́talélógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (46,500).
12. Ẹ̀yà Símónì ni yóò pa ibùdó tẹ́lé wọn. Olórí Símónì ni Ṣélúmíélì ọmọ Surisadáì.
13. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbéje. (59,300).
14. Ẹ̀yà Gáádì ló tẹ̀lé wọn. Olórí Gáádì ni Eliásáfì ọmọ Déúélì.
15. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá méjìlélógún ó lé àádọ́ta (45,650).
16. Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Rúbẹ́nì, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá márùndínlọ́gọ́rún ó lé àádọ́tàlélégbéje (151,450). Àwọn ni yóò jáde sìkéjì.
17. Nígbà náà ni àwọn ọmọ Léfì Àti Àgọ́ ìpàdé yóò tẹ̀ṣíwájú láàrin ibùdó àwọn ènìyàn, wọn yóò tẹ̀ṣíwájú ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé gẹ́gẹ́ bí wọn ṣe pa ibùdó, olúkúlùkù láàyè rẹ̀, àti lábẹ́ ọ̀págun rẹ̀.
18. Ní ìhà ìlà oòrùn ni ìpín Éfúráímù yóò pa ibùdó rẹ̀ sí lábẹ́ ọ́págun rẹ̀. Olórí Éfúráímù ni Élíṣámà ọmọ Ámíhúdì.
19. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (40,500).
20. Ẹ̀yà Mánásè ni yóò tẹ̀lé wọn. Olórí Mánásè ni Gàmálíélì ọmọ Pedasúrì.
21. Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-igba (32,200).
22. Ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì ni yóò tẹ̀ lé e. Olórí Bẹ́ńjámínì ni Ábídánì ọmọ Gídíónì.
23. Iye ìpín rẹ̀ ni ẹgbàá mẹ́tadínlógún ó lé egbéje (35,400).
24. Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Éfúráímù, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, àpapọ̀ iye wọn jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnléláàdọ́ta-ó-lé-ọgọ́rùn-ún (108,100). Àwọn ni yóò jáde sìkẹ́ta.
25. Ní ìhà àríwá, ni ìpín Dánì yóò pa ibùdó sí lábẹ́ ọ̀págun wọn. Olóri Dánì ni Áyésérì ọmọ Ámíṣádáyì.
26. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin. (62,700).
27. Ẹ̀yà Ásérì ni yóò pa ibùdó tẹ̀lé wọn. Olórí Ásérì ni Págíélì ọmọ Ókíránì.
28. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì-ó-lé-ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (41,500).
29. Ẹ̀yà Náfítanì ni yóò kàn lẹ́yìn wọn. Olórí Náfítanì ni Áhírà ọmọ Énánì.
30. Iye ìpín rẹ̀ jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìndínlógún-ó-lé-egbéje (53,400).
31. Gbogbo ènìyàn tí a yàn sí ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbàá méjìdínlọ́gọ̀rún-ó-lé-ẹgbẹ̀jọ (157,600). Àwọn ni yóò jáde kẹ́yìn lábẹ́ ọ̀págun wọn.
32. Wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n kà nípa ìdílé wọn. Gbogbo àwọn tó wà ní ibùdó, gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́-ó-lé-egbéjìdínlógún-dín àádọ́ta (603,550).
33. Ṣùgbọ́n a kò ka àwọn ọmọ Léfì papọ̀ mọ́ àwọn Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún Mósè.
34. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì se gbogbo ohun tí OLÚWA pa láṣẹ fún Mósè, báyìí ni wọ́n ṣe pa ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn, bẹ́ẹ̀ náà sì ni wọ́n ṣe jáde, oníkálùkù pẹ̀lú ẹbí àti ìdílé rẹ̀.

Saamu 29:7-11
7. Ohùn OLÚWA ń ya bí ọwọ́ iná mọ̀nà
8. Ohùn OLÚWA ń mi ihà. OLÚWA mi ihà Kádéṣì.
9. Ohùn OLÚWA ní ó lọ igi óákù, ó n mú abo àgbọ̀rín bí ó sì bọ́ igi igbó sí ìhòòhò. àti nínú tẹ́ḿpìlì Rẹ̀ gbogbo ohùn wí pé “Ògo!”
10. OLÚWA jókòó, Ó sì jọba lórí ìṣàn omi; OLÚWA jókòó lórí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba títí láéláé.
11. Kí OLÚWA fi agbára fún àwọn ènìyàn Rẹ̀; bùkún àwọn ènìyàn Rẹ̀ pẹ̀lú àlàáfíà.

Òwe 10:26-29
26. Bí ọtí kíkan sí eyín, àti èéfín sí ojú bẹ́ẹ̀ ni ọ̀lẹ sí ẹni tí ó rán an níṣẹ́.
27. Ìbẹ̀rù OLÚWA ń mú ọjọ́ ayé gígùn wá, ṣùgbọ́n a gé ojọ́ ayé ènìyàn búburú kúrú.
28. Ìrètí Olódodo ni ayọ̀ ṣùgbọ́n ìrètí ènìyàn buburú já sí òfo.
29. Ọ̀nà OLÚWA jẹ́ ààbò fún Olódodo, ṣùgbọ́n ìparun ni ó jẹ́ fún àwọn tí ń se ibi.

Marku 7:14-37
14. Lẹ́yìn náà, Jésù pe ọ̀pọ̀ ènìyàn láti wá gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ó sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ sì jẹ́ kí èyí ó yé e yín.
15. Kò sí ohunkóhun láti òde ènìyàn, tí ó wọ inú rẹ̀ lọ, tí ó lè sọ ọ́ di aláìmọ́, Ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tí ó ti inú rẹ jáde, àwọn wọ̀nyí ní ń sọ ènìyàn di aláìmọ́.
16. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ kí ó gbọ́.”
17. Nígbà tí Jésù sì wọ inú ilé kan lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tẹ̀lé é, wọ́n sì béèrè ìtumọ̀ àwọn òwe tí ó pa.
18. Jésù béèrè wí pé, “Àbí kò sí èyí tí ó yé yín nínú ọ̀rọ̀ náà? Ẹ̀yin kò rí i wí pé ohunkóhun tí ó wọ inú ènìyàn láti òde kò lè sọ ènìyàn di aláìmọ́?
19. Ìdí ni wí pé, Ohunkóhun tí ó bá wọ inú láti ìta, kò wọ inú ọkàn rárá, ṣùgbọ́n ó kọjá sí ikùn.” (Nípa sísọ èyí, Jésù fi hàn pé gbogbo oúnjẹ jẹ́ “mímọ́.”)
20. Nígbà náà, ó fi kún un pé: “Èyí ti ó ti ọkàn ènìyàn jáde ni ń sọni di aláìmọ́.
21. Nítorí pé láti inú ọkàn ènìyàn ni àwọn èrò búburú wọ̀nyí ti ń jáde wá: àgbèrè, olè, ìpànìyàn, panṣágà,
22. ọ̀kánjúwà, odì-yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀-ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀.
23. Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.”
24. Nígbà náà ni Jésù kúrò ní Gálílì, ó sí lọ sí agbégbé Tírè àti Sídónì, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yin rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri.
25. Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jésù, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́ṣẹ̀ Jésù.
26. Gíríkì ní obìnrin náà, Ṣíríàfonísíà ní orílẹ̀ èdè rẹ̀. Ó bẹ Jésù kí ó bá òun lé ẹ̀mí Èsù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
27. Jésù sọ fún obìnrin yìí pé, “Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí a fi oúnjẹ tẹ́ àwọn ọmọ lọ́rùn ná. Nítorí kò tọ́ kí a mú oúnjẹ àwọn ọmọ fún àwọn ajá.”
28. Obìnrin náà dáhùn wí pé, “Òótọ́ ni ọ̀rọ̀ yín Olúwa, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ajá pàápàá a máa ní àǹfààní láti jẹ ẹ̀ẹ́rún oúnjẹ tí ó bá bọ́ sílẹ̀ láti orí tábílì.”
29. “Ó sì wi fún un pé, nítorí ọ̀rọ̀ yìí, máa lọ, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti jáde kúrò lára ọmọbìnrin rẹ.”
30. Nígbà tí ó náà padà dé ilé, ó bá ọmọbìnrin rẹ̀ ní ìdùbúlẹ̀ jẹ́jẹ́ lórí ibùsùn, ẹ̀mí àìmọ́ náà ti fi í sílẹ̀.
31. Nígbà náà ni Jésù fi agbégbé Tírè àti Ṣídónì sílẹ̀, ó wá si òkun Gálílì láàrin agbègbè Dékápólì.
32. Níbẹ̀ ọkùnrin kan tí kò lè sọ̀rọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ Jésù, àwọn ènìyàn sì bẹ Jésù pé kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e.
33. Jésù sì mú ọkùnrin náà kúrò láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn. Ó sì fi àwọn ìka rẹ̀ sí etí ọkùnrin náà, ó tu itọ sọ́wọ́. Ó sì fi kan ahọ́n rẹ̀.
34. Nígbà náà ni Jésù wòkè ọ̀run, ó sì mí kanlẹ̀, ó sì pàṣẹ wí pé, “Éfátà,” èyí ni, “Ìwọ ṣí.”
35. Bí Jésù ti pàṣẹ yìí tan, ọkùnrin náà sì gbọ́ràn dáadáa. Ó sì sọ̀rọ̀ ketekete.
36. Jésù pàṣẹ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn tó wà níbẹ̀ pé kí wọn má ṣe tan ìròyìn náà ká. Ṣùgbọ́n bí ó ti ń pa wọ́n lẹ́nu mọ́ tó, náà ni wọ́n ń tan ìròyìn náà káàkiri tó.
37. Àwọn ènìyàn sì kún fún ìyanu, wọ́n wí pé, “Ó se ohun gbogbo dáradára, Ó mú kí adití gbọ́ràn, odi sì sọ̀rọ̀.”